Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 3:1-27

3  Ó sì tẹ̀ síwájú láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ohun tí o rí, jẹ ẹ́. Jẹ àkájọ ìwé yìí,+ sì lọ, bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”  Nítorí náà, mo la ẹnu mi, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sì mú mi jẹ àkájọ ìwé yìí.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, mú kí ikùn rẹ jẹ ẹ́, kí o lè fi àkájọ ìwé yìí tí mo ń fi fún ọ kún ìfun rẹ.” Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́, ó sì wá dà bí oyin ní ẹnu mi ní dídùn.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ, wọ àárín ilé+ Ísírẹ́lì, sì fi ọ̀rọ̀ mi bá wọn sọ̀rọ̀.  Nítorí kì í ṣe àwọn ènìyàn tí èdè+ wọn kò yéni tàbí tí ahọ́n wọn wúwo+ ni a rán ọ sí—sí ilé Ísírẹ́lì,  kì í ṣe sí àwọn ènìyàn tí wọ́n pọ̀ níye, tí èdè wọn kò yéni tàbí tí ahọ́n wọn wúwo, ọ̀rọ̀ àwọn tí ìwọ kò lè gbọ́ ní àgbọ́yé.+ Bí ó bá jẹ́ àwọn ni mo rán ọ sí, àwọn wọ̀nyẹn yóò fetí sí ọ.+  Ṣùgbọ́n ní ti ilé Ísírẹ́lì, wọn kì yóò fẹ́ láti fetí sí ọ, nítorí wọn kò fẹ́ láti fetí sí mi;+ nítorí pé gbogbo ilé Ísírẹ́lì jẹ́ kìígbọ́-kìígbà àti ọlọ́kàn-líle.+  Wò ó! Mo ti mú kí ojú rẹ le gan-an bí ojú wọn,+ mo sì mú kí iwájú orí rẹ le gan-an bí iwájú orí wọn.+  Bí dáyámọ́ǹdì, tí ó le ju akọ òkúta lọ,+ ni mo ti ṣe iwájú orí rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fòyà wọn,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú wọn kó ìpayà bá ọ,+ nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé.”+ 10  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ mi tí èmi yóò sọ fún ọ, fi sí ọkàn-àyà rẹ,+ kí o sì fi etí rẹ gbọ́ ọ. 11  Sì lọ, wọ àárín àwọn ìgbèkùn,+ àárín àwọn ọmọ ènìyàn rẹ, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,’ yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọ́n fà sẹ́yìn.”+ 12  Ẹ̀mí sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé mi lọ,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ìró ìrọ́gìrì ńláǹlà+ lẹ́yìn mi pé: “Ìbùkún ni fún ògo Jèhófà láti àyè rẹ̀.”+ 13  Ìró ìyẹ́ apá àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n ń fi ara kan ara wọn tímọ́tímọ́+ sì wà, àti ìró àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn pẹ́kípẹ́kí,+ àti ìró ìrọ́gìrì ńláǹlà. 14  Ẹ̀mí náà sì gbé mi lọ,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú mi lọ, tí mo fi lọ pẹ̀lú ìhónú nínú ẹ̀mí mi lọ́nà kíkorò, ọwọ́ Jèhófà sì le lára mi.+ 15  Bẹ́ẹ̀ ni mo wọ àárín àwọn ìgbèkùn ní Tẹli-ábíbù, tí wọ́n ń gbé+ lẹ́bàá Odò Kébárì,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbi tí wọ́n ń gbé; mo sì gbé níbẹ̀ fún ọjọ́ méje, tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu ní àárín wọn.+ 16  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin ọjọ́ méje pé ọ̀rọ̀ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá, pé: 17  “Ọmọ ènìyàn, olùṣọ́ ni mo fi ọ́ ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,+ kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu mi, kí o sì kìlọ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ mi.+ 18  Nígbà tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Dájúdájú ìwọ yóò kú,’+ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún un ní tòótọ́, kí o sì sọ̀rọ̀ láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kí ó kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ láti pa a mọ́ láàyè,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni burúkú, yóò kú nínú ìṣìnà rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè padà ní ọwọ́ rẹ.+ 19  Ṣùgbọ́n ní ti ìwọ, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o ti kìlọ̀ fún ẹni burúkú+ tí òun ní tòótọ́ kò sì yí padà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ̀ àti kúrò nínú ọ̀nà burúkú rẹ̀, òun gan-an yóò kú nítorí ìṣìnà rẹ̀;+ ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ yóò ti dá ọkàn rẹ nídè.+ 20  Nígbà tí ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo bá sì yí padà kúrò nínú òdodo rẹ̀,+ tí òun sì ṣe àìṣèdájọ́ òdodo ní tòótọ́, tí èmi sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀,+ òun gan-an yóò kú nítorí pé ìwọ kò kìlọ̀ fún un. Òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ ìṣe òdodo tí ó ti ṣe ni a kì yóò sì rántí,+ ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè padà ní ọwọ́ rẹ.+ 21  Ní ti ìwọ, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olódodo pé kí olódodo má ṣe dẹ́ṣẹ̀,+ tí òun kò sì dẹ́ṣẹ̀ ní tòótọ́, òun, láìkùnà, yóò máa wà láàyè nìṣó nítorí pé a ti kìlọ̀ fún un,+ ìwọ alára yóò ti dá ọkàn rẹ nídè.”+ 22  Ọwọ́ Jèhófà sì wà lára mi níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Dìde, jáde lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì,+ ibẹ̀ ni èmi yóò sì ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 23  Bẹ́ẹ̀ ni mo dìde, mo sì jáde lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, sì wò ó! ògo Jèhófà dúró sí ibẹ̀,+ bí ògo tí mo rí lẹ́bàá Odò Kébárì,+ mo sì dojú bolẹ̀.+ 24  Nígbà náà ni ẹ̀mí wọ inú mi,+ ó sì mú mi dìde dúró lórí ẹsẹ̀ mi,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé: “Wá, ti ara rẹ mọ́ inú ilé rẹ. 25  Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, wò ó! wọn yóò fi okùn lé ọ lára dájúdájú, wọn yóò sì fi wọ́n dè ọ́ tí ìwọ kì yóò fi lè jáde lọ sí àárín wọn.+ 26  Ahọ́n rẹ pàápàá ni èmi yóò mú kí ó lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ,+ dájúdájú, ìwọ yóò sì yadi,+ ìwọ kì yóò sì jẹ́ ọkùnrin tí ń fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà fún wọn,+ nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀+ ilé. 27  Nígbà tí mo bá sì bá ọ sọ̀rọ̀, èmi yóò la ẹnu rẹ, kí o sì sọ fún wọn pé,+ ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’ Kí ẹni tí yóò bá gbọ́, gbọ́,+ kí ẹni tí yóò bá fà sẹ́yìn sì fà sẹ́yìn, nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé