Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 30:1-26

30  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí pé,+ ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ẹ hu pé, ‘Págà fún ọjọ́ náà!’+  nítorí ọjọ́ kan sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ ni, ọjọ́ tí ó jẹ́ ti Jèhófà sún mọ́lé.+ Ọjọ́ àwọsánmà,+ àkókò tí a yàn kalẹ̀ vfún àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò jẹ́.+  Idà kan yóò wá sí Íjíbítì,+ ìrora mímúná yóò sì wà ní Etiópíà nígbà tí ẹnì kan yóò ṣubú lulẹ̀ ní òkú ní Íjíbítì, tí wọn yóò sì kó ọlà ilẹ̀ náà ní tòótọ́, tí a ó sì ya ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀ ní tòótọ́.+  Etiópíà+ àti Pútì+ àti Lúdì àti gbogbo àwùjọ onírúurú ènìyàn+ àti Kúbù àti àwọn ọmọ ilẹ̀ májẹ̀mú—pẹ̀lú wọn ni wọn yóò tipa ida ṣubú.”’+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Àwọn alátìlẹyìn Íjíbítì yóò ṣubú pẹ̀lú, ìyangàn okun rẹ̀ yóò sì wálẹ̀.’+ “‘Láti Mígídólì+ dé Síénè,+ àní wọn yóò tipa idà ṣubú nínú rẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.  ‘A ó sọ wọ́n di ahoro pẹ̀lú láàárín àwọn ilẹ̀ tí a ti sọ di ahoro, àwọn ìlú ńlá rẹ̀ yóò sì wá wà gan-an ní àárín àwọn ìlú ńlá tí a pa run di ahoro.+  Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dá iná sí Íjíbítì, tí a sì ṣẹ́ gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní ti tòótọ́.+  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ońṣẹ́ yóò jáde lọ láti iwájú mi nínú àwọn ọkọ̀ òkun, láti kó Etiópíà agbọ́kànlé-ara-ẹni sínú ìwárìrì.+ Ìrora mímúná yóò sì wà láàárín wọn ní ọjọ́ Íjíbítì, nítorí, wò ó! yóò dé.’+ 10  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣe ni èmi yóò mú kí ogunlọ́gọ̀ Íjíbítì kásẹ̀ nílẹ̀ nípa ọwọ́ Nebukadirésárì ọba Bábílónì.+ 11  Òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti àwọn orílẹ̀-èdè,+ ni a ń kó bọ̀ láti run ilẹ̀ náà. Wọn yóò sì fa idà wọn yọ sí Íjíbítì, wọn yóò sì fi àwọn tí a pa kún ilẹ̀ náà.+ 12  Ṣe ni èmi yóò sọ àwọn ipa odò Náílì+ di ilẹ̀ gbígbẹ, èmi yóò ta ilẹ̀ náà sí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,+ èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ náà àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ di ahoro nípa ọwọ́ àwọn àjèjì.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’+ 13  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ṣe ni èmi yóò pa àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ run pẹ̀lú,+ èmi yóò sì mú kí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nófì,+ kì yóò sí ìjòyè mọ́ láti ilẹ̀ Íjíbítì; ṣe ni èmi yóò sì fi ìbẹ̀rù sí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò sì mú Pátírọ́sì+ wá sí ìsọdahoro, èmi yóò sì dá iná sí Sóánì,+ èmi yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún ní Nóò.+ 15  Ṣe ni èmi yóò da ìhónú+ mi sórí Sínì, odi agbára Íjíbítì, èmi yóò sì ké ogunlọ́gọ̀ Nóò+ kúrò. 16  Ṣe ni èmi yóò dá iná sí Íjíbítì. Láìkùnà, Sínì yóò sì jẹ ìrora mímúná, Nóò alára yóò wà fún ìkólọ nípasẹ̀ àlàfo; àti ní ti Nófì—àwọn elénìní yóò wà ní ojúmọmọ! 17  Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ónì+ àti Píbésétì, nípa idà ni wọn yóò ṣubú, àwọn ìlú ńlá náà yóò sì lọ sí oko òǹdè. 18  Ní Tehafínéhésì,+ ọ̀sán yóò ṣókùnkùn ní ti gidi, nígbà tí mó bá ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà Íjíbítì+ níbẹ̀. A ó sì mú kí ìyangàn okun rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.+ Ní tirẹ̀, àwọsánmà pàápàá yóò bò ó,+ àwọn àrọko rẹ̀ yóò sì lọ sí oko òǹdè.+ 19  Dájúdájú, èmi yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún ní Íjíbítì;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’” 20  Ó sì ṣẹlẹ̀ síwájú sí i pé ní ọdún kọkànlá, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ keje oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé: 21  “Ọmọ ènìyàn, apá Fáráò ọba Íjíbítì ni èmi yóò ṣẹ́+ dájúdájú, sì wò ó! a kì yóò dì í rárá láti jẹ́ kí ó sàn nípa fífi ọ̀já-ìdi-ọgbẹ́ dì í mọ́ra,+ kí ó lè di lílé láti di idà mú.” 22  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ Fáráò ọba Íjíbítì,+ dájúdájú, èmi yóò ṣẹ́ apá rẹ̀,+ èyí tí ó le àti èyí tí ó ṣẹ́,+ ṣe ni èmi yóò sì mú kí idà já bọ́ ní ọwọ́ rẹ̀.+ 23  Ṣe ni èmi yóò tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn ká sáàárín àwọn ilẹ̀.+ 24  Ṣe ni èmi yóò fún apá ọba Bábílónì+ lókun, èmi yóò sì fi idà sí ọwọ́ rẹ̀,+ èmi yóò sì ṣẹ́ apá Fáráò, àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti gbọgbẹ́ ikú, òun yóò kérora kíkankíkan níwájú rẹ̀ dájúdájú.+ 25  Ṣe ni èmi yóò fún apá ọba Bábílónì lókun, apá Fáráò pàápàá yóò sì bọ́; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá fi idà mi sí ọwọ́ ọba Bábílónì, tí òun yóò sì nà án jáde ní tòótọ́ sí ilẹ̀ Íjíbítì.+ 26  Dájúdájú, èmi yóò tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ èmi yóò sì fọ́n wọn ká sáàárín àwọn ilẹ̀; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé