Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 6:1-14

6  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, gbé ojú rẹ sí ìhà àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀+ fún wọn.+  Kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè ńlá Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ:+ Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké,+ fún àwọn ojú ìṣàn omi àti fún àwọn àfonífojì: “Èmi rèé! Èmi yóò mú idà wá sórí yín, èmi yóò sì pa àwọn ibi gíga yín run dájúdájú.+  A ó sì sọ àwọn pẹpẹ yín di ahoro,+ àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a óò wó, èmi yóò sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ tí a pa ṣubú níwájú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín.+  Èmi yóò sì kó òkú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì síwájú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun yín yí àwọn pẹpẹ yín ká.+  Ní gbogbo ibi gbígbé yín,+ àwọn ìlú ńlá pàápàá yóò pa run di ahoro,+ àwọn ibi gíga yóò sì di ahoro, kí wọ́n lè wà ní ìparundahoro,+ kí àwọn pẹpẹ yín lè di ahoro, kí a sì wó wọn ní ti tòótọ́,+ kí a lè mú kí àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín kásẹ̀ nílẹ̀,+ kí a sì ké àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀,+ kí a sì nu àwọn iṣẹ́ yín kúrò.  Ẹni tí a pa yóò ṣubú dájúdájú ní àárín yín,+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+  “‘“Nígbà tí ó bá sì ṣẹlẹ̀, èmi yóò jẹ́ kí ẹ ní gẹ́gẹ́ bí àṣẹ́kù, àwọn tí ó sá àsálà kúrò lọ́wọ́ idà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, nígbà tí ẹ bá tú ká sí àwọn ilẹ̀ náà.+  Àwọn tí ó sálà nínú yín yóò rántí mi dájúdájú láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti mú wọn ní òǹdè,+ nítorí ìdààmú ti bá mi nítorí ọkàn-àyà wọn tí ń ṣe àgbèrè, tí ó yà kúrò lọ́dọ̀ mi+ àti nítorí ojú wọn tí ń tọ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn+ lẹ́yìn nínú àgbèrè; wọn yóò sì ní ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin ní ojú wọn nítorí ohun búburú tí wọ́n ti ṣe nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn.+ 10  Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà; èmi kò sọ̀rọ̀ lásán+ nípa ṣíṣe ohun tí ó kún fún ìyọnu àjálù yìí sí wọn.”’+ 11  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Pàtẹ́wọ́,+ kí o sì fẹsẹ̀ kilẹ̀, kí o sì wí pé: “Págà!” ní tìtorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí búburú ilé Ísírẹ́lì,+ nítorí pé nípa idà,+ nípa ìyàn+ àti nípa àjàkálẹ̀ àrùn ni wọn yóò ṣubú.+ 12  Ní ti ẹni tí ó jìnnà réré,+ nípa àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò kú; àti ní ti ẹni tí ó wà nítòsí, nípa idà ni yóò ṣubú; àti ní ti ẹni tí ó ṣẹ́ kù tí a sì fi ìṣọ́ ṣọ́, nípa ìyàn ni yóò kú, èmi yóò sì mú ìhónú mi wá sí ìparí lára wọn.+ 13  Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí àwọn ènìyàn wọn tí a pa yóò bá wà ní àárín àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn,+ yí ká àwọn pẹpẹ wọn,+ lórí gbogbo òkè kékeré tí ó ga,+ ní orí gbogbo àwọn òkè ńlá+ àti lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ àti lábẹ́ gbogbo igi ẹlẹ́ka púpọ̀,+ ibi tí wọ́n ti rúbọ òórùn amáratuni sí gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn.+ 14  Èmi yóò sì na ọwọ́ mi jáde lòdì sí wọn,+ èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro, àní ìsọdahoro tí ó burú ju aginjù níhà Díbílà, ní gbogbo ibi gbígbé wọn. Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé