Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 2:1-22

2  Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde+ mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ,+  láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n,+ kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀;+  jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye,+ tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀,+  bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà,+ tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin,+  bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù+ Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.+  Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n;+ láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.+  Òun yóò sì to ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́+ jọ fún àwọn adúróṣánṣán; ó jẹ́ apata+ fún àwọn tí ń rìn nínú ìwà títọ́,  nípa pípa àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́,+ yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.+ 10  Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ,+ tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá,+ 11  agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ,+ ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ,+ 12  láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú,+ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà,+ 13  kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń fi àwọn ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà òkùnkùn,+ 14  kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,+ àwọn tí ń kún fún ìdùnnú nínú àwọn ohun àyídáyidà ìwà búburú;+ 15  àwọn tí ipa ọ̀nà wọn jẹ́ wíwọ́, tí wọ́n sì ń ṣe békebèke ní gbogbo ipa ọ̀nà wọn;+ 16  láti dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin, kúrò lọ́wọ́ obìnrin ilẹ̀ òkèèrè+ tí ó ti mú kí àwọn àsọjáde rẹ̀ dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in,+ 17  ẹni tí ń fi ọ̀rẹ́ àfinúhàn ìgbà èwe+ rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì ti gbàgbé májẹ̀mú Ọlọ́run rẹ̀.+ 18  Nítorí inú ikú nísàlẹ̀ ni ilé rẹ̀ rì sí àti sí ìsàlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú ni àwọn òpó ọ̀nà rẹ̀.+ 19  Kò sí ìkankan lára àwọn tí ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tí yóò padà wá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò tún padà rí ipa ọ̀nà àwọn alààyè.+ 20  Ète rẹ̀ ni pé kí ìwọ lè máa rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere,+ kí o sì lè pa ipa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.+ 21  Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé,+ àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.+ 22  Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an;+ àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé