Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 44:1-31

44  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gba ti ẹnubodè ibùjọsìn padà wá, ti òde tí ó dojú kọ ìlà-oòrùn,+ ó sì wà ní títì.+  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Ní ti ẹnubodè yìí, títì ni yóò wà. A kì yóò ṣí i, ènìyàn lásán-làsàn kì yóò gba ibẹ̀ wọlé; nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ti gba ibẹ̀ wọlé, yóò sì wà ní títì.  Àmọ́ ṣá o, ìjòyè+—gẹ́gẹ́ bí ìjòyè, òun alára yóò jókòó nínú rẹ̀, láti jẹ oúnjẹ níwájú Jèhófà.+ Gọ̀bì ẹnubodè ni òun yóò gbà wọlé, ibẹ̀ sì ni yóò gbà jáde.”+  Wàyí o, ó mú mi gba ti ẹnubodè àríwá wá síwájú Ilé náà, kí n lè rí i, sì wò ó! ògo Jèhófà kún ilé Jèhófà.+ Mo sì dojú bolẹ̀.+  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, fi ọkàn-àyà sí i,+ kí o sì fi ojú rẹ rí i, kí o sì fi etí rẹ gbọ́ gbogbo ohun tí èmi yóò sọ fún ọ nípa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ ilé Jèhófà àti nípa gbogbo òfin rẹ̀, kí o sì fi ọkàn-àyà rẹ sí ọ̀nà àbáwọ Ilé náà pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà àbájáde ibùjọsìn.  Kí o sì wí fún Ìṣọ̀tẹ̀,+ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yín, ilé Ísírẹ́lì,+  nígbà tí ẹ mú àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà àti àwọn aláìdádọ̀dọ́ ẹran ara,+ wọlé wá, kí ó lè wà nínú ibùjọsìn mi láti sọ ọ́ di aláìmọ́, àní ilé mi; nígbà tí ẹ gbé oúnjẹ mi,+ ọ̀rá+ àti ẹ̀jẹ̀+ wá, nígbà tí wọ́n ti wà lẹ́nu bíba májẹ̀mú mi jẹ́ ní tìtorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yín.+  Ẹ kò bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti àwọn ohun mímọ́ mi,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò yan àwọn ẹlòmíràn sí àyè iṣẹ́ fún ara yín gẹ́gẹ́ bí olùbójútó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe mi nínú ibùjọsìn mi.”’+  “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà àti aláìdádọ̀dọ́ ẹran ara, kò gbọ́dọ̀ wá sínú ibùjọsìn mi, èyíinì ni, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè èyíkéyìí tí ó wà ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”’+ 10  “‘Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ́ mi+ nígbà tí Ísírẹ́lì, tí ó rìn gbéregbère lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, rìn gbéregbère tọ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn lẹ́yìn, wọn yóò ru ìṣìnà wọn pẹ̀lú.+ 11  Nínú ibùjọsìn mi, wọn yóò di òjíṣẹ́ níbi iṣẹ́ àbójútó lórí àwọn ẹnubodè Ilé náà àti àwọn òjíṣẹ́ ní Ilé náà.+ Àwọn alára ni yóò máa pa odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ fún àwọn ènìyàn náà,+ àwọn alára ni yóò sì máa dúró níwájú wọn láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+ 12  Nítorí ìdí náà pé wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn,+ tí wọ́n sì di ohun ìkọ̀sẹ̀ sínú ìṣìnà+ fún ilé Ísírẹ́lì, ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ọwọ́ mi sókè lòdì sí wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘wọn yóò sì ru ìṣìnà wọn. 13  Wọn kì yóò sì tọ̀ mí wá láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi tàbí láti sún mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun mímọ́ mi, láti sún mọ́ ohun mímọ́ jù lọ,+ wọn yóò sì ru ìtẹ́lógo wọn àti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn tí wọ́n ṣe.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ wọ́n di olùbójútó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe Ilé náà, nípa gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti ní ti gbogbo ohun tí a ó ṣe nínú rẹ̀.’+ 15  “‘Àti ní ti àwọn àlùfáà ọmọ Léfì,+ àwọn ọmọ Sádókù,+ àwọn tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ibùjọsìn mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn gbéregbère lọ kúrò lọ́dọ̀ mi,+ àwọn alára yóò sún mọ́ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, wọn yóò sì dúró níwájú mi+ láti gbé ọ̀rá+ àti ẹ̀jẹ̀+ wá síwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 16  ‘Àwọn ni yóò wá sínú ibùjọsìn mi,+ àwọn alára ni yóò sì sún mọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi,+ wọn yóò sì bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún mi.+ 17  “‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí wọ́n bá wá sínú àwọn ẹnubodè àgbàlá inú lọ́hùn-ún, ẹ̀wù ọ̀gbọ̀ ni kí wọ́n wọ̀, wọn kò gbọ́dọ̀ wọ irun àgùntàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnubodè àgbàlá inú lọ́hùn-ún àti ní inú.+ 18  Ìwérí tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ni kí ó wà lórí wọn,+ ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀gbọ̀ sì ni kí ó wà ní ìgbáròkó wọn.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ fi ohun tí ń fa òógùn di ara wọn lámùrè. 19  Nígbà tí wọ́n bá sì jáde lọ sí àgbàlá òde, àní sí àgbàlá òde sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, kí wọ́n bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ṣe ìránṣẹ́+ kúrò lára, kí wọ́n sì kó wọn sí àwọn yàrá ìjẹun mímọ́,+ kí wọ́n sì wọ ẹ̀wù mìíràn, kí wọ́n má bàa fi ẹ̀wù+ wọn sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́. 20  Wọn kò sì gbọ́dọ̀ fá+ orí wọn, wọn kò sì gbọ́dọ̀ tú irun orí wọn sílẹ̀ jọwọrọ. Wọ́n ní láti gé irun orí wọn.+ 21  Èyíkéyìí nínú àwọn àlùfáà kò sì gbọ́dọ̀ mu wáìnì kankan nígbà tí wọ́n bá wá sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún.+ 22  Wọn kò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ opó tàbí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ ṣe aya+ fún ara wọn, ṣùgbọ́n wúńdíá nínú àwọn ọmọ ilé Ísírẹ́lì+ tàbí opó tí ó jẹ́ opó àlùfáà ni wọ́n lè fẹ́.’ 23  “‘Kí wọ́n sì fún àwọn ènìyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́; kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tí ó mọ́.+ 24  Àti nínú ẹjọ́, àwọn tìkára wọn ni kí ó dìde dúró láti ṣe ìdájọ́;+ àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi sì ni kí wọ́n fi dá a.+ Kí wọ́n sì pa àwọn òfin mi àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi nípa gbogbo àkókò àjọyọ̀+ mi mọ́, kí wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́.+ 25  Òun kò sì gbọ́dọ̀ wọlé tọ òkú aráyé láti di aláìmọ́, ṣùgbọ́n nítorí baba tàbí nítorí ìyá tàbí nítorí ọmọkùnrin tàbí nítorí ọmọbìnrin tàbí nítorí arákùnrin tàbí nítorí arábìnrin tí kò ní ọkọ ni wọ́n fi lè sọ ara wọn di aláìmọ́.+ 26  Lẹ́yìn ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀, ọjọ́ méje ni kí wọ́n kà fún un.+ 27  Ní ọjọ́ tí yóò wá sí ibi mímọ́, sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, láti ṣe ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́, kí ó mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 28  “‘Kí ó sì di tiwọn gẹ́gẹ́ bí ogún: Èmi ni ogún wọn.+ Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fún wọn ní ohun ìní kankan ní Ísírẹ́lì: Èmi ni ohun ìní wọn. 29  Ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi—àwọn ni yóò máa jẹ wọ́n.+ Àti gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì—tiwọn ni yóò jẹ́.+ 30  Àti àkọ́kọ́ nínú gbogbo àkọ́pọ́n èso ohun gbogbo àti gbogbo ọrẹ ohun gbogbo tí ó wá láti inú gbogbo ọrẹ yín—ti àwọn àlùfáà ni yóò jẹ́;+ àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà yín ni kí ẹ sì fi fún àlùfáà,+ láti mú kí ìbùkún wà lórí ilé rẹ.+ 31  Òkú ẹran àti ẹ̀dá tí a fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú àwọn ẹ̀dá tí ń fò tàbí nínú àwọn ẹranko ni àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ jẹ.’+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé