Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 26:1-21

26  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kọkànlá, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, nítorí ìdí náà pé Tírè+ ti wí lòdì sí Jerúsálẹ́mù+ pé, ‘Àháà! A ti ṣẹ́ ẹ,+ ilẹ̀kùn àwọn ènìyàn!+ Dàjúdájú, ọ̀dọ̀ mi ni a ó tẹ̀ sí. A óò kún inú mi—a ti pa á run di ahoro,’+  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ́, ìwọ Tírè, ṣe ni èmi yóò sì gbé orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí òkun tí ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde.+  Dájúdájú, wọn yóò run ògiri Tírè,+ wọn yóò sì ya àwọn ilé gogoro rẹ̀ lulẹ̀,+ ṣe ni èmi yóò ha ekuru rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di àpáta gàǹgà dídán borokoto.  Ilẹ̀ àgbàlá tí a ń sá àwọ̀n ńlá+ sí ni òun yóò dà láàárín òkun.’+ “‘Nítorí èmi alára ti sọ ọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘òun yóò sì di ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè piyẹ́.  Àwọn àrọko rẹ̀ tí ó wà nínú pápá—nípa idà ni a ó pa wọ́n, àwọn ènìyàn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú Nebukadirésárì ọba Bábílónì wá gbéjà ko Tírè láti àríwá,+ ọba àwọn ọba,+ tòun ti àwọn ẹṣin+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ àti àwọn agẹṣinjagun àti ìjọ kan,+ àní ògìdìgbó ènìyàn.  Àwọn àrọko rẹ tí ó wà nínú pápá ni òun yóò fi idà pa, òun yóò sì mọ odi ìsàgatì tì ọ́, yóò sì yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì+ tì ọ́, yóò sì gbé apata ńlá sókè sí ọ;  òun yóò sì dojú ìkọlù ẹ̀rọ ìgbéjàkoni rẹ̀ kọ àwọn ògiri rẹ, àwọn ilé gogoro rẹ ni òun yóò sì bì wó, ní lílo àwọn idà rẹ̀. 10  Nítorí ìrọ́sókè sódò àgbájọ ẹṣin rẹ̀, ekuru wọn yóò bò ọ́.+ Nítorí ìró agẹṣinjagun àti àgbá kẹ̀kẹ́ àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun, àwọn ògiri rẹ yóò mì jìgìjìgì, nígbà tí ó bá gba àwọn ẹnubodè rẹ wọlé, bí ẹni wọ ìlú ńlá tí a ṣí sílẹ̀ nípasẹ̀ àlàfo. 11  Pátákò àwọn ẹṣin rẹ̀ ni òun yóò fi tẹ gbogbo ojú pópó rẹ+ mọ́lẹ̀. Òun yóò sì fi idà pàápàá pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọwọ̀n okun rẹ yóò wọlẹ̀. 12  Dájúdájú, wọn yóò sì fi àwọn ohun àmúṣọrọ̀+ rẹ ṣe ìjẹ, wọn yóò sì piyẹ́ àwọn ẹrù títà+ rẹ, wọn yóò sì ya àwọn ògiri rẹ lulẹ̀, àwọn ilé rẹ fífanimọ́ra ni wọn yóò sì bì wó. Wọn yóò sì kó òkúta rẹ àti iṣẹ́ àfigiṣe rẹ àti ekuru rẹ sí àárín omi.’ 13  “‘Ṣe ni èmi yóò mú kí ariwo orin rẹ kásẹ̀ nílẹ̀,+ àní ìró àwọn háàpù rẹ ni a kì yóò gbọ́ mọ́.+ 14  Ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di àpáta gàǹgà+ dídán borokoto. Ilẹ̀ àgbàlá tí a ń sá àwọ̀n ńlá sí ni ìwọ yóò dà.+ A kì yóò tún ọ kọ́ láé; nítorí èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+ 15  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún Tírè, ‘Nígbà ìró ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí ó gbọgbẹ́ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú bá kérora, nígbà tí ìpani ní àpalù bá ṣẹlẹ̀ láàárín rẹ, àwọn erékùṣù kì yóò ha mì jìgìjìgì?+ 16  Dájúdájú, gbogbo ìjòyè òkun yóò sọ̀ kalẹ̀+ láti orí ìtẹ́ wọn,+ wọn yóò sì bọ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn tí kò lápá, wọn yóò sì bọ́ ẹ̀wù wọn tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára. Wọn yóò gbé ìwárìrì wọ̀. Wọn yóò jókòó sórí ilẹ̀,+ wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìṣẹ́jú,+ wọn yóò sì máa wò ọ́ sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì. 17  Wọn yóò sì gbé orin arò+ dìde nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “‘“Wo bí o ti ṣègbé, ìwọ tí a ń gbé inú rẹ̀ láti òkun,+ ìwọ ìlú ńlá ìyìn, tí ó di alágbára nínú òkun,+ òun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀, àwọn tí ó fi ìpayà wọn sára gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé! 18  Wàyí o, àwọn erékùṣù yóò wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ. A ó yọ àwọn erékùṣù tí ń bẹ́ nínú òkun lẹ́nu nítorí jíjáde lọ rẹ.”’+ 19  “Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ńlá tí a pa run di ahoro, bí àwọn ìlú ńlá tí a kò gbé ní ti tòótọ́, nígbà tí mo bá mú ibú omi wá sórí rẹ, tí alagbalúgbú omi yóò ti bò ọ́.+ 20  Ṣe ni èmi yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ èmi yóò sì mú kí o wà ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ jù lọ,+ bí àwọn ibi tí a pa run di ahoro tipẹ́tipẹ́, pẹ̀lú àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò,+ kí a má bàa gbé inú rẹ; ṣe ni èmi yóò sì gbé ìṣelóge sí ilẹ̀ àwọn alààyè.+ 21  “‘Èmi yóò sọ ọ́ di ìpayà òjijì,+ ìwọ kì yóò sì sí; a óò wá ọ,+ ṣùgbọ́n a kì yóò rí ọ mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé