Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 28:1-26

28  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ fún aṣáájú Tírè pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “‘“Nítorí ìdí náà pé ọkàn-àyà rẹ di onírera,+ ìwọ sì ń wí ṣáá pé, ‘Èmi jẹ́ ọlọ́run kan.+ Ìjókòó ọlọ́run ni mo jókòó sí,+ ní àárín òkun gbalasa,’+ nígbà tí ó jẹ́ pé ará ayé ni ọ́,+ ìwọ kì í sì í ṣe ọlọ́run,+ ìwọ sì ń ṣe ọkàn-àyà rẹ bí ọkàn-àyà ọlọ́run—  wò ó! ìwọ gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ.+ Kò sí àṣírí tí ó ré kọjá agbára rẹ.+  Nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ àti nípasẹ̀ ìfòyemọ̀ rẹ, ìwọ ti ṣe ọlà fún ara rẹ, o sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ ṣáá sínú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ.+  Nípa ọ̀pọ̀ yanturu ọgbọ́n rẹ,+ nípa àwọn ẹrù títà rẹ,+ ìwọ ti mú ọlà rẹ pọ̀ gidigidi,+ ọkàn-àyà rẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìrera nítorí ọlà rẹ.”’+  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Nítorí ìdí náà pé ìwọ ṣe ọkàn-àyà rẹ bí ọkàn-àyà ọlọ́run,+  nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò mú àwọn àjèjì wá bá ọ,+ àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti àwọn orílẹ̀-èdè,+ ṣe ni wọn yóò sì fa idà wọn yọ sí ẹwà ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì sọ ìdángbinrin rẹ di aláìmọ́.+  Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò,+ ìwọ yóò sì kú ikú ẹni tí a pa ní àárín òkun gbalasa.+  Ìwọ yóò ha wí láìkùnà pé, ‘Èmi jẹ́ ọlọ́run,’ níwájú ẹni tí yóò pa ọ́,+ nígbà tí ó jẹ́ pé ará ayé lásán-làsàn ni ọ́, ìwọ kì í sì í ṣe ọlọ́run,+ ní ọwọ́ àwọn tí ń sọ ọ́ di aláìmọ́?”’ 10  “‘Ikú àwọn aláìdádọ̀dọ́ ni ìwọ yóò kú ní ọwọ́ àwọn àjèjì,+ nítorí èmi alára ti sọ ọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 11  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 12  “Ọmọ ènìyàn, gbé ohùn orin arò sókè nípa ọba Tírè,+ kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ  wí: “‘“Ìwọ ń fi èdìdì di àwòṣe kan, tí ó kún fún ọgbọ́n,+ tí ó sì pé ní ẹwà.+ 13  Ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run, ni ìwọ wà.+ Gbogbo òkúta iyebíye ni ìbora rẹ, rúbì, tópásì àti jásípérì; kírísóláítì, ónísì+ àti jéèdì; sàfáyà, tọ́kọ́ásì+ àti émírádì; wúrà sì ni a fi ṣe iṣẹ́ ọnà ojú ibi ìlẹ̀mọ́ rẹ àti ojúhò rẹ nínú rẹ. Ní ọjọ́ tí a dá ọ, a pèsè wọn. 14  Ìwọ ni kérúbù tí a fòróró yàn tí ó bò, mo sì ti gbé ọ kalẹ̀. Orí òkè ńlá mímọ́ Ọlọ́run ni ìwọ wà.+ Ní àárín òkúta oníná ni ìwọ ti ń rìn káàkiri. 15  Ìwọ jẹ́ aláìní-àléébù ní àwọn ọ̀nà rẹ láti ọjọ́ tí a ti dá ọ+ títí a fi rí àìṣòdodo nínú rẹ.+ 16  “‘“Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹrù títà rẹ,+ wọ́n fi ìwà ipá kún àárín rẹ, ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bí aláìbọ̀wọ̀ fún ohun mímọ́, èmi yóò mú ọ kúrò ní òkè ńlá Ọlọ́run, èmi yóò sì pa ọ́ run,+ ìwọ kérúbù tí ó bò, kúrò ní àárín àwọn òkúta oníná. 17  “‘“Ọkàn-àyà rẹ di onírera nítorí ẹwà rẹ.+ Ìwọ run ọgbọ́n rẹ ní tìtorí ìdángbinrin rẹ.+ Dájúdájú, orí ilẹ̀ ni èmi yóò sọ ọ́ sí.+ Ṣe ni èmi yóò gbé ọ kalẹ̀ níwájú àwọn ọba, kí wọ́n lè máa wò ọ́.+ 18  “‘“Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣìnà rẹ,+ nítorí àìṣèdájọ́ òdodo nípa àwọn ẹrù títà rẹ,+ ìwọ ti sọ àwọn ibùjọsìn rẹ di aláìmọ́. Èmi yóò mú iná jáde wá láti àárín rẹ. Òun ni yóò jẹ ọ́ run.+ Èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tí yóò rí ọ.+ 19  Ní ti gbogbo àwọn tí ó mọ̀ ọ́ láàárín àwọn ènìyàn, dájúdájú, wọn yóò máa wò ọ́ sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì.+ Ìwọ yóò sì di ìpayà òjijì, ìwọ kì yóò sì sí mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”’”+ 20  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 21  “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ Sídónì,+ kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí i. 22  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ́,+ ìwọ Sídónì, a ó sì yìn mí lógo ní àárín rẹ+ dájúdájú; àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mó bá mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́+ ṣẹ ní kíkún nínú rẹ̀, tí a sì sọ mí di mímọ́ nínú rẹ̀.+ 23  Ṣe ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀ àrùn sínú rẹ̀, èmi yóò sì rán ẹ̀jẹ̀ sí àwọn ojú pópó rẹ̀.+ Ẹni tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀ nípa idà tí ó dojú kọ ọ́ ní ìhà gbogbo;+ àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 24  Kì yóò sì sí ohun ṣóńṣó afòòró-ẹ̀mí+ fún ilé Ísírẹ́lì tàbí ẹ̀gún ríronilára láti inú gbogbo àwọn tí ó wà yí wọn ká, àwọn tí ń pẹ̀gàn wọn; àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’ 25  “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Nígbà tí mo bá kó ilé Ísírẹ́lì jọpọ̀ láti àárín àwọn ènìyàn tí a tú wọn ká sí,+ ṣe ni a ó sọ mí di mímọ́ ní àárín wọn pẹ̀lú ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Ó sì dájú pé wọn yóò sì máa gbé lórí ilẹ̀+ tí mo fi fún ìránṣẹ́ mi, fún Jékọ́bù.+ 26  Dájúdájú, wọn yóò sì máa gbé lórí rẹ̀ ní ààbò,+ wọn yóò sì kọ́ àwọn ilé,+ wọn yóò sì gbin àwọn ọgbà àjàrà,+ wọn yóò sì máa gbé ní ààbò+ nígbà tí mo bá mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí gbogbo àwọn tí ń pẹ̀gàn wọn ní gbogbo àyíká wọn;+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé