Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Òwe 13:1-25

13  Ọmọ a jẹ́ ọlọ́gbọ́n níbi tí ìbáwí baba bá wà,+ ṣùgbọ́n olùyọṣùtì ni èyí tí kò gbọ́ ìbáwí mímúná.+  Ènìyàn yóò jẹ ohun tí ó dára láti inú èso ẹnu rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ọkàn àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè jẹ́ ìwà ipá.+  Ẹni tí ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́.+ Ẹni tí ń ṣí ètè rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu—ìparun yóò jẹ́ tirẹ̀.+  Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan.+ Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.+  Àwọn olódodo kórìíra ọ̀rọ̀ èké,+ ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú, wọ́n sì ń fa ìtìjú bá ara wọn.+  Òdodo ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹni tí ó jẹ́ aláìlè-panilára ní ọ̀nà rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ìwà burúkú ni ohun tí ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.+  Ẹnì kan wà tí ń díbọ́n pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò ní nǹkan kan rárá;+ ẹnì kan wà tí ń díbọ́n pé òun jẹ́ aláìnílọ́wọ́, síbẹ̀síbẹ̀ ó ní ọ̀pọ̀ ohun tí ó níye lórí.  Ìràpadà ọkàn ènìyàn ni ọrọ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ kò gbọ́ ìbáwí mímúná.+  Àní ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo yóò yọ̀;+ ṣùgbọ́n fìtílà àwọn ẹni burúkú—a óò fẹ́ ẹ pa.+ 10  Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.+ 11  Àwọn ohun oníyelórí tí ó ti inú asán wá a máa kéré sí i níye,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọwọ́ kó jọ ni ẹni tí yóò máa pọ̀ sí i.+ 12  Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn,+ ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé ní ti tòótọ́.+ 13  Ẹni tí ó tẹ́ńbẹ́lú ọ̀rọ̀ náà,+ ohun ìdógò ajigbèsè ni a ó fi ipá gbà lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bẹ̀rù àṣẹ ni ẹni tí a ó san lẹ́san.+ 14  Òfin ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,+ láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.+ 15  Ìjìnlẹ̀ òye rere ń fúnni ní ojú rere,+ ṣùgbọ́n págunpàgun ni ọ̀nà àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè.+ 16  Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ arìndìn yóò tan ìwà òmùgọ̀ káàkiri.+ 17  Ońṣẹ́ tí ó jẹ́ ẹni burúkú yóò já sínú ohun búburú,+ ṣùgbọ́n olùṣòtítọ́ aṣojú jẹ́ ìmúniláradá.+ 18  Ẹni tí ó ṣàìnáání ìbáwí bọ́ sí ipò òṣì àti àbùkù,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mọ́ ni ẹni tí a ṣe lógo.+ 19  Ìfẹ́-ọkàn, nígbà tí a bá rí ìmúṣẹ rẹ̀, yóò dùn mọ́ ọkàn;+ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn arìndìn láti yí padà kúrò nínú ohun búburú.+ 20  Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.+ 21  Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ìyọnu àjálù ń lépa,+ ṣùgbọ́n àwọn olódodo ni ohun rere ń san lẹ́san.+ 22  Ẹni rere yóò fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ọmọ, ọlà ẹlẹ́ṣẹ̀ sì jẹ́ ohun tí a tò pa mọ́ fún olódodo.+ 23  Ilẹ̀ ríro àwọn aláìnílọ́wọ́ ń mú oúnjẹ púpọ̀ gan-an jáde,+ ṣùgbọ́n ẹnì kan wà tí a gbá lọ nítorí àìní ìdájọ́.+ 24  Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.+ 25  Olódodo ń jẹ títí yóò fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn,+ ṣùgbọ́n ikùn àwọn ẹni burúkú yóò ṣófo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé