Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 4:1-17

4  “Ìwọ, ọmọ ènìyàn, sì gbé bíríkì fún ara rẹ, kí ó sì gbé e síwájú rẹ, kí o sì fín ìlú ńlá kan sórí rẹ̀, àní Jerúsálẹ́mù.+  Kí o sì sàga tì í,+ kí o sì mọ odi ìsàgatì tì í,+ kí o sì yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì tì í,+ kí o sì gbé ìdótì tì í, kí o sì fi òlùgbóró yí i ká.+  Àti ní ti ìwọ, gbé agbada onírin sọ́dọ̀ ara rẹ, kí o sì gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ògiri irin láàárín ìwọ àti ìlú ńlá náà, kí o sì dojú rẹ kọ ọ́, kí ó sì wà nínú ìsàgatì, kí o sì sàga tì í. Àmì ni ó jẹ́ fún ilé Ísírẹ́lì.+  “Àti ní ti ìwọ, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ìṣìnà ilé Ísírẹ́lì kà á lórí.+ Iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀ lórí rẹ̀ ni ìwọ yóò fi ru ìṣìnà wọn.  Èmi alára yóò sì fún ọ ní àwọn ọdún ìṣìnà wọn,+ tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹ̀wá-dín-nírínwó ọjọ́,+ ìwọ yóò sì ru ìṣìnà ilé Ísírẹ́lì.  Kí o sì parí wọn. “Kí o sì fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún dùbúlẹ̀ ní ti ọ̀ràn kejì, kí o sì ru ìṣìnà ilé Júdà fún ogójì ọjọ́.+ Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ni ohun tí mo fi fún ọ.+  Ìwọ yóò sì dojú kọ ìsàgatì Jerúsálẹ́mù,+ pẹ̀lú apá rẹ tí a kò bò, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí i.  “Sì wò ó! èmi yóò fi okùn+ sí ọ lára kí o má bàa lè yí ara rẹ padà láti ẹ̀gbẹ́ rẹ kan sí ẹ̀gbẹ́ rẹ kejì, títí ìwọ yóò fi parí àwọn ọjọ́ ìsàgatì rẹ.  “Ní ti ìwọ, mú àlìkámà+ àti ọkà bálì àti ẹ̀wà pàkálà+ àti ẹ̀wà lẹ́ńtìlì+ àti jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ fún ara rẹ, kí o sì kó wọ́n sínú nǹkan èlò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe oúnjẹ rẹ, fún iye ọjọ́ tí o fi fi ẹ̀gbẹ́ rẹ dùbúlẹ̀; ẹ̀wá-dín-nírínwó ọjọ́ ni ìwọ yóò fi jẹ ẹ́.+ 10  Oúnjẹ tí ìwọ yóò jẹ yóò sì jẹ́ nípasẹ̀ ìwọ̀n—ogún ṣékélì fún ọjọ́ kan.+ Láti ìgbà dé ìgbà ni ìwọ yóò máa jẹ ẹ́. 11  “Ìwọ yóò sì mu omi kìkì nípa òṣùwọ̀n, ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n hínì. Láti ìgbà dé ìgbà ni ìwọ yóò máa mu ún. 12  “Bí àkàrà ọkà bálì ribiti+ ni ìwọ yóò jẹ ẹ́; àti ní ti ìyẹn, lórí imí gbígbẹ tí ó jẹ́ ìgbọ̀nsẹ̀+ aráyé ni ìwọ yóò ti yan án lójú wọn.” 13  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí pé: “Báyìí gan-an ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́+ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò fọ́n wọn ká sí.”+ 14  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Ọkàn mi kì í ṣe ẹlẹ́gbin;+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ òkú ẹran tàbí ẹran tí a fà ya láti ìgbà èwe mi wá,+ àní títí di ìsinsìnyí, ẹran tí a sọ di àìmọ́ kò sì wọ ẹnu mi rí.”+ 15  Nítorí náà, ó wí fún mi pé: “Wò ó, mo ti fi ẹlẹ́bọ́tọ màlúù dípò imí gbígbẹ ti aráyé fún ọ, kí o sì ṣe búrẹ́dì rẹ lórí rẹ̀.” 16  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, kíyè sí i, èmi yóò ṣẹ́ àwọn ọ̀pá tí a fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí,+ ní Jerúsálẹ́mù, wọn yóò sì ní láti jẹ oúnjẹ nípa ìwọ̀n àti nínú àníyàn ṣíṣe,+ nípa òṣùwọ̀n àti nínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni wọn yóò mu omi pàápàá,+ 17  fún ète pé wọn yóò ṣaláìní oúnjẹ àti omi, wọn yóò sì máa wo ara wọn tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu, wọn yóò sì jẹrà dànù nínú ìṣìnà wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé