Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Òwe 1:1-33

1  Òwe+ Sólómọ́nì+ ọmọkùnrin Dáfídì,+ ọba Ísírẹ́lì,+  fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n+ àti ìbáwí,+ láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye,+  láti gba ìbáwí+ tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye,+ òdodo+ àti ìdájọ́+ àti ìdúróṣánṣán,+  láti fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà,+ láti fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀+ àti agbára láti ronú.+  Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni+ púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá,+  láti lóye òwe àti ọ̀rọ̀ àdììtú,+ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n+ àti àlọ́ wọn.+  Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀.+ Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú.+  Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba+ rẹ, má sì ṣá òfin ìyá+ rẹ tì.  Nítorí ọ̀ṣọ́ òdòdó fífanimọ́ra ni wọ́n jẹ́ fún orí+ rẹ àti àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún ọrùn+ rẹ. 10  Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá gbìyànjú láti sún ọ dẹ́ṣẹ̀, má gbà.+ 11  Bí wọ́n bá ń wí pé: “Bá wa lọ. Jẹ́ kí a ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀.+ Jẹ́ kí a ba sí ibi tí ó lùmọ́ de àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ láìnídìí.+ 12  Jẹ́ kí a gbé wọn mì láàyè+ bí Ṣìọ́ọ̀lù+ ti ń ṣe, àní lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+ 13  Jẹ́ kí a wá onírúurú ohun iyebíye tí ó níye lórí kàn.+ Jẹ́ kí a fi ohun ìfiṣèjẹ kún ilé wa.+ 14  Ó yẹ kí o da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ tiwa. Jẹ́ kí gbogbo wa jọ ní ẹyọ àpò kan ṣoṣo”+ 15  ọmọ mi, má ṣe bá wọn rìn pọ̀ ní ọ̀nà.+ Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò ní òpópónà wọn.+ 16  Nítorí ẹsẹ̀ wọn jẹ́ èyí tí ń sáré sí kìkì ìwà búburú,+ wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ 17  Nítorí lásán ni a tẹ́ àwọ̀n sílẹ̀ lójú ohunkóhun tí ó ní ìyẹ́ apá.+ 18  Nítorí náà, àwọn fúnra wọn ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ àwọn wọ̀nyí gan-an;+ wọ́n ba sí ibi tí ó lùmọ́ de ọkàn wọn.+ 19  Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo ẹni tí ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu rí.+ Ó máa ń gba ọkàn àwọn tí ó ni ín pàápàá lọ.+ 20  Ọgbọ́n+ tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó+ gan-an. Àwọn ojúde ìlú ni ó ti ń fọ ohùn+ rẹ̀ jáde. 21  Ìpẹ̀kun òkè àwọn ojú pópó aláriwo ni ó ti ń ké jáde.+ Ibi àtiwọ àwọn ẹnubodè tí ó wọ ìlú ńlá ni ó ti ń sọ àwọn àsọjáde tirẹ̀+ pé: 22  “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìní ìrírí yóò fi máa nífẹ̀ẹ́ àìní ìrírí,+ yóò sì ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin olùyọṣùtì yóò fi máa fẹ́ ìyọṣùtì+ gbáà fún ara yín, yóò sì ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin arìndìn yóò fi máa kórìíra ìmọ̀?+ 23  Yí padà nítorí ìbáwí àfitọ́nisọ́nà+ mi. Nígbà náà, èmi yóò mú kí ẹ̀mí mi tú jáde sórí yín;+ èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi di mímọ̀ fún yín dájúdájú.+ 24  Nítorí pé mo ti ké jáde, ṣùgbọ́n ẹ ń bá a nìṣó ní kíkọ̀,+ mo ti na ọwọ́ mi jáde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ń fetí sílẹ̀,+ 25  ẹ sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣàìnáání gbogbo ìmọ̀ràn mi,+ ẹ kò sì gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mi,+ 26  èmi pẹ̀lú, ní tèmi, yóò fi àjálù tiyín rẹ́rìn-ín,+ èmi yóò fi yín ṣe ẹlẹ́yà nígbà tí ohun tí ń mú ìbẹ̀rùbojo bá yín bá dé,+ 27  nígbà tí ohun tí ń mú ìbẹ̀rùbojo bá yín bá dé gẹ́gẹ́ bí ìjì, tí àjálù tiyín sì dé ìhín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù oníjì,+ nígbà tí wàhálà àti àwọn àkókò ìnira bá dé bá yín.+ 28  Ní àkókò yẹn, wọn yóò máa pè mí ṣáá, ṣùgbọ́n èmi kì yóò dá wọn lóhùn;+ wọn yóò máa wá mi ṣáá, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi,+ 29  nítorí ìdí náà pé wọ́n kórìíra ìmọ̀,+ ìbẹ̀rù Jèhófà ni wọn kò sì yàn.+ 30  Wọn kò gba ìmọ̀ràn mi;+ wọn kò bọ̀wọ̀ fún gbogbo ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mi.+ 31  Nítorí náà, wọn yóò jẹ nínú èso ọ̀nà wọn,+ a ó sì fi àwọn ìmọ̀ràn tiwọn rọ wọ́n yó.+ 32  Nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀+ àwọn aláìní ìrírí ni ohun tí yóò pa wọ́n,+ ìdẹra dẹngbẹrẹ àwọn arìndìn sì ni ohun tí yóò pa wọ́n run.+ 33  Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò,+ yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé