Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 27:1-36

27  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, gbé ohùn orin arò sókè nípa Tírè,+  kí o sì wí fún Tírè pé, “‘Ìwọ tí ń gbé ní àwọn ẹnu ọ̀nà òkun,+ ìwọ obìnrin oníṣòwò ti àwọn ènìyàn fún ọ̀pọ̀ erékùṣù,+ èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ìwọ Tírè, ìwọ alára wí pé, ‘Mo pé ní ẹwà fífanimọ́ra.’+  Àárín òkun ni àwọn ìpínlẹ̀ rẹ wà.+ Àwọn tí ó tẹ̀ ọ́ dó ti sọ ẹwà fífanimọ́ra rẹ di pípé.+  Lára àwọn gẹdú júnípà tí ó wá láti Sénírì+ ni wọ́n fi bá ọ kan gbogbo pátákó. Kédárì kan láti Lẹ́bánónì+ ni wọ́n mú láti fi ṣe òpó ìgbòkun sórí rẹ.  Lára àwọn igi ràgàjì tí ó wá láti Báṣánì ni wọ́n fi gbẹ́ àwọn àjẹ̀ rẹ. Wọ́n fi eyín erin ṣe iwájú ọkọ̀ rẹ pẹ̀lú apákó sípírẹ́sì, láti àwọn erékùṣù Kítímù.+  Aṣọ ọ̀gbọ̀ ní onírúurú àwọ̀ láti Íjíbítì+ ni aṣọ fífẹ̀ rẹ jẹ́, kí ó lè máa jẹ́ ìgbòkun rẹ. Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù+ àti irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró,+ tí ó wá láti àwọn erékùṣù Élíṣáhì,+ ni ohun tí a fi bo òkè ọkọ̀ rẹ.  “‘“Àwọn olùgbé Sídónì+ àti ti Áfádì+ di atukọ̀ fún ọ. Àwọn ọ̀jáfáfá+ rẹ wà nínú rẹ, ìwọ Tírè; àwọn ni òṣìṣẹ́ ọkọ̀ rẹ.+  Àní àwọn àgbà ọkùnrin Gébálì+ àti àwọn ọ̀jáfáfá rẹ̀ wà nínú rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń dí ìkò ọkọ̀ rẹ.+ Gbogbo ọkọ̀ òkun àti àwọn atukọ̀ wọn pàápàá wà nínú rẹ, kí wọ́n bàa lè ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ẹrù ọjà. 10  Àwọn ará Páṣíà+ àti Lúdímù+ àti àwọn ènìyàn Pútì+—wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ológun rẹ, àwọn ọkùnrin ogun rẹ. Apata àti àṣíborí ni wọ́n gbé kọ́ sínú rẹ.+ Àwọn ni ó jẹ́ kí o ní ọlá ńlá. 11  Àwọn ọmọ Áfádì,+ àní ẹgbẹ́ ológun rẹ, wà lórí ògiri rẹ yí ká, ògbójú sì ni àwọn tí ó wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ. Wọ́n gbé àwọn apata wọn bìrìkìtì kọ́ sára ògiri rẹ yí ká.+ Àwọn alára ni ó sọ ẹwà fífanimọ́ra rẹ di pípé. 12  “‘“Táṣíṣì+ ni olówò rẹ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu gbogbo onírúurú ohun tí ó níye lórí.+ Fàdákà rẹ̀, irin, tánganran àti òjé, ni a fi àwọn nǹkan tí o tọ́jú pa mọ́ gbà.+ 13  Jáfánì,+ Túbálì+ àti Méṣékì+ alára ni àwọn oníṣòwò rẹ. Àwọn ọkàn aráyé+ àti àwọn ohun èlò bàbà ni a fi àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ gbà. 14  Láti ilé Tógámà+ ni àwọn ẹṣin àti àwọn ẹṣin ogun àti àwọn ìbaaka ti wá, àwọn tí a fi àwọn nǹkan tí o tọ́jú pamọ́ gbà. 15  Àwọn ọmọ Dédánì+ ni oníṣòwò rẹ; ọ̀pọ̀ erékùṣù ni àwọn olówò tí ń ṣiṣẹ́ fún ọ; àwọn ìwo eyín erin+ àti igi ẹ́bónì ni wọ́n fi san án padà fún ọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. 16  Édómù ni olówò rẹ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ rẹ. Òkúta tọ́kọ́ásì,+ irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró àti aṣọ onírúurú àwọ̀ àti aṣọ híhun àtàtà àti iyùn àti òkúta rúbì, ni a fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí o tọ́jú pamọ́. 17  “‘“Júdà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì alára ni àwọn oníṣòwò rẹ. Àlìkámà+ ti Mínítì+ àti àkànṣe èlò oúnjẹ àti oyin+ àti òróró básámù,+ ni a fi àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ gbà.+ 18  “‘“Damásíkù+ ni olówò rẹ nínú ọ̀pọ̀ yanturu iṣẹ́ rẹ, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu gbogbo nǹkan rẹ tí ó níye lórí, pẹ̀lú wáìnì+ Hélíbónì àti irun àgùntàn aláwọ̀ eérú àdàpọ̀-mọ́-pupa. 19  Fédánì àti Jáfánì láti Úsálì—ni wọ́n fi àwọn nǹkan tí o tọ́jú pamọ́ gbà. Iṣẹ́ ọnà tí a fi irin ṣe, igi kasíà àti ewéko onípòròpórò+—àwọn ni a fi àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ gbà. 20  Dédánì+ ni oníṣòwò rẹ nínú ẹ̀wù tí a hun fún gígẹṣin. 21  Àwọn Árábù+ àti gbogbo ìjòyè Kídárì+ pàápàá ni olówò tí ń ṣiṣẹ́ fún ọ. Nínú akọ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn àgbò àti àwọn òbúkọ+—nínú wọn ni wọ́n jẹ́ olówò rẹ. 22  Àwọn oníṣòwò Ṣébà+ àti Ráámà+ pàápàá ni àwọn oníṣòwò rẹ; gbogbo onírúurú lọ́fínńdà tí ó dára jù lọ àti gbogbo onírúurú òkúta iyebíye àti wúrà, ni a fi àwọn nǹkan tí o tọ́jú pa mọ́ gbà.+ 23  Háránì+ àti Kánè àti Édẹ́nì,+ àwọn oníṣòwò Ṣébà,+ Áṣúrì+ àti Kílímádì ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24  Àwọn ni oníṣòwò rẹ nínú ẹ̀wù mèremère, nínú àwọn aṣọ ìlékè ti aṣọ aláwọ̀ búlúù àti aṣọ onírúurú àwọ̀ àti kápẹ́ẹ̀tì tí ó jẹ́ ẹ̀yà aláwọ̀ méjì, nínú ìjàrá ẹlẹ́lọ̀ọ́ tí a ṣe ní líle pọ́nkí, nínú ibùdó ìṣòwò rẹ. 25  “‘“Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ ni ọ̀wọ́ èrò rẹ fún àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ, tí o fi kún fọ́fọ́, tí o sì di ológo gidigidi ní àárín òkun gbalasa.+ 26  “‘“Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú alagbalúgbú omi.+ Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn ti ṣẹ́ ọ ní àárín òkun gbalasa.+ 27  Àwọn nǹkan rẹ tí ó níye lórí àti àwọn nǹkan tí o tọ́jú pa mọ́,+ àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ,+ àwọn atukọ̀-òkun rẹ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ rẹ,+ àwọn tí ń dí ìkò ọkọ̀ rẹ+ àti àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ẹrù ọjà rẹ àti gbogbo ọkùnrin ogun rẹ,+ tí wọ́n wà nínú rẹ àti nínú gbogbo ìjọ rẹ, tí wọ́n wà ní àárín rẹ,—wọn yóò já sáàárín òkun gbalasa ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.+ 28  “‘“Ilẹ̀ gbalasa yóò mì jìgìjìgì nígbà ìró igbe ẹkún àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ rẹ.+ 29  Gbogbo àwọn tí ń lò àjẹ̀, àwọn atukọ̀-òkun, gbogbo òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun, yóò sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ òkun wọn dájúdájú; wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.+ 30  Nítorí rẹ, wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ wọn dájúdájú nípa ohùn wọn, wọn yóò sì ké jáde lọ́nà kíkorò.+ Wọn yóò sì da ekuru sórí ara wọn.+ Inú eérú ni wọn yóò ti máa yíràá.+ 31  Ṣe ni wọn yóò sọ ara wọn di apárí nípasẹ̀ ìpárí fún ọ,+ wọn yóò sán aṣọ àpò ìdọ̀họ,+ wọn yóò sì sunkún fún ọ nínú ìkorò ọkàn,+ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún kíkorò. 32  Nínú ìdárò wọn, ṣe ni wọn yóò gbé ohùn orin arò sókè fún ọ, wọn yóò sì sun rárà nítorí rẹ+ pé, “‘“‘Ta ní dà bí Tírè,+ tí ó dà bí ẹni tí a pa lẹ́nu mọ́ ní àárín òkun?+ 33  Nígbà tí àwọn nǹkan tí o tọ́jú pa mọ́+ jáde kúrò nínú òkun gbalasa,+ ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́rùn.+ Ìwọ fi ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan rẹ tí ó níye lórí àti àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ sọ àwọn ọba ilẹ̀ ayé di ọlọ́rọ̀.+ 34  Wàyí o, òkun gbalasa ti ṣẹ́ ọ, nínú ibú omi.+ Ní ti àwọn ohun àfiṣe-pàṣípààrọ̀ rẹ àti gbogbo ìjọ rẹ,+ wọ́n ti ṣubú ní àárín rẹ. 35  Gbogbo olùgbé àwọn erékùṣù+—dájúdájú, pẹ̀lú kàyéfì ni wọn yóò wò ọ́ sùn-ùn, ṣe ni àwọn ọba wọn pàápàá yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì nínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀.+ Àwọn ojú yóò kan gbínríngbínrín.+ 36  Ní ti àwọn olówò láàárín àwọn ènìyàn, ṣe ni wọn yóò súfèé nítorí rẹ.+ Ìwọ yóò sì di ìpayà òjijì, ìwọ kì yóò sì sí mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.’”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé