Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 33:1-33

33  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, bá àwọn ọmọ ènìyàn rẹ sọ̀rọ̀,+ kí o sì wí fún wọn pé, “‘Ní ti ilẹ̀ kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé mo mú idà+ wá sórí rẹ̀ tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, sì mú ènìyàn kan, tí wọ́n sì yàn án ṣe olùṣọ́ wọn+ ní tòótọ́,  tí ó sì rí idà tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ náà ní ti tòótọ́, tí ó sì fun ìwo, tí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà,+  tí olùgbọ́ sì gbọ́ ìró ìwo náà ní ti tòótọ́, ṣùgbọ́n tí kò gba ìkìlọ̀ rárá,+ tí idà sì dé, tí ó sì mú un kúrò, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wá wà lórí òun tìkára rẹ̀.+  Ó gbọ́ ìró ìwo, ṣùgbọ́n kò gba ìkìlọ̀. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí òun tìkára rẹ̀. Ká ní òun alára ti gba ìkìlọ̀ ni, ọkàn rẹ̀ ì bá yè bọ́.+  “‘Wàyí o, ní ti olùṣọ́ náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó rí idà tí ń bọ̀ tí kò sì fun ìwo+ ní ti tòótọ́, tí àwọn ènìyàn kò sì rí ìkìlọ̀ gbà rárá, tí idà sì dé, tí ó sì mú ọkàn kúrò láti àárín wọn, fún ìṣìnà tirẹ̀, òun gan-an ni a óò mú kúrò,+ ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè lọ́wọ́ olùṣọ́ náà fúnra rẹ̀.’+  “Wàyí o, ní ti ìwọ, ọmọ ènìyàn, olùṣọ́ ni mo fi ọ́ ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,+ ìwọ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹnu mi, ìwọ yóò sì fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.+  Nígbà tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ìwọ ẹni burúkú, dájúdájú, ìwọ yóò kú!’+ ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sọ̀rọ̀ ní tòótọ́ láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kí ó kúrò ní ọ̀nà rẹ̀,+ òun alára gẹ́gẹ́ bí ẹni burúkú yóò kú nínú ìṣìnà rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ.  Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ kìlọ̀ fún ẹni burúkú ní ti tòótọ́, pé kí ó kúrò ní ọ̀nà rẹ̀, láti yí padà kúrò nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n tí òun kò yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀ ní ti tòótọ́, òun alára yóò kú nínú ìṣìnà rẹ̀,+ nígbà tí ó jẹ́ pé ìwọ alára yóò dá ọkàn rẹ nídè dájúdájú.+ 10  “Wàyí o, ní ti ìwọ, ọmọ ènìyàn, sọ́ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Báyìí ni ẹ wí: “Nítorí pé ìdìtẹ̀ wa àti ẹ̀ṣẹ̀ wa ń bẹ lórí wa àti pé àwa ń jẹrà dànù nínú wọn,+ báwo wá ní àwa yóò ṣe máa wà láàyè nìṣó?”’+ 11  Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, “èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú,+ bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí padà kúrò+ nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó ní tòótọ́.+ Ẹ yí padà, ẹ yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín,+ nítorí kí ni ẹ ó ṣe kú, ilé Ísírẹ́lì?”’+ 12  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ọmọ ènìyàn rẹ pé, ‘Òdodo olódodo kì yóò dá a nídè ní ọjọ́ ìdìtẹ̀ rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n ní ti ìwà burúkú ẹni burúkú, èyí kì yóò mú un kọsẹ̀ ní ọjọ́ tí ó bá yí padà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ̀.+ Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń ṣe òdodo pàápàá kì yóò lè máa wà láàyè nìṣó nítorí èyí ní ọjọ́ tí ó bá dẹ́ṣẹ̀.+ 13  Nígbà tí mo bá sọ fún olódodo pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò máa wà láàyè nìṣó,” tí òun alára sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé ní tòótọ́ nínú òdodo tirẹ̀, tí ó sì ṣe àìṣèdájọ́ òdodo,+ gbogbo ìṣe òdodo tirẹ̀ ni a kì yóò rántí, ṣùgbọ́n nítorí àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe—òun yóò kú nítorí èyí.+ 14  “‘Nígbà tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: “Dájúdájú ìwọ yóò kú,”+ tí ó sì yí padà ní tòótọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ tí ó sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo,+ 15  tí ẹni burúkú náà sì dá ohun náà tí a fi dógò padà,+ tí ó san àwọn ohun náà tí a gbà nípa ìjanilólè padà,+ tí ó sì ń rìn ní tòótọ́ nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ìyè nípa ṣíṣàìṣe àìṣèdájọ́ òdodo,+ dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó.+ Òun kì yóò kú. 16  Kò sí ìkankan nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ tí a óò rántí lòdì sí i.+ Ó ti ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo. Dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó.’+ 17  “Àwọn ọmọ ènìyàn rẹ sì wí pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò gún,’+ ṣùgbọ́n, ní ti wọn, ọ̀nà wọn ni kò gún. 18  “Nígbà tí olódodo bá yí padà kúrò nínú òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣèdájọ́ òdodo ní tòótọ́, òun yóò kú nítorí wọn pẹ̀lú.+ 19  Nígbà tí ẹni burúkú bá sì yí padà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ̀, tí ó sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní tòótọ́, ní tìtorí ìwọ̀nyí ni òun alára yóò fi máa wà láàyè nìṣó.+ 20  “Ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò gún.’+ Olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ ni èmi yóò dá yín lẹ́jọ́,+ ilé Ísírẹ́lì.” 21  Nígbà tí ó ṣe, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kejìlá, ní oṣù kẹwàá, ní [ọjọ́] karùn-ún oṣù ìgbèkùn wa, pé olùsálà láti Jerúsálẹ́mù+ tọ̀ mí wá, ó wí pé: “A ti ṣá ìlú ńlá náà balẹ̀!”+ 22  Wàyí o, àní ọwọ́ Jèhófà wà lára mi ní alẹ́, ṣáájú dídé olùsálà náà,+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí ẹnu mi kí ẹni yẹn tó dé ọ̀dọ̀ mi ní òwúrọ̀, ẹnu mi sì là, èmi kò sì jẹ́ aláìlèsọ̀rọ̀ mọ́.+ 23  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá, pé: 24  “Ọmọ ènìyàn, àwọn olùgbé ibi ìparundahoro+ wọ̀nyí ń sọ, àní nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ábúráhámù jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo, síbẹ̀, ó gba ilẹ̀ náà.+ Àwa sì pọ̀; àwa ni a ti fi ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’+ 25  “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀ ni ẹ ń jẹun,+ ẹ sì ń gbé ojú yín sókè sí àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín,+ ẹ sì ń da ẹ̀jẹ̀ jáde.+ Nítorí náà, ẹ̀yin yóò ha fi ilẹ̀ náà ṣe ìní bí?+ 26  Ẹ̀yin ti gbára lé idà yín.+ Ẹ ti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí,+ olúkúlùkù yín sì ti sọ aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+ Nítorí náà, ẹ ó ha fi ilẹ̀ náà ṣe ìní bí?”’+ 27  “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Bí mo ti ń bẹ láàyè, dájúdájú, àwọn tí wọ́n wà ní ibi ìparundahoro yóò tipa idà ṣubú;+ ẹni tí ó sì wà lórí pápá ni èmi yóò fi ṣe oúnjẹ fún ẹranko ìgbẹ́ dájúdájú;+ àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi tí ó lágbára àti inú àwọn hòrò+ yóò kú nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn. 28  Èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro+ ní ti tòótọ́, àní ìsọdahoro, a ó sì mú kí ìyangàn okun rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀,+ a ó sì sọ àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì di ahoro,+ láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò máa gba ibẹ̀ kọjá. 29  Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ àní ìsọdahoro, ní tìtorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn tí wọ́n ti ṣe.”’+ 30  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, àwọn ọmọ ènìyàn rẹ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì nípa rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà àwọn ilé,+ ẹnì kìíní sì ń bá ẹnì kejì sọ̀rọ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà jáde.’+ 31  Wọn yóò sì wọlé wá bá ọ, bí ìwọlé wá àwọn ènìyàn, wọn yóò sì jókòó níwájú rẹ bí àwọn ènìyàn mi;+ wọn yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ dájúdájú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò ṣe wọ́n,+ nítorí ẹnu wọn ni wọ́n fi ń sọ ìfẹ́-ọkàn onífẹ̀ẹ́kúfẹ̀ẹ́ jáde, èrè wọn aláìbá ìdájọ́ òdodo mu sì ni ọkàn-àyà wọn ń tọ̀ lẹ́yìn.+ 32  Sì wò ó! lójú wọn, ìwọ dà bí orin ìfẹ́ tí ń ru ìmọ̀lára sókè, bí ẹni tí ó ní ohùn iyọ̀, tí ó sì ń ta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín dáadáa.+ Wọn yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ dájúdájú, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí yóò ṣe wọ́n.+ 33  Nígbà tí ó bá sì ṣẹ—wò ó! yóò ṣẹ+—àwọn pẹ̀lú yóò ní láti mọ̀ pé wòlíì kan ti wà ní àárín wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé