Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 17:1-28

17  Búrẹ́dì gbígbẹ tòun ti ìdákẹ́jẹ́ẹ́+ sàn ju ilé tí ó kún fún àwọn ẹbọ pa pọ̀ pẹ̀lú aáwọ̀.+  Ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn yóò ṣàkóso lórí ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú,+ yóò sì ṣe àjọpín ogún láàárín àwọn arákùnrin.+  Ìkòkò ìyọ́hunmọ́ wà fún fàdákà àti ìléru fún wúrà,+ ṣùgbọ́n Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.+  Aṣebi ń fetí sí ètè ìṣenilọ́ṣẹ́.+ Aṣèké ń fi etí sí ahọ́n tí ń fa àgbákò.+  Ẹni tí ó bá ń fi aláìnílọ́wọ́ ṣẹ̀sín ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀.+ Ẹni tí ó bá kún fún ìdùnnú nítorí àjálù ẹlòmíràn kì yóò bọ́ lọ́wọ́ ìyà.+  Adé arúgbó ni àwọn ọmọ-ọmọ,+ ẹwà àwọn ọmọ sì ni baba wọn.+  Ètè ìdúróṣánṣán kò yẹ ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ òpònú.+ Áńbọ̀sìbọ́sí ètè èké fún ọ̀tọ̀kùlú!+  Ẹ̀bùn jẹ́ òkúta tí ń jèrè ojú rere lójú olúwa rẹ̀ atóbilọ́lá.+ Ibi gbogbo tí òun bá yíjú sí ni yóò ti máa kẹ́sẹ járí.+  Ẹni tí ń bo ìrélànàkọjá mọ́lẹ̀ ń wá ìfẹ́,+ ẹni tí ó sì ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ọ̀ràn, ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.+ 10  Ìbáwí mímúná ń ṣiṣẹ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí ó ní òye+ ju lílu arìndìn ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.+ 11  Kìkì ìṣọ̀tẹ̀ ni ẹni búburú ń wá,+ ìkà sì ni ońṣẹ́ tí a rán sí i.+ 12  Ó yá kí ènìyàn pàdé béárì tí ó ṣòfò ọmọ+ rẹ̀ ju kí ó pàdé ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ arìndìn nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.+ 13  Ní ti ẹnikẹ́ni tí ń fi búburú san ire,+ ohun búburú kì yóò ṣí kúrò ní ilé rẹ̀.+ 14  Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde;+ nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.+ 15  Ẹnikẹ́ni tí ń pe ẹni burúkú ní olódodo+ àti ẹnikẹ́ni tí ń pe olódodo ní ẹni burúkú+—àní àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.+ 16  Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé iye owó láti fi ra ọgbọ́n ń bẹ ní ọwọ́ arìndìn,+ nígbà tí kò ní ọkàn-àyà?+ 17  Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà,+ ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.+ 18  Ènìyàn tí ọkàn-àyà kù fún a máa bọ ọwọ́,+ ní ṣíṣe onídùúró pátápátá níwájú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.+ 19  Ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìrélànàkọjá nífẹ̀ẹ́ ìjàkadì.+ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀ ní gíga ń wá ìfọ́yángá.+ 20  Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́kàn-àyà wíwọ́ kì yóò rí ire,+ ẹni tí ó bá sì ti yí po ní ahọ́n rẹ̀ yóò já sínú ìyọnu àjálù.+ 21  Ẹnikẹ́ni tí ó bí arìndìn ọmọ—ẹ̀dùn-ọkàn ni ó jẹ́ fún un;+ baba òpònú ọmọ kì í sì í yọ̀.+ 22  Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn,+ ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.+ 23  Ènìyàn burúkú yóò mú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ pàápàá ní oókan àyà+ láti yí ipa ọ̀nà ìdájọ́ po.+ 24  Ọgbọ́n wà níwájú olóye,+ ṣùgbọ́n ojú arìndìn wà ní ìkángun ilẹ̀ ayé.+ 25  Arìndìn ọmọ jẹ́ ìbìnújẹ́ fún baba rẹ̀+ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i.+ 26  Pẹ̀lúpẹ̀lù, bíbu ìtanràn lé olódodo kò dára.+ Láti kọlu àwọn ọ̀tọ̀kùlú lòdì sí ohun dídúró ṣánṣán.+ 27  Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀,+ ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.+ 28  Ẹni tí ó tilẹ̀ ya òmùgọ̀, nígbà tí ó bá dákẹ́, ni a ó kà sí ọlọ́gbọ́n;+ ẹni tí ó pa ètè ara rẹ̀ dé, ni a ó kà sí ẹni tí ó ní òye.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé