Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 7:1-27

7  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ‘Òpin, àní òpin, ti dé sórí ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà.+  Òpin ti dé sórí rẹ wàyí,+ èmi yóò sì rán ìbínú mi sí ọ, èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ,+ èmi yóò sì mú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ wá sórí rẹ.  Ojú mi kì yóò sì káàánú fún ọ,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ní ìyọ́nú, nítorí èmi yóò mú àwọn ọ̀nà rẹ wá sórí rẹ, àárín rẹ ni àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ yóò sì wà;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ìyọnu àjálù, ìyọnu àjálù aláìláfijọ, wò ó! ó ń bọ̀.+  Òpin pàápàá gbọ́dọ̀ dé.+ Òpin gbọ́dọ̀ dé; ó gbọ́dọ̀ jí fún ọ. Wò ó! Ó ń bọ̀.+  Òdòdó ẹ̀yẹ gbọ́dọ̀ wá bá ọ, ìwọ olùgbé ilẹ̀ náà, àkókò gbọ́dọ̀ dé, ọjọ́ náà sún mọ́lé.+ Ìdàrúdàpọ̀ wà, kì í sì í ṣe igbe kíké ti àwọn òkè ńlá.  “‘Wàyí o, láìpẹ́ èmi yóò da ìhónú mi sórí rẹ,+ èmi yóò sì mú ìbínú mi lòdì sí ọ wá sí ìparí rẹ̀,+ èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ,+ gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ ni èmi yóò sì mú wá sórí rẹ.  Ojú mi kì yóò káàánú,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ní ìyọ́nú.+ Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ ni èmi yóò mú un wá sórí rẹ, àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ yóò wà ní àárín rẹ gan-an;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà tí ń ṣe ìkọlù náà.+ 10  “‘Wò ó! Ọjọ́ náà! Wò ó! Ó ń bọ̀.+ Òdòdó ẹ̀yẹ ti jáde lọ.+ Ọ̀pá ti yọ ìtànná.+ Ìkùgbù ti rú jáde.+ 11  Ìwà ipá ti dìde di ọ̀pá ìwà burúkú.+ Kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti inú ọlà wọn; kì í sì í ṣe láti ọwọ́ àwọn fúnra wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ọlá ògo kankan nínú wọn. 12  Àkókò gbọ́dọ̀ dé, ọjọ́ náà gbọ́dọ̀ dé. Ní ti olùrà, kí ó má ṣe yọ̀;+ àti ní ti olùtà, kí ó má wọnú ìṣọ̀fọ̀, nítorí pé ìmọ̀lára gbígbóná wà lòdì sí gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀. 13  Nítorí olùtà kì yóò padà sí ohun tí a tà, nígbà tí ó jẹ́ pé ìwàláàyè wọn ṣì wà láàárín àwọn alààyè; nítorí ìran náà wà fún gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kì yóò padà, olúkúlùkù wọn kì yóò sì ní ìwàláàyè rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣìnà òun fúnra rẹ̀. 14  “‘Wọ́n ti fun kàkàkí,+ gbogbo ènìyàn sì ti múra sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò kó wọnú ìjà ogun, nítorí pé ìmọ̀lára gbígbóná mi wà lòdì sí gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀.+ 15  Idà+ wà lóde, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú.+ Ẹnì yòówù tí ó bá wà nínú pápá, yóò tipa idà kú, àwọn tí ó bá sì wà nínú ìlú ńlá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò jẹ wọ́n run.+ 16  Àwọn olùsálà wọn yóò sá àsálà dájúdájú,+ wọn yóò sì wà lórí àwọn òkè ńlá bí àdàbà àfonífojì,+ tí gbogbo wọn ń kédàárò, olúkúlùkù nínú ìṣìnà rẹ̀. 17  Ní ti gbogbo ọwọ́, wọ́n ń rọ jọwọrọ;+ àti ní ti gbogbo eékún, omi ń ro tótó lára wọn.+ 18  Wọ́n sán aṣọ àpò ìdọ̀họ,+ ìgbọ̀njìnnìjìnnì sì ti bò wọ́n;+ ìtìjú sì bá gbogbo ojú,+ orí gbogbo wọn sì pá.+ 19  “‘Wọn yóò sọ fàdákà wọn pàápàá sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan ti Jèhófà.+ Wọn kì yóò tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, wọn kì yóò sì kún ìfun wọn, nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ tí ń fa ìṣìnà wọn.+ 20  Àti ìṣelóge ohun ọ̀ṣọ́ ẹni—ó ti gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdí fún ìyangàn; àwọn ère ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn,+ àwọn ohun ìríra wọn,+ ni wọ́n fi í ṣe. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ ọ́ di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.+ 21  Èmi yóò sì fi í lé àwọn àjèjì lọ́wọ́ fún ìpiyẹ́ àti fún àwọn ẹni burúkú ilẹ̀ ayé fún ohun ìfiṣèjẹ,+ wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́. 22  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì yí ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọn yóò sì sọ ibi ìkọ̀kọ̀ mi di aláìmọ́ ní ti tòótọ́, àwọn ọlọ́ṣà yóò sì wá sínú rẹ̀ ní tòótọ́, wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 23  “‘Ṣe ẹ̀wọ̀n,+ nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ìdájọ́ alábààwọ́n-ẹ̀jẹ̀,+ ìlú ńlá náà sì kún fún ìwà ipá.+ 24  Dájúdájú, èmi yóò sì mú àwọn tí ó burú jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè wá,+ ṣe ni wọn yóò sì gba àwọn ilé wọn,+ èmi yóò sì mú kí ìgbéraga àwọn alágbára kásẹ̀ nílẹ̀,+ a ó sì sọ ibùjọsìn wọn di aláìmọ́.+ 25  Làásìgbò yóò dé, wọn yóò sì wá àlàáfíà dájúdájú, ṣùgbọ́n kì yóò sí ìkankan.+ 26  Àgbákò lórí àgbákò yóò dé,+ ìròyìn lórí ìròyìn yóò wà, dájúdájú, àwọn ènìyàn yóò sì wá ìran láti ọ̀dọ̀ wòlíì,+ òfin pàápàá yóò ṣègbé kúrò lọ́dọ̀ àlùfáà àti ìmọ̀ràn kúrò lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà.+ 27  Ọba pàápàá yóò wọnú ìṣọ̀fọ̀;+ àní ìjòyè yóò fi ahoro wọ ara rẹ̀ ní aṣọ,+ ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sì rí ìyọlẹ́nu. Èmi yóò ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà wọn,+ àwọn ìdájọ́ wọn ni èmi yóò fi dá wọn lẹ́jọ́;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé