Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 37:1-28

37  Ọwọ́ Jèhófà wà lára mi,+ ó sì mú mi jáde nínú ẹ̀mí Jèhófà,+ ó sì gbé mi kalẹ̀ ní àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, ó sì kún fún egungun.+  Ó sì mú mi kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ní gbogbo àyíká, sì wò ó! púpọ̀ gan-an ni ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì náà, sì wò ó! wọ́n gbẹ gidigidi.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ha lè wá sí ìyè bí?” Mo fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ alára mọ̀ dáadáa.”+  Ó sì ń ba a lọ láti wí fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ sórí egungun wọ̀nyí, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà:  “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún egungun wọ̀nyí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú èémí wá sínú yín, ẹ ó sì wá sí ìyè.+  Ṣe ni èmi yóò fi àwọn fọ́nrán iṣan sára yín, èmi yóò sì mú kí ẹran ara wá sára yín, ṣe ni èmi yóò fi awọ bò yín, èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ ó sì wá sí ìyè;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+  Mo sì sọ tẹ́lẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi.+ Ìró kan sì bẹ̀rẹ̀ sí dún ní gbàrà tí mo sọ tẹ́lẹ̀, dídún kan sì wà, àwọn egungun sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ra, egungun mọ́ egungun.  Mo sì rí i, sì wò ó! àwọn fọ́nrán iṣan àti ẹran ara wá sára wọn, awọ sì bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n lórí. Ṣùgbọ́n ní ti èémí, kò sí ìkankan nínú wọn.  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ sí ẹ̀fúùfù. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí o sì wí fún ẹ̀fúùfù pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ìwọ ẹ̀fúùfù, wá láti ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí o sì fẹ́ sára àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a pa,+ kí wọ́n lè wá sí ìyè.”’”+ 10  Mo sì sọ tẹ́lẹ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún mi, èémí sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sínú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wà láàyè, wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn,+ ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà. 11  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ní ti egungun wọ̀nyí, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ni wọ́n.+ Kíyè sí i, wọ́n ń wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ, ìrètí wa sì ti ṣègbé.+ Ní ti wa, a ti yà wá nípa pátápátá.’ 12  Nítorí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò ṣí àwọn ibi ìsìnkú yín,+ ṣe ni èmi yóò mú yín gòkè kúrò ní àwọn ibi ìsìnkú yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò sì mú yín wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 13  Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá ṣí àwọn ibi ìsìnkú yín, àti nígbà tí mo bá mú yín gòkè kúrò ní àwọn ibi ìsìnkú yín, ẹ̀yin ènìyàn mi.”’+ 14  ‘Ṣe ni èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, ẹ ó sì wá sí ìyè,+ èmi yóò tẹ̀ yín dó sórí ilẹ̀ yín; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́, mo sì ti ṣe é,’ ni àsọjáde Jèhófà.”+ 15  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 16  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú ọ̀pá+ kan fún ara rẹ, kí o sì kọ̀wé sára rẹ̀ pé, ‘Fún Júdà àti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alájọṣe rẹ̀.’+ Kí o sì mú ọ̀pá mìíràn, kí o sì kọ̀wé sára rẹ̀ pé, ‘Fún Jósẹ́fù, ọ̀pá Éfúráímù,+ àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì alájọṣe rẹ̀.’+ 17  Kí o sì sún èkíní-kejì wọn mọ́ra di ọ̀pá kan ṣoṣo fún ara rẹ, wọn yóò sì di ọ̀kan ṣoṣo ní ọwọ́ rẹ ní tòótọ́.+ 18  Nígbà tí àwọn ọmọ ènìyàn rẹ bá sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ọ pé, ‘Ìwọ kì yóò ha sọ fún wa ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí fún ọ?’+ 19  sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ọ̀pá Jósẹ́fù, èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù, àti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì alájọṣe rẹ̀, dájúdájú, èmi yóò sì fi wọ́n sára rẹ̀, èyíinì ni, ọ̀pá Júdà, èmi yóò sì sọ wọ́n di ọ̀pá kan ṣoṣo+ ní tòótọ́, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”’ 20  Àwọn ọ̀pá tí o kọ̀wé sí lára yóò sì wà ní ọwọ́ rẹ níwájú wọn.+ 21  “Sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, dájúdájú, èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀ láti gbogbo àyíká, èmi yóò sì mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn.+ 22  Ní tòótọ́, èmi yóò sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà,+ lórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì, ọba kan ṣoṣo ni gbogbo wọn yóò wá ní gẹ́gẹ́ bí ọba,+ wọn kì yóò máa bá a lọ láti jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pín sí ìjọba méjì mọ́.+ 23  Wọn kì yóò sì fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn àti àwọn ohun ìríra wọn àti gbogbo ìrélànàkọjá+ wọn sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́; èmi yóò sì gbà wọ́n là kúrò nínú gbogbo ibi gbígbé wọn nínú èyí tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, èmi yóò wẹ̀ wọ́n mọ́,+ wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run wọn.+ 24  “‘“Dáfídì ìránṣẹ́ mi yóò sì jẹ ọba lórí wọn,+ olùṣọ́ àgùntàn kan ṣoṣo ni gbogbo wọn yóò wá ní;+ wọn yóò sì máa rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi,+ wọn yóo sì pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́,+ wọn yóò sì máa mú wọn ṣe ní ti tòótọ́.+ 25  Wọn yóò sì máa gbé ní tòótọ́ lórí ilẹ̀ tí mo fi fún iránṣẹ́ mi, fún Jékọ́bù, èyí tí àwọn baba ńlá yín gbé,+ wọn yóò sì máa gbé lórí rẹ̀ ní tòótọ́,+ àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ-ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò sì jẹ́ ìjòyè wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 26  “‘“Dájúdájú, èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà;+ májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ohun tí yóò wà pẹ̀lú wọn.+ Ṣe ni èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,+ èmi yóò sì fi ibùjọsìn mi sí àárín wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 27  Àgọ́ mi yóò sì wà lórí wọn+ ní ti tòótọ́, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn dájúdájú, àwọn pàápàá yóò sì di ènìyàn mi.+ 28  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi, Jèhófà,+ ní ń sọ Ísírẹ́lì di mímọ́ nígbà tí ibùjọsìn mi yóò wà ní àárín wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé