Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 43:1-27

43  Lẹ́yìn náà, ó mú kí n lọ sí ẹnubodè, ẹnubodè tí ó dojú kọ ìlà-oòrùn.+  Sì wò ó! ògo+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ń bọ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn,+ ohùn rẹ̀ sì dà bí ohùn alagbalúgbú omi;+ ilẹ̀ ayé pàápàá mọ́lẹ̀ yòò nítorí ògo rẹ̀.+  Ó sì dà bí ìrísí ìran tí mo rí,+ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti run ìlú ńlá náà;+ àwọn ìrísí sì wà tí ó dà bí ìrísí tí mo rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò Kébárì,+ mo sì dojú bolẹ̀.  Ògo+ Jèhófà sì wá sínú Ilé náà láti ọ̀nà ẹnubodè tí iwájú rẹ̀ dojú kọ ìlà-oòrùn.+  Ẹ̀mí sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé mi sókè,+ ó sì mú mi wá sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, sì wò ó! Ilé náà kún fún ògo Jèhófà.+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ẹnì kan tí ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Ilé náà,+ ọkùnrin náà sì wá dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí ni ibi ìtẹ́ mi+ àti ibi àtẹ́lẹsẹ̀ mi,+ ibi tí èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ àwọn, ìyẹn ilé Ísírẹ́lì, wọn kì yóò sì sọ orúkọ mímọ́ mi+ di ẹlẹ́gbin mọ́, àwọn àti ọba wọn,+ nípa àgbèrè wọn àti nípa òkú+ àwọn ọba wọn nígbà ikú wọn,  nípa fífi ibi àbáwọlé tiwọn sí ibi àbáwọlé mi àti nípa fífi òpó ilẹ̀kùn wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri láàárín èmi àti àwọn.+ Wọ́n sì sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin nípa àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn tí wọ́n ṣe,+ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n run pátápátá nínú ìbínú mi.+  Kí wọ́n mú àgbèrè wọn+ àti òkú àwọn ọba wọn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi+ nísinsìnyí, dájúdájú, èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 10  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì nípa Ilé náà,+ kí wọ́n lè gba ìtẹ́lógo nítorí àwọn ìṣìnà wọn,+ kí wọ́n sì díwọ̀n àwòṣe náà. 11  Bí wọ́n bá sì gba ìtẹ́lógo ní tòótọ́ nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, àwòrán ìpìlẹ̀ Ilé náà,+ àti ìṣètò rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà àbájáde rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀, àti gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe rẹ̀, àti gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo òfin rẹ̀ ni kí o sọ di mímọ̀ fún wọn, kí o sì kọ ọ́ sílẹ̀ ní ìṣojú wọn, kí wọ́n bàa lè máa kíyè sí gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe rẹ̀, kí wọ́n lè máa mú wọn ṣe ní ti tòótọ́.+ 12  Èyí ni òfin Ilé náà. Lórí òkè ńlá, gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ̀ pátá ní gbogbo àyíká jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ.+ Wò ó! Èyí ni òfin Ilé náà. 13  “Ìwọ̀nyí sì ni ìwọ̀n pẹpẹ náà ní ìgbọ̀nwọ́-ìgbọ̀nwọ́,+ ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìbú ọwọ́ kan.+ Ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Ìgbọ̀nwọ́ kan sì ni fífẹ̀ rẹ̀. Ìgbátí rẹ̀ sì wà ní etí rẹ̀ yí ká, ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Èyí sì ni ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. 14  Láti ìsàlẹ̀ lórí ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ dé orí bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó lọ yí ká nísàlẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ méjì ni ó jẹ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Àti láti ibi bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ kékeré tí ó lọ yí ká dé ibi bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ ńlá tí ó lọ yí ká, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní o jẹ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. 15  Ibi ìdáná pẹpẹ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, láti ibi ìdáná pẹpẹ sókè ni ìwo mẹ́rin+ wà. 16  Ibi ìdáná pẹpẹ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní gígùn, pẹ̀lú ìgbọ̀nwọ́ méjìlá ní fífẹ̀,+ ó dọ́gba ní ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.+ 17  Bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó lọ yí ká sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, pẹ̀lú ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, ní ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; ìgbátí tí ó wà yí i ká sì jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yí ká. “Àtẹ̀gùn rẹ̀ dojú kọ ìlà-oòrùn.” 18  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ti pẹpẹ ní ọjọ́ tí a mọ ọ́n, láti lè máa rú odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ lórí rẹ̀ àti láti máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí rẹ̀.’+ 19  “‘Kí o sì fún àwọn àlùfáà ọmọ Léfì,+ àwọn tí ó wá láti inú àwọn ọmọ Sádókù,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘àwọn tí ń tọ̀ mí wá+ láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ní ẹgbọrọ akọ màlúù kan, ọmọ ọ̀wọ́ ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 20  Kí o sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi í sára ìwo rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti sára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó lọ yí ká àti sára ìgbàtí tí ó yí i ká, kí o sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,+ kí o sì ṣe ètùtù fún un.+ 21  Kí o sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí ẹnì kan sì fi iná sun ún ní ibi tí a yàn kalẹ̀ nínú Ilé náà, lóde ibùjọsìn.+ 22  Ní ọjọ́ kejì, kí o sì mú akọ ewúrẹ́ kan sún mọ́ tòsí, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; kí wọ́n sì wẹ pẹpẹ náà mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe fi ẹgbọrọ akọ màlúù náà wẹ̀ ẹ́ mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.’ 23  “‘Nígbà tí o bá parí ṣíṣe ìwẹ̀mọ́gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ yóò mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan sún mọ́ tòsí, ọmọ ọ̀wọ́ ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, àti àgbò kan láti inú agbo ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá. 24  Kí o sì mú wọn wá síwájú Jèhófà, kí àwọn àlùfáà da iyọ̀ sí wọn lára, kí wọ́n sì fi wọ́n rúbọ+ gẹ́gẹ́ bí odindi ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà. 25  Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi òbúkọ kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lóòjọ́;+ ẹgbọrọ akọ màlúù kan, ọmọ ọ̀wọ́ ẹran, àti àgbò kan láti inú agbo ẹran, èyí tí ara wọn pé, ni wọn yóò fi rúbọ. 26  Ọjọ́ méje ni wọn yóò fi ṣe ètùtù+ fún pẹpẹ náà, wọn yóò sì wẹ̀ ẹ́ mọ́, wọn yóò sì ṣètò rẹ̀ kalẹ̀. 27  Wọn yóò sì lo àwọn ọjọ́ náà pé. Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ+ àti láti ìgbà náà lọ pé àwọn àlùfáà yóò máa rú àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ yín lórí pẹpẹ; dájúdájú, èmi yóò sì ní inú dídùn sí yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé