Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 32:1-32

32  Ó sì tún ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kejìlá, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, gbé ohùn orin arò sókè nípa Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì wí fún un pé, ‘Bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ti àwọn orílẹ̀-èdè ni a ṣe pa ọ́ lẹ́nu mọ́.+ “‘Ìwọ sì dà bí ẹran ńlá abàmì inú òkun,+ ìwọ sì ń tú pùúpùú nínú àwọn odò rẹ, ìwọ sì ń fi ẹsẹ̀ rẹ sọ omi di onípẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀, o sì ń sọ àwọn odò wọn di àìmọ́.’  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ṣe ni èmi yóò na àwọ̀n+ mi lé ọ nípasẹ̀ ìjọ ènìyàn púpọ̀, ṣe ni wọn yóò mú ọ wá nínú àwọ̀n ńlá mi.+  Èmi yóò sì pa ọ́ tì sórí ilẹ̀. Orí pápá ni èmi yóò fi ọ́ sọ̀kò sí.+ Ṣe ni èmi yóò mú gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run máa gbé orí rẹ, ṣe ni èmi yóò sì tẹ́ àwọn ẹranko ìgbẹ́ gbogbo ilẹ̀ ayé lọ́rùn lára rẹ.+  Dájúdájú, èmi yóò fi ẹran ara rẹ sórí àwọn òkè ńlá, èmi yóò sì fi pàǹtírí ara rẹ kún àwọn àfonífojì.+  Ṣe ni èmi yóò mú kí ilẹ̀ fa ohun tí ó jáde láti ara rẹ mu, láti inú ẹ̀jẹ̀ rẹ,+ lórí àwọn òkè ńlá; àwọn ojú ìṣàn omi pàápàá yóò sì kún fún ọ.’  “‘Nígbà tí a bá mú òpin dé bá ọ, èmi yóò bo ojú ọ̀run, èmi yóò sì mú àwọn ìràwọ̀ wọn ṣókùnkùn dájúdájú. Ní ti oòrùn, èmi yóò fi àwọsánmà bò ó, òṣùpá pàápàá kì yóò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn.+  Gbogbo orísun ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run—èmi yóò mú wọn ṣókùnkùn ní tìtorí rẹ, ṣe ni èmi yóò fi òkùnkùn sórí ilẹ̀ rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì mú ọkàn-àyà ọ̀pọ̀ ènìyàn bínú nígbà tí mó bá kó àwọn òǹdè láti inú rẹ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lọ sí àwọn ilẹ̀ tí ìwọ kò mọ̀.+ 10  Èmi yóò sì mú kí ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì+ kọlu àwọn ènìyàn nítorí rẹ, àwọn ọba wọn alára yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì nínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ nítorí rẹ nígbà tí mo bá ju idà mi fìrìfìrì níwájú wọn,+ ó dájú pé wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìṣẹ́jú, olúkúlùkù fún ọkàn rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.’+ 11  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Àní ìdà ọba Bábílónì yóò wá sórí rẹ.+ 12  Èmi yóò mú kí ogunlọ́gọ̀ rẹ ṣubú nípa idà àwọn alágbára ńlá, àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo wọn pátá;+ wọn yóò sì fi ohun ìyangàn Íjíbítì ṣe ìjẹ ní ti tòótọ́, gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ ni a ó sì pa rẹ́ ráúráú.+ 13  Ṣe ni èmi yóò pa gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀ run kúrò lẹbàá omi púpọ̀,+ ẹsẹ̀ ará ayé kì yóò sì sọ wọ́n di onípẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀+ mọ́, àní pátákò ẹran agbéléjẹ̀ kì yóò sọ wọ́n di onípẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀.’ 14  “‘Ní àkókò yẹn, èmi yóò mú kí omi wọn mọ́ gaara, èmi yóò sì mú kí odò wọn ṣàn bí òróró’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 15  “‘Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro, tí ilẹ̀ náà sì di ahoro láìní ẹ̀kún+ rẹ̀ mọ́, nígbà tí mo bá ṣá gbogbo àwọn olùgbé rẹ̀ balẹ̀, wọn yóò sì ní láti mọ̀ pẹ̀lú pé èmi ni Jèhófà.+ 16  “‘Orin arò ni èyí, ṣe ni àwọn ènìyàn yóò máa kọ ọ́. Àní àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa kọ ọ́;+ lórí Íjíbítì àti lórí gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ ni wọn yóò máa kọ ọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 17  Ó sì tún ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé: 18  “Ọmọ ènìyàn, ṣèdárò lórí ogunlọ́gọ̀ Íjíbítì, kí o sì mú un sọ̀ kalẹ̀,+ òun àti àwọn ọmọbìnrin àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá ńlá, sí ilẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+ 19  “‘Ta ni ìwọ jẹ́ ẹni gbígbádùnmọni jù ní ìfiwéra?+ Sọ̀ kalẹ̀, kí a sì tẹ́ ọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́!’+ 20  “‘Àárín àwọn tí a fi idà pa ni wọn yóò ṣubú sí.+ A ti  fi í fún idà. Ẹ wọ́ ọ lọ tòun ti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀. 21  “‘Àwọn tí ó wà ní ipò iwájú nínú àwọn alágbára ńlá yóò sọ̀rọ̀ láti inú Ṣìọ́ọ̀lù àní sí i, pẹ̀lú àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.+ Wọn yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ dájúdájú;+ wọn yóò dùbúlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìdádọ̀dọ́, tí a fi idà pa. 22  Ibẹ̀ ni Ásíríà àti gbogbo ìjọ rẹ̀ wà.+ Àwọn ibi ìsìnkú rẹ̀ wà yí i ká. Gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí wọ́n típa idà ṣubú.+ 23  Nítorí a ti fi àwọn ibi ìsìnkú rẹ̀ sí ìhà inú kòtò+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ìjọ rẹ̀ sì wà yí ká sàréè rẹ̀, gbogbo wọn ni a pa, ní títipa idà ṣubú, nítorí pé wọ́n fa ìpayà ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 24  “‘Ibẹ̀ ni Élámù+ wà àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ yí ká sàréè rẹ̀, gbogbo wọn ni a pa, àwọn tí wọ́n tipa idà ṣubú, àwọn tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìdádọ̀dọ́ lọ sí ilẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀, àwọn tí wọ́n fa ìpayà wọn ní ilẹ̀ àwọn alààyè; wọn yóò sì ru ìtẹ́lógo wọn pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+ 25  Àárín àwọn tí a pa ni wọ́n gbé ibùsùn+ kalẹ̀ sí fún un láàárín gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀. Àwọn ibi ìsìnkú rẹ̀ wà yí ibùsùn náà ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, tí a fi idà pa,+ nítorí pé a dá ìpayà wọn sílẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè; wọn yóò sì ru ìtẹ́lógo wọn pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò. Àárín àwọn tí a pa ni a gbé e sí. 26  “‘Ibẹ̀ ni Méṣékì+ àti Túbálì+ àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ wà. Àwọn ibi ìsìnkú rẹ̀ wà yí i ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, tí a fi idà gún ní àgúnyọ, nítorí wọ́n ti dá ìpayà wọn sílẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 27  Wọn kì yóò ha sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá,+ tí ń ṣubú láti àárín àwọn aláìdádọ̀dọ́, àwọn tí wọ́n ti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù ti àwọn ti ohun ìjà ogun wọn? Wọn yóò sì fi idà wọn sábẹ́ orí wọn, ìṣìnà wọn yóò sì wà lára egungun wọn,+ nítorí pé àwọn alágbára ńlá jẹ́ ìpayà ní ilẹ̀ àwọn alààyè.+ 28  Ní ti ìwọ, a óò ṣẹ́ ọ ní àárín àwọn aláìdádọ̀dọ́, ìwọ yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. 29  “‘Ibẹ̀ ni Édómù,+ àwọn ọba rẹ̀ àti gbogbo ìjòyè rẹ̀ wà, àwọn tí ó jẹ́ pé, nínú agbára ńlá wọn, a fi wọ́n pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa;+ àwọn alára yóò dùbúlẹ̀ àní pẹ̀lú àwọn aláìdádọ̀dọ́+ àti pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò. 30  “‘Ibẹ̀ ni àwọn mọ́gàjí àríwá wà, gbogbo wọn pátá, àti gbogbo àwọn ọmọ Sídónì,+ tí wọ́n ti sọ̀ kalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn tí a pa, nínú ìjayà wọn nítorí agbára ńlá wọn, pẹ̀lú ìtìjú. Wọn yóò sì dùbúlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìdádọ̀dọ́ pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn yóò sì ru ìtẹ́lógo wọn pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.+ 31  “‘Àwọn wọ̀nyí ni Fáráò yóò rí, a ó sì tù ú nínú nítorí gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀+ Fáráò àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí a fi idà pa,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 32  “‘Nítorí tí ó ti dá ìpayà rẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè,+ a ó sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ láàárín àwọn aláìdádọ̀dọ́, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, àní Fáráò àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé