Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 12:1-28

12  Olùfẹ́ ìbáwí jẹ́ olùfẹ́ ìmọ̀,+ ṣùgbọ́n olùkórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà jẹ́ aláìnírònú.+  Ẹni rere ń rí ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà,+ ṣùgbọ́n ènìyàn elérò-ọkàn burúkú ni ó ń pè ní ẹni burúkú.+  Kò sí ènìyàn kankan tí yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ ìwà burúkú;+ ṣùgbọ́n ní ti gbòǹgbò ìpìlẹ̀ àwọn olódodo, a kì yóò mú kí ó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.+  Aya tí ó dáńgájíá jẹ́ adé fún olúwa rẹ̀,+ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìjẹrà nínú egungun olúwa rẹ̀ ni obìnrin tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú.+  Ìrònú àwọn olódodo jẹ́ ìdájọ́;+ ìdarí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni burúkú jẹ́ ẹ̀tàn.+  Ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú jẹ́ lílúgọ de ẹ̀jẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹnu àwọn adúróṣánṣán ni yóò dá wọn nídè.+  Ìbìṣubú àwọn ẹni burúkú ṣẹlẹ̀, wọn kò sì sí mọ́,+ ṣùgbọ́n ilé àwọn olódodo yóò máa bá a nìṣó ní dídúró.+  A ó yin ènìyàn nítorí ẹnu rẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n inú hàn,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ onímàgòmágó ní ọkàn-àyà yóò wá di ìfojú-tín-ín-rín.+  Ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, ṣùgbọ́n tí ó ní ìránṣẹ́, sàn ju ẹni tí ń ṣe ara rẹ̀ lógo ṣùgbọ́n tí ó ṣaláìní oúnjẹ.+ 10  Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ìkà ni àánú àwọn ẹni burúkú.+ 11  Ẹni tí ń ro ilẹ̀ ara rẹ̀ ni a ó fi oúnjẹ tẹ́ òun fúnra rẹ̀ lọ́rùn,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.+ 12  Ojú ẹni burúkú wọ ẹran ọdẹ tí a fi àwọ̀n mú tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn búburú;+ ṣùgbọ́n ní ti gbòǹgbò àwọn olódodo, ó ń so.+ 13  Nípasẹ̀ ìrélànàkọjá ètè ni a ń dẹkùn mú ènìyàn búburú,+ ṣùgbọ́n olódodo yóò yọ kúrò nínú wàhálà.+ 14  Láti inú èso ẹnu ènìyàn ni a ti ń fi ohun rere tẹ́ ẹ lọ́rùn,+ àní ìgbòkègbodò iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn yóò padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.+ 15  Ọ̀nà òmùgọ̀ tọ̀nà ní ojú ara rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fetí sí ìmọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n.+ 16  Òmùgọ̀ ni ó máa ń sọ ìbínú rẹ̀ di mímọ̀ ní ọjọ́ kan náà,+ ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà a máa bo àbùkù mọ́lẹ̀.+ 17  Ẹni tí ń gbé ìṣòtítọ́ yọ a máa sọ ohun tí í ṣe òdodo,+ ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké, a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.+ 18  Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà,+ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.+ 19  Ètè òtítọ́+ ni a ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in títí láé,+ ṣùgbọ́n ahọ́n èké yóò wà fún kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú kan.+ 20  Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn-àyà àwọn tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ibi,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbani nímọ̀ràn àlàáfíà ń yọ̀.+ 21  Kò sí ohun aṣenilọ́ṣẹ́ tí yóò ṣẹlẹ̀ sí olódodo,+ ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ni àwọn tí yóò kún fún ìyọnu àjálù dájúdájú.+ 22  Ètè èké jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ hùwà jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+ 23  Afọgbọ́nhùwà ń bo ìmọ̀,+ ṣùgbọ́n ọkàn-àyà àwọn arìndìn ni èyí tí ń pòkìkí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.+ 24  Ọwọ́ àwọn ẹni aláápọn ni yóò ṣàkóso,+ ṣùgbọ́n ọwọ́ dẹngbẹrẹ yóò wá wà fún òpò àfipámúniṣe.+ 25  Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba,+ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.+ 26  Olódodo ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò pápá ìjẹko tirẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ẹni burúkú ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère.+ 27  Ìṣọwọ́dẹngbẹrẹ kì yóò mú àwọn ẹran tí ènìyàn ń ṣọdẹ rẹ̀ bẹ́ gìjà,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláápọn ni ọlà iyebíye ènìyàn. 28  Ìyè wà ní ipa ọ̀nà òdodo,+ ìrìn àjò ní òpópó ọ̀nà rẹ̀ kò sì túmọ̀ sí ikú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé