Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 9:1-11

9  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ohun rara ké ní etí mi, pé: “Ẹ mú kí àwọn tí wọ́n ń fún ìlú ńlá náà ní àfiyèsí sún mọ́ tòsí, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ fún mímú ìparun wá!”  Sì wò ó! àwọn ọkùnrin mẹ́fà ń bọ̀ láti ìhà ẹnubodè apá òkè,+ èyí tí ó dojú kọ àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà ìfọ́túútúú rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀; ọkùnrin kan sì wà láàárín wọn tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ pẹ̀lú ìwo yíǹkì akọ̀wé ní ìgbáròkó rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé, wọ́n sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ bàbà.+  Àti ní ti ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ a gbé e kúrò lórí àwọn kérúbù+ níbi tí ó wà tẹ́lẹ̀, wá sí ibi àbáwọ ilé náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí nahùn pe ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà,+ tí ìwo yíǹkì akọ̀wé wà ní ìgbáròkó rẹ̀.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “La àárín ìlú ńlá náà já, àárín Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora+ nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe ní àárín rẹ̀.”+  Ó sì sọ fún àwọn yòókù ní etí mi pé: “Ẹ la ìlú ńlá náà já tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, kí ẹ sì ṣe ìkọlù. Kí ojú yín má ṣe káàánú, ẹ má sì ní ìyọ́nú.+  Àgbà ọkùnrin, ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn obìnrin+ ni kí ẹ pa dànù—títí dórí rírun wọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sún mọ́ ènìyàn èyíkéyìí tí àmì náà wà lórí rẹ̀,+ láti ibùjọsìn mi ni kí ẹ sì ti bẹ̀rẹ̀.”+ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn arúgbó tí wọ́n wà níwájú ilé náà.+  Ó sì sọ fún wọn síwájú sí i pé: “Ẹ sọ ilé náà di ẹlẹ́gbin, kí ẹ sì fi àwọn tí a pa kún àwọn àgbàlá.+ Ẹ jáde lọ!” Wọ́n sì jáde lọ, wọ́n sì ṣe ìkọlù nínú ìlú ńlá náà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìkọlù, tí a sì fi èmi sílẹ̀, mo sì dojú bolẹ̀,+ mo sì ké jáde, mo wí pé: “Págà,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ìwọ yóò ha run gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì bí o ti ń da ìhónú rẹ jáde sórí Jerúsálẹ́mù?”+  Nítorí náà, ó wí fún mi pé: “Ìṣìnà ilé Ísírẹ́lì àti Júdà+ pọ̀ gidigidi,+ ilẹ̀ náà sì kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀,+ ìlú ńlá náà sì kún fún ìwà wíwọ́;+ nítorí wọ́n wí pé, ‘Jèhófà ti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀,+ Jèhófà kò sì ríran.’+ 10  Ní ti èmi pẹ̀lú, ojú mi kì yóò káàánú,+ èmi kì yóò sì fi ìyọ́nú hàn.+ Dájúdájú, èmi yóò mú ọ̀nà wọn wá sórí wọn.”+ 11  Sì wò ó! ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tí ìwo yíǹkì wà ní ìgbáròkó rẹ̀, mú ọ̀rọ̀ padà wá, pé: “Mo ti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti pàṣẹ fún mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé