Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 40:1-49

40  Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbèkùn wa,+ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún náà, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ní ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn tí a ti ṣá ìlú ńlá náà balẹ̀,+ ní ọjọ́ yìí gan-an ni ọwọ́ Jèhófà wà lára mi,+ tí ó fi jẹ́ pé ó mú mi wá sí ibẹ̀.+  Nínú àwọn ìran ti Ọlọ́run, ó mú mi wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbé mi kalẹ̀ sórí òkè ńlá kan tí ó ga gan-an,+ lórí èyí tí ohun kan wà tí ó ní ìrísí ìlú ńlá níhà gúúsù.+  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi wá sí ibẹ̀, sì wò ó! ọkùnrin kan wà níbẹ̀. Ìrísí rẹ̀ dà bí ìrísí bàbà,+ okùn ọ̀gbọ̀ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀, àti ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan,+ ó sì dúró ní ẹnubodè.  Ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn,+ fi ojú rẹ wò, kí o sì fi etí rẹ gbọ́, kí o sì fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ohun tí èmi yóò fi hàn ọ́, nítorí kí n lè fi hàn ọ́ ni a ṣe mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ìwọ yóò rí fún ilé Ísírẹ́lì.”+  Sì wò ó! ògiri kan wà lóde ilé náà yíká. Ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì ni ọ̀pá esùsú tí a fi ń wọn nǹkan wà, èyí tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, nípa ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìbú ọwọ́ kan. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ìbú ohun tí a kọ́, ọ̀pá esùsú kan; àti gíga rẹ̀, ọ̀pá esùsú kan.  Lẹ́yìn náà, ó wá sí ẹnubodè, tí iwájú rẹ̀ dojú kọ ìlà-oòrùn,+ ó sì bá àtẹ̀gùn rẹ̀ gòkè. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ibi àbáwọ ẹnubodè,+ ọ̀pá esùsú kan ní fífẹ̀, àti ibi àbáwọlé kejì, ọ̀pá esùsú kan ní fífẹ̀.  Ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan ní gígùn àti ọ̀pá esùsú kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni ó sì wà láàárín àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́;+ ibi àbáwọ ẹnubodè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gọ̀bì ẹnubodè níhà inú lọ́hùn-ún sì jẹ́ ọ̀pá esùsú kan.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn gọ̀bì ẹnubodè níhà inú lọ́hùn-ún, ọ̀pá esùsú kan.+  Bẹ́ẹ̀ ni ó wọn gọ̀bì ẹnubodè, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ; àti àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́, ìgbọ̀nwọ́ méjì; gọ̀bì ẹnubodè sì wà níhà inú lọ́hùn-ún. 10  Àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ ẹnubodè níhà ìlà-oòrùn sì jẹ́ mẹ́ta ní ìhà ìhín àti mẹ́ta ní ìhà ọ̀hún. Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ́ ìwọ̀n kan náà, àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ sì jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. 11  Lẹ́yìn náà, ó wọn fífẹ̀ ibi àtiwọ ẹnubodè náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá; gígùn ẹnubodè náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá. 12  Ibi àsọgbàyíká ní iwájú àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, ibi àsọgbàyíká tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan sì wà ní ìhà kọ̀ọ̀kan. Ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìhà ìhín àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìhà ọ̀hún. 13  Ó sì ń bá a lọ láti wọn ẹnubodè láti òrùlé ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ kan dé òrùlé ti èkejì, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀;+ ẹnu ọ̀nà wà ní òdì-kejì ẹnu ọ̀nà. 14  Lẹ́yìn náà, ó ṣe ti àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ tí ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní dé àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ inú àgbàlá ní àwọn ẹnubodè yí ká. 15  Iwájú ẹnubodè ti ọ̀nà àbáwọlé títí dé iwájú gọ̀bì ti ẹnubodè inú lọ́hùn-ún sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 16  Àwọn fèrèsé oníférémù tóóró+ sì wà fún àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ àti fún àwọn ọwọ̀n wọn ẹ̀gbẹ́ níhà inú ẹnubodè yí ká, bí àwọn gọ̀bì náà ti rí nìyẹn. Gbogbo fèrèsé náà sì wà yí ká níhà inú, àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ sì wà lára àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́. 17  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi wá sínú àgbàlá òde, sì wò ó! àwọn yàrá ìjẹun+ ń bẹ, àti ibi títẹ́ tí a ṣe fún àgbàlá náà yí ká. Ọgbọ̀n yàrá ìjẹun ni ó wà lórí ibi títẹ́ náà.+ 18  Ibi títẹ́ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè sì jẹ́ bákan náà gan-an bí gígùn àwọn ẹnubodè—ibi títẹ́ ìsàlẹ̀. 19  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn fífẹ̀ rẹ̀ láti iwájú ẹnubodè ìsàlẹ̀ dé iwájú àgbàlá inú lọ́hùn-ún. Ní òde, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, síhà ìlà-oòrùn àti síhà àríwá. 20  Àgbàlá òde sì ní ẹnubodè tí iwájú rẹ̀ dojú kọ àríwá. Ó wọn gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀. 21  Àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́ta ní ìhà ìhín àti mẹ́ta ní ìhà ọ̀hún. Àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ àti gọ̀bì rẹ̀ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ẹnubodè àkọ́kọ́. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. 22  Àwọn fèrèsé rẹ̀ àti gọ̀bì rẹ̀ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ rẹ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà bí ti àwọn ti ẹnubodè tí iwájú rẹ̀ dojú kọ ìlà-oòrùn. Àtẹ̀gùn méje sì ni àwọn ènìyàn lè bá gòkè lọ sínú rẹ̀, gọ̀bì rẹ̀ wà ní iwájú wọn. 23  Ẹnubodè àgbàlá inú lọ́hùn-ún sì dojú kọ ẹnubodè ìhà àríwá; bákan náà, ọ̀kan níhà ìlà-oòrùn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀n ọ́n láti ẹnubodè sí ẹnubodè, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 24  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi wá síhà gúúsù, sì wò ó! ẹnubodè kan wà níhà gúúsù,+ ó sì wọn àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ àti gọ̀bì rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí. 25  Òun àti gọ̀bì rẹ̀ sì ní àwọn fèrèsé yí ká, bí fèrèsé wọ̀nyí. Àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. 26  Àtẹ̀gùn méje sì ni ó wà fún gígun òkè rẹ̀,+ gọ̀bì rẹ̀ sì wà ní iwájú wọn. Ó sì ní àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ, ọ̀kan ní ìhà ìhín àti ọ̀kan ní ìhà ọ̀hún lára àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́. 27  Àgbàlá inú lọ́hùn-ún sì ní ẹnubodè kan níhà gúúsù. Ó sì wọ̀n ọ́n láti ẹnubodè sí ẹnubodè níhà gúúsù, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 28  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi gba ẹnubodè gúúsù wá sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ẹnubodè gúúsù ní ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí. 29  Àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àti àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ àti gọ̀bì rẹ̀ sì jẹ́ ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí. Òun àti gọ̀bì rẹ̀ sì ní àwọn fèrèsé yí ká. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.+ 30  Àwọn gọ̀bì sì wà yí ká; gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. 31  Gọ̀bì rẹ̀ sì wà níhà àgbàlá òde, àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ sì wà lára àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́,+ ìgòkè rẹ̀ sì jẹ́ àtẹ̀gùn mẹ́jọ.+ 32  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó mú mi gba ti ìlà-oòrùn wá sínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ẹnubodè náà ní ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí. 33  Àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àti àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ àti gọ̀bì rẹ̀ sì jẹ́ ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí, òun àti gọ̀bì rẹ̀ sì ní àwọn fèrèsé yí ká. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. 34  Gọ̀bì rẹ̀ sì wà níhà àgbàlá òde, àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ sì wà lára àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ìgòkè rẹ̀ sì jẹ́ àtẹ̀gùn mẹ́jọ. 35  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi wá sínú ẹnubodè àríwá,+ ó sì wọ̀n ọ́n, pẹ̀lú ìwọ̀n kan náà bí ìwọ̀nyí,+ 36  àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ àti gọ̀bì rẹ̀. Ó sì ní àwọn fèrèsé yí ká. Gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. 37  Àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ sì wà níhà àgbàlá òde, àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ sì wà lára àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ẹ̀gbẹ́ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún.+ Ìgòkè rẹ̀ sì jẹ́ àtẹ̀gùn mẹ́jọ. 38  Yàrá ìjẹun kan àti ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì wà ní ìhà àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ ti àwọn ẹnubodè náà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣan odindi ọrẹ ẹbọ sísun.+ 39  Nínú gọ̀bì ẹnubodè ni tábìlì méjì wà ní ìhà ìhín àti tábìlì méjì ní ìhà ọ̀hún, fún pípa odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ lórí wọn. 40  Ní ìhà òde, bí ènìyàn bá ti ń gòkè lọ sí ibi àtiwọ ẹnubodè àríwá, tábìlì méjì ń bẹ. Àti ní ìhà tọ̀hún tí ó jẹ́ ti gọ̀bì ẹnubodè, tábìlì méjì ń bẹ. 41  Tábìlì mẹ́rin ń bẹ níhìn-ín, tábìlì mẹ́rin sì ń bẹ lọ́hùn-ún lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè—tábìlì mẹ́jọ, lórí èyí tí wọ́n ti máa ń pẹran. 42  Tábìlì mẹ́rin náà fún odindi ọrẹ ẹbọ sísun ni a fi òkúta gbígbẹ́ ṣe. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Orí wọn ni wọ́n máa ń kó ohun èlò ìṣiṣẹ́ sí, èyí tí wọ́n fi máa ń pa odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ. 43  Àwọn bèbè tẹ́ẹ́rẹ́ fún gbígbé àwọn nǹkan lé sì jẹ́ ìbú ọwọ́ kan, tí a mú mọ́lẹ̀ gbọin-in mọ́ ìhà inú wọn yíká-yíká; orí àwọn tábìlì náà ni wọ́n máa ń gbé ẹran ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn sí.+ 44  Àti ní òde ẹnubodè inú lọ́hùn-ún ni àwọn yàrá ìjẹun àwọn akọrin+ wà, nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, tí ó wà ní ìhà ẹnubodè àríwá. Apá iwájú wọn sì dojú kọ gúúsù. Ọ̀kan wà ní ìhà ẹnubodè ìlà-oòrùn. Iwájú rẹ̀ dojú kọ àríwá. 45  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún mi pé: “Eléyìí, yàrá ìjẹun tí iwájú rẹ̀ dojú kọ gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ilé náà.+ 46  Yàrá ìjẹun tí iwájú rẹ̀ dojú kọ́ àríwá sì wà fún àwọn àlùfáà tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti pẹpẹ.+ Àwọn ọmọ Sádókù+ ni wọ́n, àwọn tí ó jẹ́ pé, nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn ni ó ń tọ Jèhófà wá láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.”+ 47  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn àgbàlá inú lọ́hùn-ún. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba. Pẹpẹ náà sì wà ní iwájú ilé. 48  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi wá sínú gọ̀bì ilé náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ gọ̀bì náà, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìhà ìhín àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìhà ọ̀hún. Fífẹ̀ ẹnubodè náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ìhà ìhín àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ìhà ọ̀hún. 49  Gígùn gọ̀bì náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mọ́kànlá. Àtẹ̀gùn ni wọ́n sì máa ń bá gòkè lọ sínú rẹ̀. Àwọn ọwọ̀n sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ arópòódògiri ẹ̀gbẹ́, ọ̀kan níhìn-ín àti ọ̀kan lọ́hùn-ún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé