Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 31:1-18

31  Ó sì tún ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kẹta, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Fáráò ọba Íjíbítì àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀+ pé, “‘Ta ni ìwọ jọ nínú ìtóbi rẹ?  Wò ó! Ará Ásíríà kan, kédárì kan ní Lẹ́bánónì,+ tí ó rẹwà ní ẹ̀tun,+ pẹ̀lú ìgbòrò tí ó ṣù ṣìkìtì tí ó pèsè òjìji, tí ó sì ga ní ìdúró,+ tí ó fi jẹ́ pé téńté rẹ̀ wà láàárín àwọsánmà.+  Omi ni ó mú un tóbi;+ ibú omi ni ó mú kí ó dàgbà sókè. Ìṣàn rẹ̀ ni o ń mú kí ó lọ yí ká ibi tí a gbìn ín sí; ó sì rán ipa ojú ọ̀nà rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ gbogbo igi inú pápá.  Ìdí nìyẹn tí ó fi ga sókè ní ìdúró rẹ̀ ju gbogbo igi yòókù nínú pápá.+ “‘Àwọn ẹ̀tun rẹ̀ sì ń di púpọ̀ sí i, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ń gùn sí i nítorí pé omi púpọ̀ wà ní àwọn ipadò rẹ̀.+  Orí àwọn ẹ̀tun rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run kọ́ ìtẹ́ wọn sí,+ abẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni gbogbo ẹranko inú pápá ti ń bímọ,+ inú ibòji rẹ̀ sì ni gbogbo orílẹ̀-èdè elénìyàn púpọ̀ ń gbé.  Ó sì wá lẹ́wà ní ìtóbi rẹ̀,+ ní gígùn àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé, nítorí pé àwọn gbòǹgbò rẹ̀ wà ní orí omi púpọ̀.  Àwọn kédárì yòókù kò lè bá a dọ́gba nínú ọgbà Ọlọ́run.+ Ní ti àwọn igi júnípà, wọn kò jọ àwọn ẹ̀tun rẹ̀ rárá. Àwọn igi adánra pàápàá kò dà bí rẹ̀ ní ti ẹ̀ka. Kò sí igi mìíràn nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó jọ ọ́ ní ẹwà fífanimọ́ra rẹ̀.+  Arẹwà ni mo ṣe é nínú ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀ka rẹ̀ eléwé,+ gbogbo igi yòókù nínú Édẹ́nì, àwọn tí ó wà nínú ọgbà Ọlọ́run tòótọ́ sì ń ṣe ìlara rẹ̀.’+ 10  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé ìwọ ga ní ìdúró, tí ó fi fi téńté rẹ̀ sí àárín àwọsánmà+ pàápàá, tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì di èyí tí ó gbé ga nítorí gíga rẹ̀,+ 11  èmi náà yóò fi í sí ọwọ́ abàṣẹwàá àwọn orílẹ̀-èdè.+ Láìkùnà, òun yóò gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí i. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwà burúkú rẹ̀, ṣe ni èmi yóò lé e jáde.+ 12  Àwọn àjèjì, àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti àwọn orílẹ̀-èdè, yóò gé e lulẹ̀, àwọn ènìyàn yóò sì pa á tì sórí àwọn òkè ńlá; ó sì dájú pé gbogbo àfonífojì ni àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé yóò já bọ́ sí, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a óò sì ṣẹ́ ní àárín gbogbo ojú ìṣàn omi ilẹ̀ ayé.+ Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé yóò sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ibòji rẹ̀, wọn yóò sì pa á tì.+ 13  Orí ìtì rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run yóò máa gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni gbogbo ẹranko inú pápá yóò wà dájúdájú;+ 14  tí yóò fi jẹ́ pé kò ní sí ìkankan nínú àwọn igi tí a bomi rin tí yóò ga ní ìdúró wọn, tàbí tí yóò fi téńté wọn sí àárín àwọsánmà pàápàá, tí kì yóò sì fi sí igi èyíkéyìí tí ń mu omi tí yóò dìde sí i nínú gíga wọn, nítorí pé a ó fi gbogbo wọn fún ikú dájúdájú,+ fún ilẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀,+ ní àárín àwọn ọmọ aráyé, fún àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò.’ 15  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní ọjọ́ tí ó bá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù, èmi yóò fa ìṣọ̀fọ̀ dájúdájú.+ Ní tìtorí rẹ̀, ṣe ni èmi yóò bo ibú omi, kí n lè fawọ́ ìṣàn rẹ̀ sẹ́yìn, kí a sì lè dá ìṣàn omi púpọ̀ dúró; àti ní tìtorí rẹ̀, èmi yóò mú Lẹ́bánónì ṣókùnkùn, àti ní tìtorí rẹ̀, gbogbo igi inú pápá yóò dákú lọ gbári. 16  Nígbà ìró ìṣubú rẹ̀, ṣe ni èmi yóò mú kí àwọn orílẹ̀-èdè mì jìgìjìgì nígbà tí mó bá mú un sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò,+ àti ní ilẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀, gbogbo igi Édẹ́nì,+ ààyò jù lọ àti èyí tí ó dára jù lọ ti Lẹ́bánónì, gbogbo àwọn tí ń mu omi, ni a ó tù nínú.+ 17  Àwọn náà ti sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù,+ sọ́dọ̀ àwọn tí a fi idà pa, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n ti gbé gẹ́gẹ́ bí irú-ọmọ rẹ̀ nínú òjìji rẹ̀ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè.’+ 18  “‘Ta ni ìwọ wá fi ògo+ àti ìtóbi jọ báyìí láàárín àwọn igi Édẹ́nì?+ Ṣùgbọ́n mímú ni a óò mú ọ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì wá sí ilẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀.+ Àárín àwọn aláìdádọ̀dọ́ ni ìwọ yóò dùbúlẹ̀ sí pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Èyí ni Fáráò àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé