Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 24:1-34

24  Má ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú,+ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí bíbá wọn wọlé.+  Nítorí ìfiniṣèjẹ ni ohun tí ọkàn-àyà wọ́n ń ṣe àṣàrò ṣáá, ìjàngbọ̀n sì ni ètè wọ́n ń sọ ṣáá.+  Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró,+ nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+  Nípa ìmọ̀ sì ni àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún yóò fi kún fún gbogbo ohun oníyelórí tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni.+  Ẹni tí ó gbọ́n ní okun ni abarapá ọkùnrin,+ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.+  Nítorí nípasẹ̀ ìdarí jíjáfáfá ni ìwọ yóò fi máa bá ogun rẹ lọ,+ ìgbàlà sì ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.+  Fún òmùgọ̀, ọgbọ́n tòótọ́ ti ga jù;+ òun kì yóò la ẹnu rẹ̀ ní ẹnubodè.  Ní ti ẹnikẹ́ni tí ń pète-pèrò àtiṣe búburú, a ó pè é ní ọ̀gá kìkì nídìí àwọn èrò ibi.+  Ìwà àìníjàánu ti ìwà òmùgọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí sì ni olùyọṣùtì lójú aráyé.+ 10  Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí?+ Agbára rẹ yóò kéré jọjọ. 11  Dá àwọn tí a ń mú lọ fún ikú nídè; àwọn tí ó sì ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sínú ìfikúpa, kí o fà wọ́n sẹ́yìn.+ 12  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ sọ pé: “Wò ó! Àwa kò mọ̀ nípa èyí,”+ ẹni tí ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà kì yóò ha fi òye mọ̀ ọ́n,+ ẹni tí ń ṣàkíyèsí ọkàn rẹ kì yóò ha mọ̀+ kí ó sì san án padà dájúdájú fún ará ayé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbòkègbodò rẹ̀?+ 13  Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí ó dára; sì jẹ́ kí afárá oyin dídùn wà ní òkè ẹnu rẹ.+ 14  Lọ́nà kan náà, mọ ọgbọ́n fún ọkàn rẹ.+ Bí ìwọ bá ti wá a rí, nígbà náà, ọjọ́ ọ̀la yóò wà, a kì yóò sì ké ìrètí rẹ kúrò.+ 15  Má ṣe lúgọ, bí ẹni burúkú, de ibi gbígbé olódodo;+ má fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ.+ 16  Nítorí pé olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú;+ ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni a óò mú kọsẹ̀ nípasẹ̀ ìyọnu àjálù.+ 17  Nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má yọ̀; nígbà tí a bá sì mú un kọsẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ má ṣe kún fún ìdùnnú,+ 18  kí Jèhófà máa bàa rí i, kí ó sì burú ní ojú rẹ̀, òun a sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lára rẹ̀ dájúdájú.+ 19  Má ṣe gbaná jẹ nítorí àwọn aṣebi. Má ṣe ìlara àwọn ènìyàn burúkú.+ 20  Nítorí kì yóò sí ọjọ́ ọ̀la fún ẹni búburú kankan;+ àní fìtílà àwọn ènìyàn burúkú ni a óò fẹ́ pa.+ 21  Ọmọ mi, bẹ̀rù Jèhófà àti ọba.+ Má tojú bọ ọ̀ràn àwọn tí ó wà fún ìyípadà.+ 22  Nítorí àjálù wọn yóò dìde lójijì tó bẹ́ẹ̀,+ tí ó fi jẹ́ pé, ta ni ó mọ̀ nípa àkúrun àwọn tí ó wà fún ìyípadà?+ 23  Àsọjáde wọ̀nyí pẹ̀lú wà fún àwọn ọlọ́gbọ́n:+ Fífi ojúsàájú hàn nínú ìdájọ́ kò dára.+ 24  Ẹni tí ó bá ń sọ fún ẹni burúkú pé: “Olódodo ni ọ́,”+ àwọn ènìyàn yóò fi í bú, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè yóò dá a lẹ́bi. 25  Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ń fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà,+ yóò dùn mọ́ni, ìbùkún ohun rere yóò sì wá sórí wọn.+ 26  Ẹni tí ó bá ń fèsì lọ́nà tí ó tọ́ yóò fi ẹnu ko ètè.+ 27  Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún ara rẹ ní pápá.+ Lẹ́yìn ìgbà náà, kí o gbé agbo ilé rẹ ró pẹ̀lú. 28  Má di ẹlẹ́rìí lòdì sí ọmọnìkejì rẹ láìnídìí.+ Ṣe ni ìwọ yóò wá lo ètè rẹ lọ́nà òmùgọ̀.+ 29  Má sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí mi gan-an, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe sí i.+ Èmi yóò san án padà fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ rẹ̀.”+ 30  Mo kọjá lọ lẹ́bàá pápá ọ̀lẹ+ àti lẹ́bàá ọgbà àjàrà ènìyàn tí ọkàn-àyà kù fún.+ 31  Sì wò ó! gbogbo rẹ̀ hu èpò.+ Àní èsìsì bò ó, ògiri òkúta rẹ̀ ni a ti ya lulẹ̀.+ 32  Nítorí náà, èmi fúnra mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí wò; mo bẹ̀rẹ̀ sí fi í sí ọkàn-àyà;+ mo rí, mo gba ìbáwí:+ 33  Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ láti dùbúlẹ̀,+ 34  ó dájú pé ipò òṣì rẹ yóò dé gẹ́gẹ́ bí dánàdánà àti àìní rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé