Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 16:1-33

16  Àwọn ìṣètò ọkàn-àyà jẹ́ ti ará ayé,+ ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn ahọ́n ti máa ń wá.+  Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó mọ́ gaara ní ojú ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n Jèhófà ni ó ń díwọ̀n àwọn ẹ̀mí.+  Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀,+ a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+  Ohun gbogbo ni Jèhófà ti ṣe fún ète rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni, àní ẹni burúkú fún ọjọ́ ibi.+  Olúkúlùkù ẹni tí ó gbéra ga ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.+ Ọwọ́ lè so pọ̀ mọ́ ọwọ́, síbẹ̀ ẹni náà kì yoo bọ́ lọ́wọ́ ìyà.+  Nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ ni a ń ṣètùtù fún ìṣìnà,+ àti nípa ìbẹ̀rù Jèhófà, ènìyàn a yí padà kúrò nínú ohun búburú.+  Nígbà tí Jèhófà bá ní ìdùnnú nínú àwọn ọ̀nà ènìyàn,+ ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.+  Díẹ̀ tòun ti òdodo,+ sàn ju ọ̀pọ̀ yanturu àmújáde láìsí ìdájọ́ òdodo.+  Ọkàn-àyà ará ayé lè gbìrò ọ̀nà ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ń darí àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀.+ 10  Ìpinnu onímìísí ni ó yẹ kí ó wà ní ètè ọba;+ kò yẹ kí ẹnu rẹ̀ jẹ́ aláìṣòótọ́ nínú ìdájọ́.+ 11  Àwọn atọ́ka-ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n títọ́ jẹ́ ti Jèhófà;+ gbogbo àwọn òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ń bẹ nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀.+ 12  Híhu ìwà burúkú jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún àwọn ọba,+ nítorí nípasẹ̀ òdodo ni ìtẹ́ fi ń fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ 13  Ètè òdodo jẹ́ ìdùnnú atóbilọ́lá ọba;+ ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun adúróṣánṣán.+ 14  Ìhónú ọba túmọ̀ sí àwọn ońṣẹ́ ikú,+ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni ẹni tí ń yẹ̀ ẹ́.+ 15  Inú ìmọ́lẹ̀ ojú ọba ni ìyè,+ ìfẹ́ rere rẹ̀ sì dà bí àwọsánmà òjò ìgbà ìrúwé.+ 16  Níní ọgbọ́n, ó mà kúkú sàn ju wúrà o!+ Níní òye sì ni kí a yàn ju fàdákà.+ 17  Òpópó àwọn adúróṣánṣán ni láti yí padà kúrò nínú ohun búburú.+ Ẹni tí ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́.+ 18  Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá,+ ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.+ 19  Ó sàn láti jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọlọ́kàn tútù+ ju láti pín ohun ìfiṣèjẹ pẹ̀lú àwọn tí ń gbé ara wọn ga.+ 20  Ẹni tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hàn nínú ọ̀ràn yóò rí ire,+ aláyọ̀ sì ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+ 21  Ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà ni a ó pè ní olóye,+ ẹni tí ètè rẹ̀ sì dùn ń fi ìyíniléròpadà kún un.+ 22  Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tí ó ni ín;+ ìbáwí àwọn òmùgọ̀ sì ni ìwà òmùgọ̀.+ 23  Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń mú kí ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀ òye hàn,+ èyí sì ń fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.+ 24  Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin,+ ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.+ 25  Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn,+ ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.+ 26  Ọkàn òṣìṣẹ́ kára ti ṣiṣẹ́ kára fún un,+ nítorí pé ẹnu rẹ̀ ti sún un tipátipá.+ 27  Ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun ń hú ohun tí ó burú jáde,+ àti ní ètè rẹ̀, ohun kan wà tí a lè pè ní iná tí ń jóni gbẹ.+ 28  Ènìyàn tí ń so ìpàǹpá ń rán asọ̀ jáde ṣáá,+ afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ sì ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.+ 29  Ènìyàn tí ń hu ìwà ipá yóò sún ọmọnìkejì rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀,+ dájúdájú, yóò mú kí ó rin ọ̀nà tí kò dára.+ 30  Ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò láti pète-pèrò àwọn ìpàǹpá.+ Ní kíká ètè rẹ̀ sínú, ṣe ni ó ń ṣe ibi ní àṣeparí. 31  Orí ewú jẹ́ adé ẹwà+ nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.+ 32  Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá,+ ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.+ 33  Orí itan ni a ń ṣẹ́ kèké lé,+ ṣùgbọ́n gbogbo ìpinnu tí a ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé