Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 46:1-24

46  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní ti ẹnubodè àgbàlá inú lọ́hùn-ún tí ó dojú kọ ìlà-oòrùn,+ kí ó wà ní títì+ fún ọjọ́ iṣẹ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà,+ kí a ṣí i ní ọjọ́ sábáàtì, kí a sì ṣí i+ ní ọjọ́ òṣùpá tuntun.  Kí ìjòyè sì gba ti gọ̀bì ẹnubodè+ wọlé, láti òde, kí ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè;+ kí àwọn àlùfáà sì rú odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀, kí ó sì tẹrí ba lórí ibi àbáwọ ẹnubodè,+ kí ó sì jáde lọ, ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ ti ẹnubodè náà títí di alẹ́.  Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò sì máa tẹrí ba ní ibi àtiwọ ẹnubodè yẹn ní àwọn sábáàtì àti ní àwọn òṣùpá tuntun, níwájú Jèhófà.+  “‘Odindi ọrẹ ẹbọ sísun tí ìjòyè náà yóò mú wá síwájú Jèhófà ní ọjọ́ sábáàtì yóò jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà tí ara wọn dá ṣáṣá àti àgbò kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá;+  àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò náà,+ àti fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà, ọrẹ ẹbọ ọkà bí òun ṣe lè mú wá tó,+ àti pé, ní ti òróró, òṣùwọ̀n hínì kan fún òṣùwọ̀n eéfà kan.+  Àti ní ọjọ́ òṣùpá tuntun,+ kí ẹgbọrọ akọ màlúù kan wà, ọmọ ọ̀wọ́ ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan; àwọn tí ara wọn dá ṣáṣá ni kí wọ́n jẹ́.+  Òṣùwọ̀n eéfà kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò kan sì ni kí ó fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà, àti fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára rẹ̀ ká; àti pé, ní ti òróró, òṣùwọ̀n hínì kan fún òṣùwọ̀n eéfà kan.+  “‘Nígbà tí ìjòyè+ náà bá sì wọlé, gọ̀bì ẹnubodè ni kí ó gbà wọlé, ibẹ̀ sì ni kí ó gbà jáde.+  Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá sì wá síwájú Jèhófà ní àwọn àkókò àjọyọ̀,+ ẹni tí ó bá gba ti ẹnubodè àríwá+ wọlé láti tẹrí ba, kí ó gba ti ẹnubodè gúúsù+ jáde; ẹni tí ó bá sì gba ti ẹnubodè gúúsù wọlé, kí ó gba ti ẹnubodè ìhà àríwá jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ti ẹnubodè tí ó gbà wọlé padà, nítorí pé ọ̀kánkán rẹ̀ tààrà ni kí ó gbà jáde. 10  Àti ní ti ìjòyè àárín wọn, nígbà tí wọ́n bá wọlé, ni kí ó wọlé; nígbà tí wọ́n bá sì jáde, ni kí ó jáde.+ 11  Àti ní àwọn àjọyọ̀+ àti ní àwọn àkókò àjọyọ̀, kí ọrẹ ẹbọ ọkà jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù náà àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò náà, àti fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà gẹ́gẹ́ bí òun ṣe lè mú wá tó; àti pé, ní ti òróró, òṣùwọ̀n hínì kan fún òṣùwọ̀n eéfà kan.+ 12  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìjòyè náà pèsè odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, tàbí àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà, kí ẹnì kan ṣí ẹnubodè tí ó dojú kọ ìlà-oòrùn+ fún un, kí òun sì pèsè odindi ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ sábáátì.+ Kí ó sì jáde, kí ẹnì kan sì ti ẹnubodè lẹ́yìn tí ó bá jáde.+ 13  “‘Akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, ní ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́, ni kí o pèsè gẹ́gẹ́ bí odindi ọrẹ ẹbọ sísun lójoojúmọ́ sí Jèhófà.+ Òròòwúrọ̀ ni kí o máa pèsè rẹ̀. 14  Àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà, kí o máa pèsè ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà pẹ̀lú rẹ̀ ní òròòwúrọ̀ àti pé, ní ti òróró, ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì fún fífi wọ́n ìyẹ̀fun kíkúnná.+ Ọrẹ ẹbọ ọkà fún Jèhófà jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, nígbà gbogbo. 15  Kí wọ́n sì máa pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti òróró ní òròòwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí odindi ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.’ 16  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjòyè náà fi ẹ̀bùn fún olúkúlùkù àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀, èyí yóò di dúkìá ti àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun ìní wọn ni nípasẹ̀ ogún. 17  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ó fi ẹ̀bùn láti inú ogún rẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò sì di tirẹ̀ pẹ̀lú títí di ọdún ìdásílẹ̀ lómìnira;+ yóò sì padà sọ́dọ̀ ìjòyè náà. Kìkì ogún rẹ̀—ní ti àwọn ọmọ rẹ̀—ni kí ó máa bá a lọ láti jẹ́ tiwọn. 18  Ìjòyè náà kò sì gbọ́dọ̀ gba èyíkéyìí nínú ogún àwọn ènìyàn láti fipá lé wọn kúrò nínú ohun ìní wọn.+ Láti inú ohun ìní rẹ̀ ni kí ó ti fi ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a má bàa tú àwọn ènìyàn mi ká, olúkúlùkù kúrò nínú ohun ìní rẹ̀.’”+ 19  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gba ti ọ̀nà àbáwọlé+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè wọlé sí àwọn yàrá ìjẹun mímọ́, àwọn tí ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà, tí wọ́n dojú kọ àríwá,+ sì wò ó! àyè kan wà níbẹ̀ ní ìhà ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ní ìwọ̀-oòrùn. 20  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún mi pé: “Èyí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti máa se ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ àti ibi tí wọn yóò ti máa yan ọrẹ ẹbọ ọkà,+ kí a má bàa gbé nǹkan kan jáde wá sí àgbàlá òde láti sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́.”+ 21  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi jáde wá sí àgbàlá òde, ó sì mú mi kọjá lọ síbi arópòódògiri igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti àgbàlá náà, sì wò ó! àgbàlá kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ arópòódògiri igun ìhín nínú àgbàlá náà, àgbàlá kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ arópòódògiri igun tọ̀hún nínú àgbàlá náà. 22  Níbi arópòódogiri igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbàlá náà ni àwọn àgbàlá kéékèèké wà, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ọgbọ̀n ní fífẹ̀. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹ̀lú igun ohun tí a kọ́, ní ìwọ̀n kan náà. 23  Ẹsẹ kan sì wà yí wọn ká, yí ká àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àwọn ibi ìse-nǹkan+ sì wà tí a ṣe sábẹ́ àwọn ẹsẹ náà yí ká. 24  Nígbà náà ni ó wí fún mi pé: “Ìwọnyí ni ilé àwọn tí ń se nǹkan, níbi tí àwọn òjíṣẹ́ Ilé náà ti ń se ẹbọ àwọn ènìyàn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé