Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 22:1-29

22  Orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀;+ ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.+  Ọlọ́rọ̀ àti aláìnílọ́wọ́ ti pàdé ara wọn.+ Olùṣẹ̀dá gbogbo wọn ni Jèhófà.+  Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́,+ ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.+  Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.+  Ẹ̀gún àti pańpẹ́ ń bẹ ní ọ̀nà oníwà wíwọ́;+ ẹni tí ń ṣọ́ ọkàn rẹ̀ yóò jìnnà réré sí wọn.+  Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀;+ nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.+  Ọlọ́rọ̀ ní ń ṣàkóso lórí àwọn aláìnílọ́wọ́,+ ayá-nǹkan sì ni ìránṣẹ́ awínni.+  Ẹni tí n fúnrúgbìn àìṣòdodo yóò ká ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,+ ṣùgbọ́n ọ̀pá ìbínú rẹ̀ kíkan yóò wá sí òpin rẹ̀.+  Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú ni a ó bù kún, nítorí ó ti fún ẹni rírẹlẹ̀ lára oúnjẹ rẹ̀.+ 10  Lé olùyọṣùtì lọ, kí asọ̀ lè jáde lọ, kí ìfagagbága lábẹ́ òfin àti àbùkù sì lè kásẹ̀ nílẹ̀.+ 11  Ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ìmọ́gaara ọkàn-àyà+—nítorí òòfà ẹwà ètè rẹ̀, ọba yóò jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.+ 12  Ojú Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fi ìṣọ́ ṣọ́ ìmọ̀,+ ṣùgbọ́n ó máa ń dojú ọ̀rọ̀ aládàkàdekè dé.+ 13  Ọ̀lẹ sọ pé:+ “Kìnnìún ń bẹ lóde!+ A ó ṣìkà pa mí ní àárín ojúde ìlú!” 14  Kòtò jíjìn ni ẹnu àjèjì obìnrin.+ Ẹni tí Jèhófà dá lẹ́bi yóò já sínú rẹ̀.+ 15  Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí;+ ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.+ 16  Ẹni tí ń lu ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì láti lè pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan fún ara rẹ̀,+ àti ẹni tí ń fi fún ọlọ́rọ̀ pẹ̀lú, àìní ni ó forí lé dájúdájú.+ 17  Dẹ etí rẹ sílẹ̀ kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,+ kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ gan-an sí ìmọ̀ mi.+ 18  Nítorí ó dùn mọ́ni pé kí o pa wọ́n mọ́ sínú ikùn rẹ,+ kí wọ́n lè jùmọ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ètè rẹ.+ 19  Kí ìgbọ́kànlé rẹ lè wá wà nínú Jèhófà+ ni mo ṣe fún ọ ní ìmọ̀ lónìí, àní ìwọ. 20  Èmi kò ha ti kọ̀wé sí ọ ṣáájú àkókò yìí pẹ̀lú àwọn ìgbani-nímọ̀ràn àti ìmọ̀,+ 21  láti fi ìjótìítọ́ àwọn àsọjáde tòótọ́ hàn ọ́, láti lè mú àwọn àsọjáde tí í ṣe òtítọ́ padà lọ—fún ẹni tí ó rán ọ jáde?+ 22  Má ja ẹni rírẹlẹ̀ lólè nítorí tí ó jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀,+ má sì tẹ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ní àtẹ̀rẹ́ ní ẹnubodè.+ 23  Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò,+ yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tọwọ́ wọn.+ 24  Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́;+ má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé,+ 25  kí ìwọ má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú, kí o sì gba ìdẹkùn fún ọkàn rẹ dájúdájú. 26  Má di ara àwọn tí ń gba ọwọ́,+ ara àwọn tí ń ṣe onídùúró fún ohun yíyá.+ 27  Bí ìwọ kò bá ní ohunkóhun láti fi san án, èé ṣe tí òun yóò fi gba ibùsùn rẹ kúrò lábẹ́ rẹ? 28  Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìn, èyí tí àwọn baba ńlá rẹ ti pa.+ 29  Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí;+ kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé