Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 34:1-31

34  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì. Sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún wọn, fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì,+ àwọn tí ó ti di olùbọ́ ara wọn!+ Kì í ha ṣe agbo ẹran ni ó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa bọ́?+  Ọ̀rá ni ẹ ń jẹ,+ irun àgùntàn sì ni ẹ fi ń wọ ara yín. Ẹran sísanra rọ̀múrọ̀mú+ ni ẹ ń pa.+ Agbo ẹran pàápàá ni ẹ kò bọ́.  Àwọn tí ń ṣàìsàn ni ẹ kò fún lókun,+ èyí tí ń ṣòjòjò ni ẹ kò sì mú lára dá, èyí tí ó fara pa ni ẹ kò sì fi ọ̀já wé, èyí tí a lé lọ ni ẹ kò sì mú padà bọ̀, èyí tí ó sọnù ni ẹ kò sì wá ọ̀nà láti rí,+ ṣùgbọ́n ọwọ́ lílé koko ni ẹ fi ń tẹ̀ wọ́n lórí ba, àní pẹ̀lú ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.+  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n tú ká nítorí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn,+ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n di oúnjẹ fún gbogbo ẹranko inú pápá, wọ́n sì ń bá a lọ láti wà ní títúká.+  Àwọn àgùntàn mi ń ṣáko lọ ṣáá lórí gbogbo òkè ńlá àti lórí gbogbo òkè kéékèèké gíga;+ orí ilẹ̀ gbogbo sì ni àwọn àgùntàn mi+ tú ká sí, láìsí ẹni tí ń wá wọn kiri àti láìsí ẹni tí ń wá ọ̀nà láti rí wọn.  “‘“Nítorí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,  ‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, “dájúdájú, nítorí ìdí náà pé àwọn àgùntàn mi di ohun ìpiyẹ́, tí àwọn àgùntàn mi sì ń bá a lọ láti di oúnjẹ fún gbogbo ẹranko inú pápá, nítorí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn kankan, tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò sì wá àwọn àgùntàn mi, ṣùgbọ́n tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń bọ́ ara wọn,+ tí wọn kò sì bọ́ àwọn àgùntàn mi,”’  nítorí náà, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 10  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn,+ dájúdájú, èmi yóò sì béèrè àwọn àgùntàn mi padà lọ́wọ́ wọn, èmi yóò sì mú kí wọ́n ṣíwọ́ bíbọ́ àwọn àgùntàn mi,+ àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà kì yóò sì bọ́ ara wọn mọ́;+ ṣe ni èmi yóò dá àwọn àgùntàn mi nídè kúrò ní ẹnu wọn, wọn kì yóò sì di oúnjẹ fún wọn.’”+ 11  “‘Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Èmi rèé, àní èmi, èmi yóò sì wá àwọn àgùntàn mi, èmi yóò sì bójú tó wọn dájúdájú.+ 12  Gẹ́gẹ́ bí àbójútó ẹni tí ń bọ́ agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀+ ní ọjọ́ tí ó wà ní àárín àwọn àgùntàn rẹ̀ tí a fọ́n ká,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi; ṣe ni èmi yóò dá wọn nídè kúrò ní gbogbo ibi tí a tú wọn ká sí ní ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù nínípọn.+ 13  Ṣe ni èmi yóò mú wọn jáde+ kúrò láàárín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀ láti àwọn ilẹ̀,+ èmi yóò mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò sì bọ́ wọn ní orí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì, lẹ́bàá àwọn ojú ìṣàn omi àti lẹ́bàá gbogbo ibi gbígbé ilẹ̀ náà.+ 14  Ní pápá ìjẹko tí ó dára ni èmi yóò ti bọ́ wọn, orí àwọn òkè ńlá gíga ti Ísírẹ́lì sì ni àwọn ibi gbígbé wọn yóò wà.+ Ibẹ̀ ni wọn yóò dùbúlẹ̀ sí ní ibi gbígbé tí ó dára,+ orí pápá ìjẹko ọlọ́ràá ni wọn yóò sì ti máa jẹ lórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì.” 15  “‘“Èmi alára yóò bọ́ àwọn àgùntàn mi,+ èmi alára yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 16  “Èyí tí ó sọnù ni èmi yóò wá kiri,+ èyí tí a lé lọ ni èmi yóò sì mú padà bọ̀, èyí tí ó fara pa ni èmi yóò sì fi ọ̀já wé, èyí tí ń ṣòjòjò ni èmi yóò sì fún lókun, ṣùgbọ́n èyí tí ó sanra+ àti èyí tí ó lágbára ni èmi yóò pa rẹ́ ráúráú. Èmi yóò fi ìdájọ́ bọ́ ìyẹn.”+ 17  “‘Àti ní ti ẹ̀yin àgùntàn mi, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àgùntàn àti àgùntàn, láàárín àwọn àgbò àti àwọn òbúkọ.+ 18  Ohun kékeré bẹ́ẹ̀ ha ni lójú yín pé, orí pápá ìjẹko tí ó dára jù lọ ni ẹ ti ń jẹ+ ṣùgbọ́n ìyókù pápá ìjẹko yín ni ẹ ń fi ẹsẹ̀ yín tẹ̀ mọ́lẹ̀, àti pé omi mímọ́gaara ni ẹ ń mu ṣùgbọ́n èyí tí ó ṣẹ́ kù ni ẹ sọ di àìmọ́ nípa fífi ẹsẹ̀ yín rú u? 19  Àti ní ti àwọn àgùntàn mi, ṣé orí ilẹ̀ ìjẹko tí ẹ fi ẹsẹ̀ yín tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí wọ́n ti máa jẹ, ṣe omi tí ó di àìmọ́ nípa ẹsẹ̀ yín tí ó rú u ni ó yẹ kí wọ́n máa mu?” 20  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún wọn: “Èmi rèé, àní èmi, dájúdájú, èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àgùntàn sísanra rọ̀múrọ̀mú àti àgùntàn tí ó rù, 21  nítorí ìdí náà pé ìhà àti èjìká ni ẹ fi ń tì wọ́n, ìwo yín sì ni ẹ fi ń rọ́ gbogbo àwọn tí ń ṣàìsàn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, títí ẹ fi tú wọn ká sí òde.+ 22  Dájúdájú, èmi yóò gba àwọn àgùntàn mi là, wọn kì yóò di ohun ìpiyẹ́ mọ́;+ ṣe ni èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ láàárín àgùntàn àti àgùntàn. 23  Ṣe ni èmi yóò gbé olùṣọ́ àgùntàn kan dìde sórí wọn,+ òun yóò sì máa bọ́ wọn, àní ìránṣẹ́ mi Dáfídì.+ Òun fúnra rẹ̀ yóò máa bọ́ wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì di olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ 24  Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò sì di Ọlọ́run wọn,+ ìránṣẹ́ mi Dáfídì yóò sì di ìjòyè kan ní àárín wọn.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́. 25  “‘“Dájúdájú, èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà,+ èmi yóò sì mú kí aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà kásẹ̀ nílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ wọn yóò sì máa gbé ní ààbò ní aginjù ní ti tòótọ́, wọn yóò sì sùn nínú igbó.+ 26  Ṣe ni èmi yóò sọ àwọn àti àwọn àyíká òkè kékeré mi di ìbùkún,+ èmi yóò sì mú kí ọ̀yamùúmùú òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀. Ọ̀yamùúmùú òjò ìbùkún yóò wà.+ 27  Igi pápá yóò sì mú èso rẹ̀ wá,+ ilẹ̀ náà yóò sì mú èso rẹ̀ wá,+ wọn yóò sì wà lórí ilẹ̀ wọn ní ààbò+ ní ti tòótọ́. Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà wọn,+ nígbà tí mo bá dá wọn nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn tí ó ti ń lò wọ́n bí ẹrú.+ 28  Wọn kì yóò di ohun ìpiyẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè mọ́;+ àti ní ti ẹranko ẹhànnà ilẹ̀ ayé, kì yóò pa wọ́n jẹ, wọn yóò sì máa gbé ní ààbò ní ti tòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní mú wọn wárìrì.+ 29  “‘“Dájúdájú, èmi yóò sì gbé ọ̀gbìn kan dìde fún wọn láti fi gba orúkọ,+ wọn kì yóò sì di àwọn tí ìyàn kó kúrò ní ilẹ̀ náà mọ́,+ wọn kì yóò sì ru ìtẹ́lógo láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́.+ 30  ‘Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run wọn, wà pẹ̀lú wọn,+ pé wọ́n sì jẹ́ ènìyàn mi, ilé Ísírẹ́lì,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’+ 31  “‘Àti ní ti ẹ̀yin àgùntàn mi,+ ẹ̀yin àgùntàn mi tí ń jẹ̀, ará ayé ni yín. Èmi ni Ọlọ́run yín,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé