Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 29:1-21

29  Ní ọdún kẹwàá, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kejìlá oṣù náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ Fáráò ọba Íjíbítì,+ kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí i àti lòdì sí Íjíbítì látòkè délẹ̀.+  Sọ̀rọ̀, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò dojú ìjà kọ ọ́, ìwọ Fáráò, ọba Íjíbítì,+ ẹran ńlá abàmì inú òkun+ tí ó nà gbalaja ní àárín àwọn ipa odò Náílì rẹ̀,+ tí ó wí pé, ‘Odò Náílì mi jẹ́ tèmi, èmi—èmi ni ó ṣe é fún ara mi.’+  Ṣe ni èmi yóò fi ìwọ̀ sí páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ,+ èmi yóò sì jẹ́ kí ẹja àwọn ipa odò Náílì rẹ lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ. Ṣe ni èmi yóò sì mú ọ gòkè kúrò ní àárín àwọn ipa odò Náílì rẹ àti gbogbo ẹja àwọn ipa odò Náílì rẹ tí ó lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ.  Dájúdájú, èmi yóò pa ọ́ tì sí aginjù, ìwọ àti gbogbo ẹja ipa odò Náílì rẹ.+ Orí pápá ni ìwọ yóò ṣubú sí.+ A kì yóò ṣà ọ́ jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò kó ọ jọpọ̀. Ṣe ni èmi yóò fi ọ́ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko ẹhànnà ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run.+  Gbogbo àwọn olùgbé Íjíbítì yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nítorí ìdí náà pé wọ́n jẹ́, bí ìtìlẹyìn, ọ̀pá esùsú fún ilé Ísírẹ́lì.+  Nígbà tí wọ́n fi ọwọ́ dì ọ́ mú, ìwọ fọ́,+ ó sì mú kí gbogbo èjìká wọn ya. Nígbà tí wọ́n sì gbé ara wọn lé ọ, ìwọ ṣẹ́,+ ìwọ sì mú kí gbogbo ìgbáròkó wọn yẹ̀.”+  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú idà wá sórí rẹ,+ ṣe ni èmi yóò ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀+ kúrò nínú rẹ.  Ilẹ̀ Íjíbítì yóò sì di ahoro àti ibi ìparundahoro;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nítorí ìdí náà pé ó wí pé, ‘Odò Náílì jẹ́ tèmi, èmi alára ni ó sì ṣe é.’+ 10  Nítorí náà, kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ́, èmi sì dojú ìjà kọ àwọn ipa odò Náílì rẹ,+ dájúdájú, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ Íjíbítì di ibi ìparundahoro, ibi gbígbẹ, ahoro,+ láti Mígídólì+ dé Síénè+ àti títí dé ààlà Etiópíà. 11  Ẹsẹ̀ ará ayé kì yóò gbà á kọjá,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ ẹran agbéléjẹ̀ kì yóò gbà á kọjá,+ a kì yóò gbé inú rẹ̀ fún ogójì ọdún.+ 12  Ṣe ni èmi yóò sọ ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro ní àárín àwọn ilẹ̀ tí ó ti di ahoro;+ àwọn ìlú ńlá rẹ̀ yóò sì di ahoro fún ogójì ọdún ní àárín àwọn ìlú ńlá tí a pa run di ahoro;+ ṣe ni èmi yóò tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn ká sáàárín àwọn ilẹ̀.”+ 13  “‘Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ní òpin ogójì ọdún,+ èmi yóò kó àwọn ará Íjíbítì jọpọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn tí a tú wọn ká sí,+ 14  dájúdájú, èmi yóò mú àwùjọ òǹdè ará Íjíbítì padà wá; èmi yóò sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ sí ilẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò sì ti di ìjọba rírẹlẹ̀. 15  Òun yóò sì di ìjọba rírẹlẹ̀ ju àwọn yòókù lọ, òun kì yóò sì gbé ara rẹ̀ sókè mọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,+ èmi yóò sì mú kí wọ́n kéré níye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò ní lè máa jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.+ 16  Òun kì yóò sì jẹ́ ìgbọ́kànlé+ ilé Ísírẹ́lì mọ́, ní mímú ìṣìnà wá sí ìrántí nípa títọ̀ wọ́n lẹ́yìn.+ Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’” 17  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé: 18  “Ọmọ ènìyàn, Nebukadirésárì fúnra rẹ̀,+ ọba Bábílónì, mú ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ńláǹlà kan lòdì sí Tírè.+ Gbogbo orí ni a mú pá, gbogbo èjìká sì di èyí tí a mú bó.+ Ṣùgbọ́n ní ti owó ọ̀yà,+ kò sí ìkankan fún un àti fún ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ láti ọwọ́ Tírè, fún iṣẹ́ ìsìn tí ó ti ṣe lòdì sí i. 19  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ilẹ̀ Íjíbítì fún Nebukadirésárì ọba Bábílónì,+ òun yóò sì kó ọlà rẹ̀ lọ, yóò sì kó ohun ìfiṣèjẹ ńlá láti ara rẹ̀,+ yóò sì piyẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; èyí yóò sì di owó ọ̀yà fún ẹgbẹ́ ológun rẹ̀.’ 20  “‘Gẹ́gẹ́ bí àsanfidípò fún un nítorí iṣẹ́ ìsìn tí ó ṣe lòdì sí i, mo ti fún un ní ilẹ̀ Íjíbítì, nítorí pé wọ́n gbé ìgbésẹ̀ fún mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 21  “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò mú kí ìwo kan rú jáde fún ilé Ísírẹ́lì,+ èmi yóò sì fún ọ ní àǹfààní láti la ẹnu ní àárín wọn;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé