Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 23:1-49

23  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá,+ pé:  “Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì, ọmọbìnrin ìyá kan náà wà.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara wọn ṣe iṣẹ́ kárùwà ní Íjíbítì.+ Ní ìgbà èwe wọn, wọ́n ṣe iṣẹ́ kárùwà.+ Ibẹ̀ ni a ti tẹ ọmú wọn,+ ibẹ̀ ni a sì ti rin oókan àyà ipò wúńdíá wọn mọ́lẹ̀.  Orúkọ wọn sì ni Òhólà èyí ẹ̀gbọ́n àti Òhólíbà arábìnrin rẹ̀, wọ́n sì wá di tèmi,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.+ Ní ti orúkọ wọn, Òhólà ni Samáríà,+ Òhólíbà sì ni Jerúsálẹ́mù.+  “Òhólà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ kárùwà,+ nígbà tí ó ṣì wà lábẹ́ ìdarí mi, tí ó sì ń ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìgbónára,+ sí àwọn ará Ásíríà,+ tí wọ́n wà nítòsí,  àwọn gómìnà tí ó wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù, àti àwọn ajẹ́lẹ̀—àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ó fani lọ́kàn mọ́ra, gbogbo wọn pátá, àwọn agẹṣinjagun tí ń gun ẹṣin.  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe iṣẹ́ kárùwà rẹ̀ lára wọn, àwọn ọmọ Ásíríà tí ó jẹ́ ààyò jù lọ, gbogbo wọn pátá; àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí—pẹ̀lú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn—ó sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin.+  Iṣẹ́ kárùwà rẹ̀ tí ó gbé wá láti Íjíbítì ni kò fi sílẹ̀, nítorí wọ́n sùn tì í ní ìgbà èwe rẹ̀, àwọn ni wọ́n sì rin oókan àyà ipò wúńdíá rẹ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì ń bá a lọ ní dída ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe wọn sórí rẹ̀.+  Nítorí náà, mo fí i lé ọwọ́ àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìgbónára,+ lé ọwọ́ àwọn ọmọ Ásíríà, àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí.+ 10  Àwọn ni wọ́n tú ìhòòhò rẹ̀ síta.+ Wọ́n kó àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀,+ àní wọ́n fi idà pa òun náà. Ó sì wá di orúkọ ìtìjú fún àwọn obìnrin, wọ́n sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí rẹ̀. 11  “Nígbà tí Òhólíbà arábìnrin rẹ̀ rí i,+ ó wá lo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ ń pani run ju tirẹ̀ lọ, iṣẹ́ kárùwà rẹ̀ sì ju àgbèrè ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin lọ.+ 12  Nítorí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn ọmọ Ásíríà,+ àwọn gómìnà àti àwọn ajẹ́lẹ̀ tí wọ́n wà nítòsí, tí wọ́n wọ aṣọ alárà gígọntíọ, àwọn agẹṣinjagun tí ń gun ẹṣin—àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ó fani lọ́kàn mọ́ra, gbogbo wọn pátá.+ 13  Mo sì rí i pé, nítorí tí o ti sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, àwọn méjèèjì ní ọ̀nà kan náà.+ 14  Ó sì ń fi kún ìṣe kárùwà rẹ̀, nígbà tí ó bá rí àwọn ọkùnrin tí a gbẹ́ sára ògiri,+ àwọn ère+ ará Kálídíà tí a gbẹ́, tí a sì kùn ní àwọ̀ pupa fòò,+ 15  tí a fi ìgbànú+ di ìgbáròkó wọn lámùrè, láwàní onídogbodógbó wà lórí wọn, wọ́n ní ìrísí jagunjagun, gbogbo wọn pátá, bí ìrí àwọn ọmọkùnrin Bábílónì, àwọn ará Kálídíà ní ti ilẹ̀ ìbí wọn. 16  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn ní gbàrà tí ojú rẹ̀ rí+ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rán ońṣẹ́ sí wọn ní Kálídíà.+ 17  Àwọn ọmọkùnrin Bábílónì sì ń wọlé tọ̀ ọ́ wá, sí ibùsùn ìfìfẹ́hàn, wọ́n sì ń fi ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe wọn sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin;+ òun sì ń bá a lọ ní dídi ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ wọn, ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí nínú ìríra kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. 18  “Ó sì ń bá a lọ ní títú ìṣe kárùwà rẹ̀ síta, ó sì ń tú ìhòòhò rẹ̀ síta,+ tí ọkàn mi fi tìtorí ìríra ṣí kúrò nínú ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkàn mi ṣe tìtorí ìríra ṣí kúrò nínú ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀.+ 19  Ó sì ń sọ ìṣe kárùwà+ rẹ̀ di púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rántí ọjọ́ èwe rẹ̀,+ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ kárùwà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 20  Ó sì ń ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́nà ti àwọn wáhàrì tí ó jẹ́ ti àwọn tí ẹ̀yà ara wọn rí bí ẹ̀yà ara akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí ẹ̀yà ara ìbímọ wọn sì rí bí ẹ̀yà ara ìbímọ akọ ẹṣin.+ 21  Ìwọ sì ń bá a lọ ní pípe àfiyèsí sí ìwà àìníjàánu ìgbà èwe rẹ nípa rírin tí a rin oókan àyà rẹ mọ́lẹ̀ láti Íjíbítì+ lọ, nítorí ọmú ìgbà èwe rẹ.+ 22  “Nítorí náà, ìwọ Òhólíbà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò gbé àwọn olùfẹ́ rẹ onígbòónára dìde sí ọ,+ àwọn tí ọkàn rẹ tìtorí ìríra ṣí kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni èmi yóò sì mú wọn wọlé lòdì sí ọ ní ìhà gbogbo,+ 23  àwọn ọmọkùnrin Bábílónì+ àti gbogbo ará Kálídíà,+ Pékódù+ àti Ṣóà àti Kóà, gbogbo àwọn ọmọkùnrin Ásíríà pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ó fani mọ́ra, àwọn gómìnà àti àwọn ajẹ́lẹ̀, gbogbo wọn pátá, àwọn jagunjagun àti àwọn tí a ń fi ọlá àṣẹ pè, tí ń gun ẹṣin, gbogbo wọn pátá. 24  Wọn yóò sì wọlé wá gbéjà kò ọ́ pẹ̀lú dídún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́,+ àti pẹ̀lú ìjọ àwọn ènìyàn, pẹ̀lú apata ńlá àti asà àti àṣíborí. Wọn yóò dojú kọ ọ́ yí ká, ṣe ni èmi yóò sì fi ìdájọ́ fún wọn, wọn yóò sì fi àwọn ìdájọ́ wọn ṣe ìdájọ́ rẹ.+ 25  Ṣe ni èmi yóò fi ìgbóná-ọkàn mi hàn sí ọ,+ wọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ọ nínú ìhónú.+ Wọn yóò mú imú rẹ àti etí rẹ kúrò, àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú rẹ yóò ṣubú, àní nípa idà. Wọn yóò kó+ àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ,+ a ó sì fi iná jẹ àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú rẹ run.+ 26  Wọn yóò bọ́ ẹ̀wù rẹ+ kúrò dájúdájú, wọn yóò sì kó ohun èlò ẹlẹ́wà rẹ lọ.+ 27  Èmi yóò sì mú kí ìwà àìníjàánu rẹ kásẹ̀ nílẹ̀ kúrò nínú rẹ+ ní ti tòótọ́, àti iṣẹ́ kárùwà rẹ tí o gbé wá láti ilẹ̀ Íjíbítì;+ ìwọ kì yóò gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ wọn, ìwọ kì yóò sì rántí Íjíbítì mọ́.’ 28  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o kórìíra, lé ọwọ́ àwọn tí ọkàn rẹ fi tìtorí ìríra ṣí kúrò lọ́dọ̀ wọn.+ 29  Wọn yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí ọ nínú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo àmújáde làálàá rẹ lọ, wọn yóò sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ìhòòhò goloto;+ a ó sì tú ìhòòhò goloto ìwà àgbèrè rẹ síta àti ìwà àìníjàánu rẹ àti ìṣe kárùwà rẹ.+ 30  Ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí sí ọ yóò sì ṣẹlẹ̀ nítorí títọ̀ tí o ń tọ àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn bí kárùwà,+ ní tìtorí òtítọ́ náà pé o fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn sọ ara rẹ di ẹlẹ́gbin.+ 31  Ìwọ ti rìn ní ọ̀nà arábìnrin rẹ;+ èmi yóò sì fi ife rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.’+ 32  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ìwọ yóò mu ife arábìnrin rẹ, èyí tí ó jinnú, tí ó sì fẹ̀.+ Ìwọ yóò di ohun ìfirẹ́rìn-ín àti ìfiṣẹ̀sín, ife tí ó gba ohun púpọ̀.+ 33  A ó fi ìmutípara àti ẹ̀dùn-ọkàn kún ọ, pẹ̀lú ife ìyàlẹ́nu tí ó peléke àti ti ahoro, ife Samáríà arábìnrin rẹ. 34  Ṣe ni ìwọ yóò mu ún, ìwọ yóò sì fà á gbẹ,+ ìwọ yóò sì gé àpáàdì rẹ̀ jẹ, ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ já.+ “Nítorí èmi alára ti sọ ọ́,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’ 35  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé ìwọ ti gbàgbé mi,+ o sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé mi jù sẹ́yìn rẹ,+ nígbà náà, kí ìwọ fúnra rẹ pẹ̀lú ru ìwà àìníjàánu rẹ àti ìṣe kárùwà rẹ.’” 36  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́+ Òhólà àti Òhólíbà,+ kí ó sì sọ àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn fún wọn?+ 37  Nítorí wọ́n ti ṣe panṣágà,+ ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn,+ wọ́n sì bá àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn ṣe panṣágà.+ Àti ní àfikún sí ìyẹn, àwọn ọmọ wọn tí wọ́n bí fún mi ni wọ́n mú la iná kọjá fún wọn gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ.+ 38  Ju èyí lọ, ohun tí wọ́n ṣe sí mi nìyí: Wọ́n ti sọ ibùjọsìn+ mi di ẹlẹ́gbin+ ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì ti sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́.+ 39  Nígbà tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn fún àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn,+ àní wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá sínú ibùjọsìn mi ní ọjọ́ yẹn láti sọ ọ́ di aláìmọ́,+ sì wò ó! ìyẹn ni ohun tí wọ́n ti ṣe ní àárín ilé mi.+ 40  Ní àfikún sí ìyẹn, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí ń bọ̀ láti ibi jíjìnnà réré, àwọn tí a rán ońṣẹ́ sí,+ sì wò ó! wọ́n dé,+ àwọn tí ìwọ tìtorí wọn wẹ ara rẹ,+ tí o tọ́ ojú rẹ,+ tí o sì fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.+ 41  Ìwọ sì jókòó lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú ológo,+ pẹ̀lú tábìlì tí a ṣètò síwájú rẹ̀,+ o gbé tùràrí+ mi àti òróró mi sórí rẹ̀.+ 42  Ìró ogunlọ́gọ̀ tí ó wà ní ìdẹ̀rùn sì wà nínú rẹ̀,+ àwọn ọ̀mùtípara wà+ tí a mú láti aginjù wá bá àwọn ènìyàn inú àgbájọ aráyé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn júfù sí ọwọ́ àwọn obìnrin àti adé ẹlẹ́wà sí orí wọn.+ 43  “Nígbà náà ni mo wí nípa ẹni tí panṣágà ti mú kí ó gbó+ pé, ‘Wàyí o, òun yóò máa bá ṣíṣe iṣẹ́ kárùwà rẹ̀ nìṣó, àní òun alára.’+ 44  Wọ́n sì ń wọlé tọ̀ ọ́ wá ṣáá, gan-an bí ẹní wọlé tọ obìnrin tí ó jẹ́ kárùwà; ní irú ọ̀nà yẹn ni wọ́n wọlé tọ Òhólà àti Òhólíbà bí àwọn obìnrin oníwà àìníjàánu.+ 45  Ṣùgbọ́n ní ti àwọn olódodo,+ àwọn ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ panṣágà obìnrin+ àti pẹ̀lú ìdájọ́ àwọn olùta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ tí ó jẹ́ obìnrin;+ nítorí panṣágà obìnrin ni wọ́n, ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.+ 46  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Gbígbé ìjọ dìde dojú kọ wọ́n+ àti sísọ wọ́n di ohun tí ń da jìnnìjìnnì boni àti ohun ìpiyẹ́+ yóò ṣẹlẹ̀. 47  Ìjọ yóò sì sọ wọ́n ní òkúta,+ fífi idà wọn ké wọn lulẹ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀. Wọn yóò sì pa àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn,+ a ó sì fi iná sun ilé wọn.+ 48  Dájúdájú, èmi yóò sì mú kí ìwà àìníjàánu+ kásẹ̀ nílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ gbogbo àwọn obìnrin yóò sì gba ìtọ́sọ́nà, kí wọ́n má bàa ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà àìníjàánu yín.+ 49  Wọn yóò sì mú ìwà àìníjàánu yín wá sórí yín,+ ẹ ó sì ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé