Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 36:1-38

36  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì, kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè ńlá Ísírẹ́lì,+ ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Nítorí ìdí náà pé ọ̀tá ti sọ̀rọ̀ lòdì sí yín+ pé, ‘Àháà! Àní àwọn ibi gíga ìgbà láéláé+—ó ti di tiwa gẹ́gẹ́ bí ohun ìní!’”’+  “Nítorí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Nítorí ìdí náà, àní nítorí ìdí náà pé wíwà ní ahoro+ àti ìkùgìrì mọ́ yín láti ìhà gbogbo ti ṣẹlẹ̀,+ kí ẹ bàa lè di ohun ìní fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,+ ọ̀rọ̀ yín sì wà lórí ahọ́n wọn,+ ìròyìn búburú sì wà láàárín àwọn ènìyàn,+  nítorí náà, ẹ̀yin òkè ńlá Ísírẹ́lì,+ ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún àwọn òkè ńlá àti fún àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn ojú ìṣàn omi àti fún àwọn àfonífojì àti fún àwọn ibi ìparundahoro tí a sọ di ahoro+ àti fún àwọn ìlú ńlá tí a pa tì, tí wọ́n jẹ́ ohun ìpiyẹ́ àti ìyọṣùtì sí fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà yí ká;+  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Dájúdájú, nínú iná ìtara mi ni èmi yóò sọ̀rọ̀+ lòdì sí àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti lòdì sí Édómù, gbogbo rẹ̀ pátá,+ àwọn tí wọ́n fi ilẹ̀ mi fún ara wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ gbogbo ọkàn-àyà,+ pẹ̀lú ìpẹ̀gàn nínú ọkàn,+ nítorí ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀ àti fún ìpiyẹ́.’”’+  “Nítorí náà, sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún àwọn òkè ńlá àti fún àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn ojú ìṣàn omi àti fún àwọn àfonífojì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Wò ó! Èmi alára nínú ìtara mi àti nínú ìhónú mi yóò sọ̀rọ̀, nítorí ìdí náà pé ìwọ ru ìtẹ́lógo láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.”’+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Èmi alára ti gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra+ pé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká—àwọn fúnra wọn yóò ru ìtẹ́lógo ara wọn.+  Ẹ̀yin fúnra yín, ẹ̀yin òkè ńlá Ísírẹ́lì, yóò yọ àwọn ẹ̀tun tí ó jẹ́ tiyín jáde, ẹ ó sì so èso tiyín fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì,+ nítorí wọ́n ti sún mọ́ àtiwọlé.+  Nítorí, kíyè sí i, èmi fara mọ́ yín, èmi yóò sì yíjú sí yín+ dájúdájú, a ó sì ro yín, a ó sì fún irúgbìn sínú yín.+ 10  Ṣe ni èmi yóò sọ ìran ènìyàn di púpọ̀ lórí yín, gbogbo ilé Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀ pátá,+ àwọn ìlú ńlá náà yóò sì di gbígbé,+ àwọn ibi ìparundahoro pàápàá ni a ó sì tún kọ́.+ 11  Bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ni èmi yóò sọ ìran ènìyàn àti ìran ẹranko+ di púpọ̀ lórí yín, wọn yóò sì di púpọ̀ ní ti tòótọ́, wọn yóò sì máa so èso, èmi yóò sì mú kí a máa gbé inú yín ní tòótọ́ bí ti ipò yín àtijọ́,+ ṣe ni èmi yóò ṣe rere ju ti ipò yín ìbẹ̀rẹ̀;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 12  Ṣe ni èmi yóò mú kí ìran ènìyàn máa rìn lórí yín, àní àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, wọn yóò gbà yín,+ ẹ ó sì di ohun ìní àjogúnbá fún wọn,+ ẹ kì yóò tún mú kí wọ́n ṣòfò+ ọmọ mọ́.’” 13  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé àwọn kan wà tí ń sọ fún yín pé: “Olùjẹ ìran ènìyàn run ni ìwọ alára jẹ́, ilẹ̀ tí ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣòfò ọmọ ni ìwọ jẹ́,”’+ 14  ‘nítorí náà, ìran ènìyàn ni ìwọ kì yóò jẹ run mọ́,+ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ ni ìwọ kì yóò sì mú kí ó ṣòfò ọmọ mọ́,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 15  ‘Èmi kò sì ní mú kí a gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ń tẹ́ni lógo mọ́ nípa rẹ láti ẹnu àwọn orílẹ̀-èdè,+ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ni ìwọ kì yóò sì rù mọ́,+ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ ni ìwọ kì yóò sì mú kí ó kọsẹ̀ mọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 16  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 17  “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ń gbé lórí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì ń fi ọ̀nà wọn àti ìbálò wọn sọ ọ́ di aláìmọ́.+ Bí ohun àìmọ́ nǹkan oṣù ni ọ̀nà wọn dà lójú mi.+ 18  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí da ìhónú mi sórí wọn ní tìtorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ti dà sórí ilẹ̀ náà,+ ilẹ̀ tí wọ́n ti fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn sọ di àìmọ́.+ 19  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n fi fọ́n ká sáàárín àwọn ilẹ̀.+ Mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà wọn àti gẹ́gẹ́ bí ìbálò wọn.+ 20  Nítorí náà, wọ́n lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ orúkọ mímọ́+ mi di aláìmọ́ ní sísọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Jèhófà, ilẹ̀ rẹ̀ sì ni wọ́n ti jáde lọ.’+ 21  Èmi yóò sì ní ìyọ́nú sí orúkọ mímọ́ mi, èyí tí ilé Ísírẹ́lì ti sọ di aláìmọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ.”+ 22  “Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kì í ṣe nítorí yín ni mo fi ń ṣe é, ilé Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí tí ẹ ti sọ di aláìmọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ lọ.”’+ 23  ‘Dájúdájú, èmi yóò sì sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́,+ èyí tí a ń sọ di aláìmọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tí ẹ sọ di aláìmọ́ láàárín wọn; àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘nígbà tí a bá sọ mí di mímọ́ láàárín yín lójú wọn.+ 24  Ṣe ni èmi yóò kó yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì kó yín jọpọ̀ láti ilẹ̀ gbogbo, èmi yóò sì mú yín wá sórí ilẹ̀ yín.+ 25  Ṣe ni èmi yóò wọ́n omi tí ó mọ́ sórí yín, ẹ ó sì di ẹni tí ó mọ́;+ èmi yóò sì wẹ̀ yín mọ́+ kúrò nínú gbogbo ohun ìdọ̀tí yín+ àti gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín. 26  Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní ọkàn-àyà tuntun,+ èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín,+ ṣe ni èmi yóò mú ọkàn-àyà òkúta kúrò nínú ẹran ara yín, èmi yóò sì fún yín ní ọkàn-àyà ẹlẹ́ran ara.+ 27  Èmi yóò sì fi ẹ̀mí mi sínú yín,+ dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀ kí ẹ bàa lè máa rín nínú àwọn ìlànà mi,+ ẹ ó sì pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, ẹ ó sì máa mú wọn ṣe ní ti tòótọ́.+ 28  Dájúdájú, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín,+ ẹ ó sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run yín.’+ 29  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín là kúrò nínú gbogbo ohun ìdọ̀tí yín,+ èmi yóò sì pe ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ gidigidi, èmi kì yóò sì mú ìyàn dé bá yín.+ 30  Ṣe ni èmi yóò mú kí èso igi pọ̀ gidigidi, àti àmújáde pápá, kí ẹ má bàa gba ẹ̀gàn ìyàn mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 31  Ó dájú pé ẹ óò rántí àwọn ọ̀nà búburú yín àti ìbálò yín tí kò dára,+ ó sì dájú pé ẹ óò kórìíra ara tiyín tẹ̀gbintẹ̀gbin ní tìtorí àwọn ìṣìnà yín àti ní tìtorí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yín.+ 32  Kì í ṣe nítorí yín ni mo fi ń ṣe èyí,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘kí ó di mímọ̀ fún yín. Kí ojú tì yín, kí a sì tẹ́ yín lógo nítorí àwọn ọ̀nà yín, ilé Ísírẹ́lì.’+ 33  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní ọjọ́ tí èmi yóò wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìṣìnà yín, ṣe ni èmi yóò mú kí a máa gbé inú àwọn ìlú ńlá náà pẹ̀lú,+ a ó sì tún àwọn ibi ìparundahoro náà kọ́.+ 34  Ilẹ̀ tí ó ti di ahoro ni a ó sì ro, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di ahoro lójú gbogbo ẹni tí ń kọjá lọ.+ 35  Àwọn ènìyàn yóò sì wí dájúdájú pé: “Ilẹ̀ ọ̀hún yẹn tí a sọ di ahoro ti dà bí ọgbà Édẹ́nì,+ àwọn ìlú ńlá tí ó ṣófo, tí a sì sọ di ahoro, tí a ya lulẹ̀, ti di olódi; wọ́n ti di gbígbé.”+ 36  Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ṣẹ́ kù ní àyíká yín yóò sì ní láti mọ̀ pé, èmi tìkára mi, Jèhófà, ti kọ́ àwọn ohun tí a ti ya lulẹ̀,+ mo ti gbin ohun tí a ti sọ di ahoro. Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́, mo sì ti ṣe é.’+ 37  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Èyí pẹ̀lú ni ohun tí èmi yóò jẹ́ kí ilé Ísírẹ́lì máa wá mi fún láti ṣe fún wọn:+ Èmi yóò mú kí ènìyàn di púpọ̀ sí i fún wọn bí agbo ẹran.+ 38  Bí agbo àwọn ẹni mímọ́, bí agbo Jerúsálẹ́mù ní àwọn àkókò àjọyọ̀ rẹ̀,+ báyìí ni àwọn ìlú ńlá tí ó ti ṣófo yóò ṣe kún fún agbo ènìyàn;+ àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé