Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 35:1-15

35  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, dojú+ kọ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì,+ kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí i.+  Kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ́, ìwọ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì,+ dájúdájú, èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí ọ,+ èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro, àní ìsọdahoro.+  Àwọn ìlú ńlá rẹ ni èmi yóò sọ di ibi ìparundahoro, ìwọ alára yóò sì di kìkìdá ahoro;+ ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+  nítorí ìdí náà pé ìwọ ní ìṣọ̀tá+ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ sì ń fa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lé agbára idà lọ́wọ́,+ ní àkókò àjálù wọn,+ ní àkókò ìṣìnà wọn tí ó kẹ́yìn.”’+  “‘Nítorí náà, bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni mo ń pèsè rẹ sílẹ̀ fún, àní ẹ̀jẹ̀ yóò máa lépa rẹ.+ Dájúdájú, ẹ̀jẹ̀ ni ìwọ kórìíra, àní ẹ̀jẹ̀ yóò sì máa lépa rẹ.+  Ṣe ni èmi yóò sọ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì di ahoro, àní ìsọdahoro,+ ẹni tí ń gba ibẹ̀ kọjá àti ẹni tí ń padà bọ̀ ni èmi yóò sì ké kúrò nínú rẹ̀.+  Dájúdájú, èmi yóò fi àwọn tí a pa kún àwọn òkè ńlá rẹ̀; ní ti àwọn òkè kéékèèké rẹ àti àwọn àfonífojì rẹ àti gbogbo ojú ìṣàn omi rẹ, àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú sínú wọn dájúdájú.+  Ahoro tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò ṣe ọ́, a kì yóò sì gbé inú àwọn ìlú ńlá rẹ;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+ 10  “Nítorí tí ìwọ ń sọ pé, ‘Orílẹ̀-èdè méjì yìí àti ilẹ̀ méjì yìí—wọn yóò di tèmi, dájúdájú, àwa yóò sì gba ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan,’+ nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà tìkára rẹ̀ wà níbẹ̀,+ 11  ‘nítorí náà, bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘ṣe ni èmi yóò gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ìbínú rẹ àti gẹ́gẹ́ bí owú rẹ tí o ti fi hàn nítorí ìkórìíra tí o ní sí wọn;+ ṣe ni èmi yóò sì sọ ara mi di mímọ̀ láàárín wọn nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ.+ 12  Ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ti gbọ́ nípa gbogbo ohun aláìlọ́wọ̀ rẹ tí o ti sọ nípa àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì,+ pé: “A ti sọ wọ́n di ahoro. A ti fi wọ́n ṣe oúnjẹ fún wa.”+ 13  Ẹ̀yin sì ń fi ẹnu+ yín fi mí ṣakọ, ẹ sì ti sọ ọ̀rọ̀ yín di púpọ̀ lòdì sí mi.+ Èmi alára ti gbọ́.’+ 14  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní àkókò kan náà tí gbogbo ilẹ̀ ayé ń yọ̀, ṣe ni èmi yóò sọ ìwọ di ahoro. 15  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ tí ń yọ̀ nígbà jíjogún ilé Ísírẹ́lì nítorí pé a sọ ọ́ di ahoro, ohun kan náà ni èmi yóò fi ọ́ ṣe.+ Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì, àní gbogbo Édómù, gbogbo rẹ̀ pátá;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé