Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 24:1-27

24  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá ní ọdún kẹsàn-án, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, pé:  “Ọmọ ènìyàn, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀ fún ara rẹ, ọjọ́ òní yìí gan-an. Ọba Bábílónì rọ́ lu Jerúsálẹ́mù ní òní yìí gan-an.+  Sọ ọ̀rọ̀ òwe nípa ọlọ̀tẹ̀ ilé náà,+ kí o sì sọ nípa wọn pé, “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Gbé ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀ kaná; gbé e kaná, sì da omi sínú rẹ̀ pẹ̀lú.+  Kó ègé jọ sínú rẹ̀,+ gbogbo ègé tí ó dára, itan àti èjìká; àní kí o fi àwọn egungun ààyò jù lọ kún inú rẹ̀.  Kí mímú àgùntàn ààyò jù lọ+ ṣẹlẹ̀, kí o sì to ìtì igi jọ ní òbìrìkìtì sábẹ́ rẹ̀. Bọ àwọn ègé rẹ̀, kí o se àwọn egungun rẹ̀ pẹ̀lú ní àárín rẹ̀.”’”+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ègbé ni fún ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀,+ ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀, tí ìpẹtà rẹ̀ wà nínú rẹ̀, èyí tí ìpẹtà rẹ̀ gan-an kò sì kúrò nínú rẹ̀! Ní ègé, ègé rẹ̀, kí o mú un jáde;+ a kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kèké lé e lórí.+  Nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gan-an wà ní àárín rẹ̀ gan-gan.+ Orí àpáta gàǹgà dídán borokoto ni ó gbé e sí. Kò dà á sórí ilẹ̀, láti fi ekuru bò ó.+  Láti gbé ìhónú dìde fún mímú ìgbẹ̀san ṣẹ ní kíkún,+ mo ti gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí àpáta gàǹgà dídán borokoto, kí a má bàa bò ó mọ́lẹ̀.’+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ègbé ni fún ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀!+ Èmi alára yóò mú kí ìtòjọpelemọ náà di ńlá.+ 10  Sọ ìtì igi di púpọ̀. Mú iná jó. Bọ ẹran náà dáadáa. Da omitoro nù, sì jẹ́ kí àwọn egungun náà di gbígbóná bí ajere. 11  Gbé e ka orí ẹyín iná rẹ̀ lófìfo kí ó bàa lè gbóná; kí bàbà rẹ̀ sì gbóná, kí ohun àìmọ́ rẹ̀ sì yọ́ ní àárín rẹ̀.+ Kí ìpẹtà rẹ̀ di èyí tí a jẹ run.+ 12  Ìdààmú! Ó ti mú kí ó rẹni, ṣùgbọ́n ìpẹtà rẹ̀ tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kò kúrò nínú rẹ̀.+ Tòun ti ìpẹtà rẹ̀, ó di inú iná!’ 13  “‘Ìwà àìníjàánu wà nínú ìwà àìmọ́ rẹ.+ Nítorí ìdí náà ni ó fi di dandan fún mi láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ́ kúrò nínú ìwà àìmọ́ rẹ.+ Ìwọ kì yóò mọ́ títí èmi yóò fi mú ìhónú mi wá sinmi nínú ọ̀ràn rẹ.+ 14  Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ̀rọ̀.+ Yóò dé,+ ṣe ni èmi yóò gbé ìgbésẹ̀. Èmi kì yóò ṣàìnáání,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò káàánú+ tàbí kẹ́dùn.+ Dájúdájú, wọn yóò ṣe ìdájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ àti ìbálò rẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 15  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 16  “Ọmọ ènìyàn, kíyè sí i, èmi yóò mú ohun tí ó fani mọ́ra+ lójú rẹ lọ nípa ìyọnu àgbálù,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ lu igẹ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sunkún tàbí kí o yọ omijé lójú.+ 17  Mí ìmí ẹ̀dùn láìsọ̀rọ̀. Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣọ̀fọ̀ àwọn òkú.+ Fi ìwérí rẹ wé orí rẹ,+ kí o sì wọ sálúbàtà rẹ sí ẹsẹ̀ rẹ.+ Kí o má ṣe bo túbọ̀mu rẹ,+ kí o má sì jẹ oúnjẹ ènìyàn.”+ 18  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, aya mi kú ní alẹ́. Nítorí náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi ni mo ṣe ní òwúrọ̀. 19  Àwọn ènìyàn náà sì ń wí fún mi pé: “Ìwọ kì yóò ha sọ fún wa bí nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe ṣe kàn wá?”+ 20  Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà gan-an ni ó tọ̀ mí wá, pé, 21  ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, ibùjọsìn mi,+ tí í ṣe ìyangàn okun yín,+ ni èmi yóò sọ di aláìmọ́, ohun tí ó fani mọ́ra lójú yín+ àti ohun tí ọkàn yín yọ́nú sí, àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín tí ẹ fi sílẹ̀ sẹ́yìn—nípa idà ni wọn yóò ṣubú.+ 22  Ẹ ó sì ní láti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe. Ẹ kì yóò bo túbọ̀mu,+ ẹ kì yóò sì jẹ oúnjẹ ènìyàn.+ 23  Ìwérí yín yóò sì wà ní orí yín, sálúbàtà yín yóò sì wà ní ẹsẹ̀ yín. Ẹ kì yóò lu ara yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò sunkún,+ ẹ ó sì jẹrà dànù nínú ìṣìnà yín,+ ẹ ó sì kérora ní ti gidi láàárín ara yín.+ 24  Ìsíkíẹ́lì sì ti di àmì àgbàyanu fún yín.+ Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ti ṣe, ni ẹ̀yin yóò ṣe. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀,+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”’”+ 25  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé ní ọjọ́ tí èmi yóò kó odi agbára wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ohun lílẹ́wà ti ayọ̀ ńláǹlà wọn, àwọn ohun fífanimọ́ra lójú wọn+ àti ìyánhànhàn ọkàn wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn,+ 26  ní ọjọ́ yẹn, olùsálà yóò wá sọ́dọ̀ rẹ fún mímú kí etí gbọ́?+ 27  Ní ọjọ́ yẹn, ẹnu rẹ yóò là fún olùsálà,+ ìwọ yóò sì sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́;+ ṣe ni ìwọ yóò sì di àmì àgbàyanu fún wọn,+ wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé