Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Òwe 11:1-31

11  Òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà,+ ṣùgbọ́n òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ó pé pérépéré jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.  Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé;+ ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.+  Ìwà títọ́ àwọn adúróṣánṣán ni ohun tí ń ṣamọ̀nà wọn,+ ṣùgbọ́n ìfèrúyípo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè ni yóò fi wọ́n ṣe ìjẹ.+  Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan,+ ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.+  Òdodo ẹni tí kò lẹ́bi ni yóò mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+ ṣùgbọ́n ẹni burúkú yóò ṣubú sínú ìwà burúkú òun fúnra rẹ̀.+  Òdodo àwọn adúróṣánṣán ni yóò dá wọn nídè,+ ṣùgbọ́n ìfàsí-ọkàn àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè ni a ó fi mú àwọn fúnra wọn.+  Nígbà tí ènìyàn burúkú bá kú, ìrètí rẹ̀ a ṣègbé;+ àní ìfojúsọ́nà tí a gbé ka orí agbára níní ti ṣègbé.+  Olódodo ni a gbà sílẹ̀ àní lọ́wọ́ wàhálà,+ ẹni burúkú sì wọlé dípò rẹ̀.+  Ẹnu ara rẹ̀ ni apẹ̀yìndà fi ń run ọmọnìkejì rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ìmọ̀ ni a fi ń gba olódodo sílẹ̀.+ 10  Nítorí ìwà rere àwọn olódodo, ìlú a kún fún ayọ̀,+ ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá ṣègbé, igbe ìdùnnú a ta.+ 11  Nítorí ìbùkún àwọn adúróṣánṣán, ìlú a ní ìgbéga,+ ṣùgbọ́n nítorí ẹnu àwọn ẹni burúkú, a di èyí tí a ya lulẹ̀.+ 12  Ẹni tí ọkàn-àyà kù fún ti tẹ́ńbẹ́lú ọmọnìkejì rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ gbígbòòrò ni ẹni tí ó dákẹ́.+ 13  Ẹni tí ń rìn káàkiri gẹ́gẹ́ bí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́+ a máa tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí a máa bo ọ̀ràn mọ́lẹ̀.+ 14  Nígbà tí kò bá sí ìdarí jíjáfáfá, àwọn ènìyàn a ṣubú;+ ṣùgbọ́n ìgbàlà wà nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.+ 15  Ó dájú pé ènìyàn yóò rí láburú nítorí pé ó lọ ṣe onídùúró fún àjèjì,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra bíbọ ọwọ́ yóò wà láìní àníyàn. 16  Obìnrin olóòfà ẹwà ni ó di ògo mú;+ ṣùgbọ́n àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, ní tiwọn, di ọrọ̀ mú. 17  Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá,+ ṣùgbọ́n ìkà ènìyàn ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ẹ̀yà ara òun fúnra rẹ̀.+ 18  Ẹni burúkú ń pa owó ọ̀yà èké,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn òdodo, ń jẹ èrè òótọ́.+ 19  Ẹni tí ó dúró gbọn-in gbọn-in fún òdodo wà ní ìlà fún ìyè,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ohun búburú wà ní ìlà fún ikú ara rẹ̀.+ 20  Àwọn oníwà wíwọ́ ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà,+ ṣùgbọ́n àwọn aláìlẹ́bi ní ọ̀nà wọ́n jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+ 21  Bí ọwọ́ tilẹ̀ wọ ọwọ́, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà;+ ṣùgbọ́n ọmọ àwọn olódodo yóò yè bọ́ dájúdájú.+ 22  Gẹ́gẹ́ bí òrùka imú oníwúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin tí ó jẹ́ arẹwà, ṣùgbọ́n tí ó yí padà kúrò nínú ìlóyenínú.+ 23  Ìfẹ́-ọkàn àwọn olódodo dára dájúdájú;+ ìrètí àwọn ẹni burúkú jẹ́ ìbínú kíkan.+ 24  Ẹnì kan wà tí ń fọ́n ká, síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i;+ àti ẹni tí ń fawọ́ sẹ́yìn kúrò nínú ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n àìní nìkan ni ó ń yọrí sí.+ 25  A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra,+ ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.+ 26  Ẹni tí ó bá ń fawọ́ ọkà sẹ́yìn—àwọn ènìyàn ìlú yóò fi í bú, ṣùgbọ́n ìbùkún ń bẹ fún orí ẹni tí ó jẹ́ kí a máa rà á.+ 27  Ẹni tí ó bá ń wá ohun rere yóò máa bá a nìṣó ní wíwá ìfẹ́ rere;+ ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ń wá ohun búburú káàkiri, yóò wá sórí rẹ̀.+ 28  Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀—òun fúnra rẹ̀ yóò ṣubú;+ ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ka eléwé ni olódodo yóò máa gbilẹ̀.+ 29  Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ilé ara rẹ̀,+ ẹ̀fúùfù ni yóò ní;+ òmùgọ̀ ènìyàn sì ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà. 30  Èso olódodo jẹ́ igi ìyè,+ ẹni tí ó bá sì ń jèrè àwọn ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.+ 31  Wò ó! Olódodo—ilẹ̀ ayé ni a ó ti san án lẹ́san.+ Mélòómélòó ni ó yẹ kí ẹni burúkú àti ẹlẹ́ṣẹ̀ rí bẹ́ẹ̀!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé