Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 42:1-20

42  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi+ gba àríwá+ wá sí àgbàlá òde. Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi wá sínú ilé yàrá ìjẹun+ tí ó wà ní iwájú àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀,+ tí ó sì wà ní iwájú ilé níhà àríwá.  Ṣáájú ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ náà ni ẹnu ọ̀nà àríwá wà, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.  Ní iwájú ogún ìgbọ̀nwọ́ tí ó jẹ́ ti àgbàlá inú lọ́hùn-ún+ àti ní iwájú ibi títẹ́+ tí ó jẹ́ ti àgbàlá òde ni ọ̀dẹ̀dẹ̀+ tí ó dojú kọ ọ̀dẹ̀dẹ̀ wà, ní àjà mẹ́ta.  Àti níwájú àwọn yàrá ìjẹun, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ wà tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ síhà inú,+ ọ̀nà tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, àwọn ẹnu ọ̀nà wọn sì wà níhà àríwá.  Ní ti àwọn yàrá ìjẹun, àwọn tí ó wà ní òkè pátápátá kúrú, nítorí àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ gbà lára wọn, ju ti àwọn tí ó wà nísàlẹ̀ pátápátá, àti ju ti àwọn àárín lọ, ní ti ilé náà.  Nítorí wọ́n jẹ́ àjà mẹ́ta,+ wọn kò sì ní ọwọ̀n bí àwọn ọwọ̀n ti àgbàlá òde. Ìdí nìyẹn tí a fi mú àyè púpọ̀ lára wọn ju ti àwọn tí ó wà nísàlẹ̀ pátápátá àti lára àwọn ti àárín láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀.  Ògiri òkúta tí ó wà lóde sì ń bẹ nítòsí àwọn yàrá ìjẹun níhà àgbàlá òde níwájú àwọn yàrá ìjẹun yòókù. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.  Nítorí gígùn àwọn yàrá ìjẹun tí ó wà níhà àgbàlá òde jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, sì wò ó! níwájú tẹ́ńpìlì, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.  Àti láti ìsàlẹ̀ yàrá ìjẹun wọ̀nyí, ọ̀nà àbáwọlé wà síhà ìlà-oòrùn, nígbà tí ènìyàn bá gba ti àgbàlá òde wọnú wọn. 10  Nínú ibi fífẹ̀ ògiri òkúta ti àgbàlá òde níhà ìlà-oòrùn, níwájú àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀+ àti níwájú ilé náà, àwọn yàrá ìjẹun+ wà. 11  Ọ̀nà kan sì wà níwájú wọn tí ó ní ìrísí ti àwọn yàrá ìjẹun tí ó wà níhà àríwá,+ bẹ́ẹ̀ ni gígùn wọn rí, bẹ́ẹ̀ sì ni fífẹ̀ wọn rí; gbogbo ọ̀nà àbájáde wọn sì rí bákan náà, àwòrán ilé kíkọ́ wọn sì rí bákan náà, ẹnu ọ̀nà wọn sì rí bákan náà. 12  Àti bí ẹnu ọ̀nà àwọn yàrá ìjẹun tí ó wà níhà gúúsù ni ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìkòríta ọ̀nà náà rí, ọ̀nà tí ó wà níwájú irú ògiri òkúta kan náà tí ó wà níhà ìlà-oòrùn, nígbà tí ènìỳan bá wọlé sínú wọn.+ 13  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún mi pé: “Àwọn yàrá ìjẹun àríwá àti àwọn yàrá ìjẹun gúúsù tí ó wà níwájú àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀,+ àwọn ni yàrá ìjẹun mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà tí ń tọ Jèhófà wá+ ti ń jẹ àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun mímọ́ jù lọ sí àti ọrẹ ẹbọ ọkà àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́.+ 14  Nígbà tí àwọn, ìyẹn àwọn àlùfáà, bá ti wọlé, wọn kì yóò jáde láti ibi mímọ́ lọ sí àgbàlá òde, ṣùgbọ́n ibẹ̀ ni wọn yóò kó ẹ̀wù wọn kalẹ̀ sí, èyí tí wọ́n sábà máa ń wọ̀ fi ṣiṣẹ́,+ nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́. Wọn yóò wọ ẹ̀wù mìíràn,+ wọn yóò sì sún mọ́ ohun tí ó nííṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn náà.” 15  Ó sì parí wíwọn ilé inú lọ́hùn-ún, ó sì mú mi jáde gba ti ẹnubodè tí iwájú rẹ̀ dojú kọ ìlà-oòrùn,+ ó sì wọ̀n ọ́n yí ká. 16  Ó fi ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan wọn ìhà ìlà-oòrùn. Ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú, yí ká, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan,+ 17  Ó wọn ìhà àríwá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú, yí ká, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan. 18  Ó wọn ìhà gúúsù, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú, ní ìbámú pẹ̀lú ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan. 19  Ó lọ yí ká sí ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ó wọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan. 20  Ó wọ̀n ọ́n ní ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri yí ká,+ tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀pá esùsú,+ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó jẹ́ mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ aláìmọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé