Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 45:1-25

45  “‘Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún,+ kí ẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà,+ ìpín mímọ́ láti inú ilẹ̀ náà;+ ní ti gígùn rẹ̀, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àti ní ti fífẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.+ Yóò jẹ́ ìpín mímọ́ ní gbogbo ààlà rẹ̀ yíká-yíká.  Láti inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta níbùú, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lóòró yóò jẹ́ ti ibi mímọ́, yóò dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yí ká;+ yóò ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìjẹko ní ìhà kọ̀ọ̀kan.+  Láti inú ìwọ̀n yìí, ìwọ yóò wọn ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀, inú rẹ̀ sì ni ibùjọsìn yóò wá wà, ohun mímọ́ jù lọ.+  Gẹ́gẹ́ bí ìpín mímọ́ láti inú ilẹ̀ náà, yóò wá jẹ́ ti àwọn àlùfáà fúnra wọn,+ àwọn òjíṣẹ́ ibùjọsìn, àwọn tí ń sún mọ́ tòsí láti ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà.+ Yóò sì jẹ́ àyè ilé fún wọn, àti àyè ọlọ́wọ̀ fún ibùjọsìn náà.  “‘Ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀+ yóò wà. Yóò di ti àwọn ọmọ Léfì, àwọn òjíṣẹ́ Ilé náà. Wọn yóò ní ogún yàrá ìjẹun+ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.  “‘Àti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ìlú ńlá, ẹ ó yọ̀ǹda ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀ àti ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní gígùn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́.+ Yóò wá jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.  “‘Ohun kan níhà ìwọ̀-oòrùn síhà ìwọ̀-oòrùn àti ohun kan níhà ìlà-oòrùn síhà ìlà-oòrùn yóò sì wà fún ìjòyè ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún ọrẹ mímọ́+ àti ti ohun ìní ìlú ńlá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọrẹ mímọ́ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun ìní ìlú ńlá. Gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ bákan náà gẹ́lẹ́ bí ti ọ̀kan nínú àwọn ìpín náà, láti ààlà ìwọ̀-oòrùn dé ààlà ìlà-oòrùn.+  Ní ti ilẹ̀ náà, yóò jẹ́ tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ní Ísírẹ́lì. Àwọn ìjòyè mi kì yóò sì ṣe àwọn ènìyàn mi níkà mọ́,+ wọn yóò sì fi ilẹ̀ náà fún ilé Ísírẹ́lì ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà wọn.’+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ó tó gẹ́ẹ́ yín, ẹ̀yin ìjòyè Ísírẹ́lì!’+ “‘Ẹ mú ìwà ipá àti ìfiṣèjẹ kúrò,+ kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo pàápàá.+ Ẹ gbé ìgbatọwọ́-ẹni yín kúrò lórí àwọn ènìyàn mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 10  ‘Àwọn òṣùwọ̀n pípéye àti òṣùwọ̀n eéfà pípéye àti òṣùwọ̀n báàfù pípéye ni kí ẹ ní.+ 11  Ní ti òṣùwọ̀n eéfà àti ti báàfù, kìkì ìwọ̀n kan ṣoṣo tí a fi lélẹ̀ pàtó ni kí ó wà, fún báàfù láti gba ìdá mẹ́wàá hómérì, kí ìdá mẹ́wàá hómérì sì gba eéfà kan;+ ní ti hómérì, ìwọ̀n rẹ̀ tí a béèrè ni kí ó jẹ́. 12  Ṣékélì+ sì jẹ́ ogún gérà.+ Ogún ṣékélì, ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni kí ó jẹ́ mánẹ̀ fún yín.’ 13  “‘Èyí ni ọrẹ tí ẹ óò mú wá, ìdá mẹ́fà eéfà láti inú hómérì kan ti àlìkámà, ìdá mẹ́fà eéfà láti inú hómérì kan ti ọkà bálì; 14  àti ní ti òróró tí a yọ̀ǹda, ó jẹ́ òṣùwọ̀n báàfù ti òróró. Báàfù jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n kọ́ọ̀. Báàfù mẹ́wàá jẹ́ hómérì kan; nítorí pé báàfù mẹ́wàá ni hómérì kan. 15  Àti àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba nínú ohun ọ̀sìn Ísírẹ́lì,+ fún ọrẹ ẹbọ ọkà+ àti fún odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ àti fún àwọn ẹbọ ìdàpọ̀,+ láti ṣe ètùtù fún wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 16  “‘Ní ti gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà, àwọn ni yóò ni ẹrù iṣẹ́ láti mú ọrẹ+ yìí wá fún ìjòyè ní Ísírẹ́lì.+ 17  Ìjòyè+ ni odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ yóò já lé léjìká nígbà àwọn àjọyọ̀+ àti nígbà òṣùpá tuntun+ àti nígbà àwọn sábáàtì,+ ní gbogbo àkókò àjọyọ̀ ilé Ísírẹ́lì.+ Òun ni yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù nítorí ilé Ísírẹ́lì.’ 18  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, kí o mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan, ọmọ ọ̀wọ́ ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá,+ kí o sì wẹ ibùjọsìn mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+ 19  Kí àlùfáà sì mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi í sára òpó ilẹ̀kùn+ Ilé náà àti sára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó lọ yí ká, tí ó jẹ́ ti pẹpẹ+ àti sára òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè àgbàlá inú lọ́hùn-ún. 20  Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì ṣe ní ọjọ́ keje ní oṣù náà, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe+ àti nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí; kí ẹ sì ṣe ètùtù fún Ilé náà.+ 21  “‘Ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà, kí ìrékọjá+ wà fún yín. Gẹ́gẹ́ bí àjọyọ̀ fún ọjọ́ méje, àkàrà aláìwú ni kí ẹ jẹ.+ 22  Àti ní ọjọ́ yẹn, nítorí ara rẹ̀ àti nítorí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà, kí ìjòyè náà pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 23  Àti fún ọjọ́ méje àjọyọ̀ náà,+ kí ó pèsè odindi ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà, ẹgbọrọ akọ màlúù méje àti àgbò méje, àwọn tí ara wọn dá ṣáṣá, lójoojúmọ́ fún ọjọ́ méje,+ àti àwọn akọ ewúrẹ́ lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 24  Àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà, òṣùwọ̀n eéfà kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù náà àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò náà ni kí ó pèsè, àti pé, ní ti òróró, òṣùwọ̀n hínì kan fún òṣùwọ̀n eéfà kan.+ 25  “‘Ní oṣù keje, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, nígbà àjọyọ̀,+ kí ó pèsè àwọn ohun bí ìwọ̀nyí fún ọjọ́ méjèèje,+ gẹ́gẹ́ bí ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, bí odindi ọrẹ ẹbọ sísun, àti bí ọrẹ ẹbọ ọkà àti bí òróró.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé