Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 25:1-17

25  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, gbé ojú rẹ síhà ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn.+  Kí o sì sọ nípa àwọn ọmọ Ámónì pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Nítorí ìdí náà pé ìwọ sọ pé Àháà! sí ibùjọsìn mi, nítorí pé a ti sọ ọ́ di aláìmọ́, àti sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí a ti sọ ọ́ di ahoro, àti sí ilé Júdà, nítorí wọ́n ti lọ sí ìgbèkùn,+  nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò fi ọ́ fún àwọn Ará Ìlà-Oòrùn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní,+ wọn yóò sì kọ́ àwọn ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká sí inú rẹ, wọn yóò sì kọ́ àwọn àgọ́ wọn sí inú rẹ dájúdájú. Àwọn alára yóò jẹ èso rẹ, àwọn alára yóò sì mu wàrà rẹ.+  Ṣe ni èmi yóò sọ Rábà+ di ilẹ̀ ìjẹko fún àwọn ràkúnmí, èmi yóò sì sọ àwọn ọmọ Ámónì di ibi ìsinmi agbo ẹran;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé ìwọ pàtẹ́wọ́,+ tí ìwọ sì fẹsẹ̀ kilẹ̀, tí o sì ń yọ̀ ṣáá pẹ̀lú gbogbo ìpẹ̀gàn rẹ nínú ọkàn rẹ lòdì sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+  nítorí náà, èmi rèé; mo ti na ọwọ́ mi lòdì sí ọ,+ ṣe ni èmi yóò fi ọ́ fúnni gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò piyẹ́; èmi yóò sì ké ọ kúrò láàárín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì pa ọ́ run kúrò lórí àwọn ilẹ̀.+ Èmi yóò pa ọ́ rẹ́ ráúráú,+ ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé Móábù+ àti Séírì+ wí pé: “Wò ó! Ilé Júdà dà bí gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù,”+  nítorí náà, èmi yóò ṣí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Móábù ní àwọn ìlú ńlá náà, ní àwọn ìlú ńlá rẹ̀ dé ààlà ilẹ̀ rẹ̀, ìṣelóge ilẹ̀ náà, Bẹti-jẹ́ṣímótì,+ Baali-méónì,+ àní dé Kíríátáímù,+ 10  dé ọ̀dọ̀ àwọn Ará Ìlà-Oòrùn,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ámónì;+ ṣe ni èmi yóò sọ ọ́ di ohun ìní, kí a má bàa rántí rẹ̀,+ èyíinì ni àwọn ọmọ Ámónì, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. 11  Èmi yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́+ ṣẹ ní kíkún nínú Móábù; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+ 12  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé Édómù gbé ìgbésẹ̀ ní gbígbẹ̀san lára ilé Júdà, wọ́n sì ń ṣe àìtọ́ lọ́nà tí ó bùáyà, wọ́n sì gbẹ̀san ara wọn lára wọn,+ 13  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Dájúdájú, èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí Édómù,+ èmi yóò sì ké ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀+ kúrò nínú rẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ibi ìparundahoro láti Témánì,+ àní dé Dédánì.+ Nípa idà ni wọn yóò ṣubú. 14  ‘Ṣe ni èmi yóò mú ẹ̀san mi wá sórí Édómù nípa ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì;+ wọn yóò sì ṣe ní Édómù gẹ́gẹ́ bí ìbínú mi àti gẹ́gẹ́ bí ìhónú mi; wọn yóò sì ní láti mọ ohun tí ẹ̀san mi jẹ́,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’ 15  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé àwọn Filísínì ti gbé ìgbésẹ̀ ìgbẹ̀san,+ wọ́n sì ń fi ẹ̀san pẹ̀lú ìpẹ̀gàn nínú ọkàn gbẹ̀san ara wọn, kí wọ́n lè fa ìparun,+ pẹ̀lú ìṣọ̀tá tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ 16  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kìyè sí i, èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí àwọn Filísínì,+ ṣe ni èmi yóò ké àwọn Kérétì kúrò,+ èmi yóò sì pa ìyókù etí òkun run.+ 17  Dájúdájú, èmi yóò sì mú ìgbẹ̀san ńláǹlà ṣẹ ní kíkún nínú wọn, pẹ̀lú ìbáwí àfitọ́nisọ́nà tí ó kún fún ìhónú,+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá mú ẹ̀san mi wá sórí wọn.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé