Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 5:1-17

5  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú idà mímú kan fún ara rẹ. Gẹ́gẹ́ bí abẹ fẹ́lẹ́ ti onígbàjámọ̀ ni kí o mú un fún ara rẹ, kí o sì mú un kọjá lọ ní orí rẹ àti ní irùngbọ̀n rẹ,+ kí o sì mú òṣùwọ̀n fún ara rẹ, kí o sì pín irun náà sí ìpín-ìpín.  Ìdá mẹ́ta ni ìwọ yóò fi iná sun ní àárín ìlú ńlá náà ní gbàrà tí ọjọ́ ìsàgatì náà bá ti pé.+ Kí o sì kó ìdá mẹ́ta mìíràn. Ìwọ yóò fi idà ṣá a yí ìlú ńlá náà ká,+ ìdá mẹ́ta tí ó kẹ́yìn ni ìwọ yóò sì tú ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì fa idà yọ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.+  “Kí o sì kó díẹ̀ níbẹ̀, kí o sì dì wọ́n sínú ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ.+  Ìyókù wọn ni kí o kó, kí o sì kó wọn sínú iná, kí o sì sun wọ́n deérú nínú iná. Láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Èyí ni Jerúsálẹ́mù. Àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni mo gbé e kalẹ̀ sí, pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ní gbogbo àyíká rẹ̀.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìwà burúkú ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ,+ ó sì lòdì sí àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi ju àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, nítorí wọ́n kọ àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi sílẹ̀, àti ní ti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, wọn kò rìn nínú wọn.’+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé ẹyin jẹ́ oníjàgídíjàgan+ ju àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká, ẹ kò rìn nínù àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi ni ẹ kò sì mú ṣe;+ ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpinnu ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká, ni ẹ̀yin ṣe, àbí ẹ kò ṣe bẹ́ẹ̀?+  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ ọ́, ìwọ ìlú ńlá, àní èmi,+ èmi yóò sì mú àwọn ìpinnu ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún ní àárín rẹ, ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè.+  Èmi yóò sì ṣe ohun tí èmi kò tíì ṣe rí nínú rẹ, irú èyí tí èmi kì yóò sì tún ṣe mọ́ nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ.+ 10  “‘“Nítorí náà, àwọn baba yóò jẹ àwọn ọmọ ní àárín rẹ,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn baba wọn, èmi yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún nínú rẹ, èmi yóò sì tú gbogbo ìyókù rẹ ká sínú gbogbo ẹ̀fúùfù.”’+ 11  “‘Nítorí náà, bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘dájúdájú, nítorí ìdí náà pé ìwọ fi gbogbo ohun ìríra+ rẹ àti gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ rẹ sọ ibùjọsìn mi di ẹlẹ́gbin, èmi alára pẹ̀lú ni Ẹni tí yóò dín ọ kù,+ ojú mi kì yóò káàánú,+ èmi alára pẹ̀lú kì yóò fi ìyọ́nú hàn.+ 12  Ìdá mẹ́ta rẹ—nípa àjàkálẹ̀ àrùn ni wọn yóò kú,+ nípa ìyàn sì ni wọn yóò wá sí òpin wọn ní àárín rẹ.+ Ìdá mẹ́ta mìíràn—nípa idà ni wọn yóò ṣubú ní gbogbo àyíká rẹ. Ìdá mẹ́ta tí ó kẹ́yìn ni èmi yóò fọ́n ká, àní sínú gbogbo ẹ̀fúùfù,+ idà sì ni èmi yóò fà yọ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.+ 13  Dájúdájú, ìbínú mi yóò wá sí ìparí rẹ̀,+ èmi yóò sì pẹ̀rọ̀ sí ìhónú mi lórí wọn,+ èmi yóò sì tu ara mi nínú;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ̀rọ̀ nínú fífi tí mo fi dandan lé ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe,+ nígbà tí mo bá mú ìhónú mi wá sí ìparí lára wọn. 14  “‘Èmi yóò sì sọ ọ́ di ibi ìparundahoro àti ẹ̀gàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí ọ ká, lójú gbogbo ẹni tí ń kọjá lọ.+ 15  Ìwọ yóò sì di ẹ̀gàn+ àti ohun ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn,+ àpẹẹrẹ akini-nílọ̀+ àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìhónú àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà tí ó kún fún ìhónú+ gbé ìgbésẹ̀ ìdájọ́ nínú rẹ. Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́. 16  “‘Nígbà tí mo bá rán ọfà aṣeniléṣe ti ìyàn sórí wọn,+ èyí tí yóò wà fún ìparun, àwọn ọfà tí èmi yóò rán láti run yín,+ àní ìyàn ni èmi yóò mú pọ̀ sí i lórí yín, èmi yóò sì ṣẹ́ àwọn ọ̀pá yín tí a fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí.+ 17  Èmi yóò sì rán ìyàn àti àwọn ẹranko ẹhànnà aṣeniléṣe+ sí yín, wọn yóò sì mú kí ẹ ṣòfò ọmọ, àjàkálẹ̀ àrùn+ àti ẹ̀jẹ̀+ yóò sì là ọ́ kọjá, idà ni èmi yóò sì mú wá sórí rẹ.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé