Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 18:1-24

18  Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan;+ gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.+  Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ arìndìn kì í rí inú dídùn nínú ìfòyemọ̀,+ bí kò ṣe pé kí ọkàn-àyà rẹ̀ tú ara rẹ̀ síta.+  Nígbà tí ẹni burúkú bá wọlé, ìfojú-tín-ín-rín yóò wọlé pẹ̀lú;+ pa pọ̀ pẹ̀lú àbùkù+ sì ni ẹ̀gàn.  Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn.+ Kànga ọgbọ́n jẹ́ ọ̀gbàrá tí ń tú jáde.+  Ṣíṣe ojúsàájú sí ẹni burúkú kò dára,+ tàbí títi olódodo sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ìdájọ́.+  Ètè arìndìn wọnú aáwọ̀,+ ẹnu rẹ̀ gan-an sì béèrè fún ẹgba pàápàá.+  Ẹnu arìndìn ni ìparun rẹ̀,+ ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀.+  Ọ̀rọ̀ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ dà bí ohun tí a ó fi ìwọra gbé mì,+ èyí tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún nínú ikùn.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹni tí ń fi ara rẹ̀ hàn ní aṣọwọ́dẹngbẹrẹ nínú iṣẹ́ rẹ̀+—ó jẹ́ arákùnrin ẹni tí ń fa ìparun.+ 10  Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára.+ Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.+ 11  Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀,+ wọ́n sì dà bí ògiri adáàbòboni nínú èrò-ọkàn rẹ̀.+ 12  Ṣáájú ìfọ́yángá, ọkàn-àyà ènìyàn a ga fíofío,+ ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ògo.+ 13  Nígbà tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ,+ èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.+ 14  Ẹ̀mí ènìyàn lè fara da àrùn rẹ̀;+ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí tí ìdààmú bá, ta ní lè mú un mọ́ra?+ 15  Ọkàn-àyà olóye ń jèrè ìmọ̀,+ etí àwọn ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti rí ìmọ̀.+ 16  Ẹ̀bùn ènìyàn yóò ṣe àyè fífẹ̀ fún un,+ yóò sì ṣamọ̀nà rẹ̀ sí iwájú àwọn ènìyàn ńlá pàápàá.+ 17  Ẹnì kìíní nínú ẹjọ́ rẹ̀ jẹ́ olódodo;+ ọmọnìkejì rẹ̀ wọlé wá, dájúdájú, ó sì yẹ̀ ẹ́ wò látòkè délẹ̀.+ 18  Kèké ń fòpin sí asọ̀ pàápàá,+ ó sì ń ya àwọn alágbára ńlá pàápàá sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara wọn.+ 19  Arákùnrin tí a hùwà ìrélànàkọjá sí, ó ju ìlú tí ó lágbára;+ asọ̀ sì wà tí ó dà bí ọ̀pá ìdábùú ilé gogoro ibùgbé.+ 20  Láti inú èso ẹnu ènìyàn ni a ó ti tẹ́ ikùn rẹ̀ lọ́rùn;+ àní a ó fi èso ètè rẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn.+ 21  Ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n,+ ẹni tí ó bá sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yóò jẹ èso rẹ̀.+ 22  Ẹnì kan ha ti rí aya rere bí?+ Ẹni náà ti rí ohun rere,+ ẹni náà sì ti rí ìfẹ́ rere gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+ 23  Àrọwà ni aláìnílọ́wọ́ ń pa,+ ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a máa dáhùn lọ́nà líle.+ 24  Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì,+ ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé