Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 22:1-31

22  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́,+ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ ìlú ńlá ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀,+ kí o sì jẹ́ kí ó mọ gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ̀?+  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ìwọ ìlú ńlá tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀+ ní àárín rẹ̀ títí àkókò rẹ̀ yóò fi dé,+ tí ó sì ti ṣe àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ láàárín ara rẹ̀ láti di aláìmọ́,+  nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ tí o ti ta sílẹ̀ ni ìwọ fi jẹ̀bi,+ nípa àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ rẹ tí o ṣe ni o fi di aláìmọ́.+ Ìwọ sì mú ọjọ́ rẹ sún mọ́ tòsí, ìwọ yóò sì wá sí ọdún rẹ. Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi sọ ọ́ di ohun ẹ̀gàn sí àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ìfiṣeyẹ̀yẹ́ sí ilẹ̀ gbogbo.+  Àwọn ilẹ̀ tí ó wà nítòsí àti àwọn tí ó jìnnà réré sí ọ yóò fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ aláìmọ́ ní orúkọ, tí ó kún fún ìdàrúdàpọ̀ púpọ̀.+  Wò ó! Àwọn ìjòyè+ Ísírẹ́lì ti wà nínú rẹ, olúkúlùkù fi ara rẹ̀ fún apá rẹ̀ fún ète títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+  Wọ́n ti fojú tín-ín-rín baba àti ìyá nínú rẹ.+ Wọ́n ti lu àtìpó ní jìbìtì ní àárín rẹ.+ Wọ́n ṣe ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó níkà nínú rẹ.”’”+  “‘Ìwọ tẹ́ńbẹ́lú àwọn ibi mímọ́ mi, ìwọ sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́.+  Àwọn afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ paraku wà nínú rẹ, fún ète títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀;+ wọ́n ti jẹun lórí àwọn òkè ńlá nínú rẹ.+ Wọ́n ń bá a lọ ní híhu ìwà àìníjàánu ní àárín rẹ.+ 10  Wọ́n ti tú ìhòòhò baba síta nínú rẹ;+ wọ́n tẹ́ obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́ nínú nǹkan oṣù rẹ̀ lógo nínú rẹ.+ 11  Ọkùnrin kan ti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí pẹ̀lú aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+ ọkùnrin kan sì ti fi ìwà àìníjàánu sọ aya ọmọ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin;+ ọkùnrin kan sì ti tẹ́ arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀, lógo nínú rẹ.+ 12  Wọ́n ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nínú rẹ fún ète títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ìwọ ti gba èlé+ àti ẹ̀dá owó,+ ìwọ sì ń fi jìbìtì+ jèrè+ lára alábàákẹ́gbẹ́ rẹ lọ́nà ìwà ipá, ìwọ sì ti gbàgbé mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 13  “‘Sì wò ó! mo ti lu ọwọ́ mi+ sí èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu tí o ti jẹ,+ àti sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ó wà ní àárín rẹ.+ 14  Ọkàn-àyà rẹ yóò ha fara dà á+ tàbí ọwọ́ rẹ yóò ha mú okun wá ní ọjọ́ tí èmi yóò gbé ìgbésẹ̀ sí ọ?+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́, èmi yóò sì gbé ìgbésẹ̀.+ 15  Ṣe ni èmi yóò tú ọ ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n ọ ká sí àwọn ilẹ̀,+ èmi yóò sì pa ohun àìmọ́ rẹ run kúrò nínú rẹ.+ 16  Dájúdájú, a ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ láàárín ìwọ alára, lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+ 17  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 18  “Ọmọ ènìyàn, lójú tèmi àwọn ti ilé Ísírẹ́lì ti di ìdàrọ́.+ Gbogbo wọn jẹ́ bàbà àti tánganran àti irin àti òjé ní àárín ìléru. Ìdàrọ́ púpọ̀, ti fàdákà ni wọ́n dà.+ 19  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé gbogbo yín ti di ìdàrọ́,+ nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò kó yín jọpọ̀ sí àárín Jerúsálẹ́mù.+ 20  Bí ti kíkó fàdákà àti bàbà àti irin+ àti òjé àti tánganran jọ sí àárín ìléru, láti fẹ́+ iná sórí rẹ̀ láti mú kí ó yọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó wọn jọpọ̀ nínú ìbínú mi àti nínú ìhónú mi, ṣe ni èmi yóò fẹ́ ẹ, èmi yóò sì mú kí ẹ yọ́. 21  Dájúdájú, èmi yóò sì kó yín jọpọ̀, èmi yóò sì fẹ́ iná ìbínú mi kíkan+ sórí yín, a ó sì mú kí ẹ yọ́ ní àárín rẹ̀.+ 22  Bí ti yíyọ́ fàdákà ní àárín ìléru, bẹ́ẹ̀ ni a óò yọ́ yín ní àárín rẹ̀; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ti da ìhónú mi sórí yín.’”+ 23  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 24  “Ọmọ ènìyàn, sọ́ fún un pé, ‘Ilẹ̀ tí a kò fọ̀ mọ́ ni ọ́, èyí tí òjò kò rọ̀ sí ní ọjọ́ ìdálẹ́bi.+ 25  Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun àwọn wòlíì rẹ̀ wà ní àárín rẹ̀,+ bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, tí ó ń fa ẹran ọdẹ ya.+ Ọkàn ni wọ́n ń jẹ run+ ní ti tòótọ́. Ìṣúra àti ohun ṣíṣeyebíye ni wọ́n ń gbà.+ Wọ́n ti sọ àwọn opó rẹ̀ di púpọ̀ ní àárín rẹ̀.+ 26  Àwọn àlùfáà rẹ̀ pàápàá ṣe ohun àìtọ́ sí òfin mi,+ wọ́n sì ń sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́.+ Wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàárín+ ohun mímọ́ àti ohun yẹpẹrẹ,+ wọn kò sì sọ ohunkóhun di mímọ̀+ láàárín ohun àìmọ́ àti ohun tí ó mọ́, wọ́n sì ti pa ojú wọn mọ́ kúrò lára àwọn sábáàtì mi,+ a sì sọ mi di aláìmọ́ ní àárín wọn.+ 27  Àwọn ọmọ aládé àárín rẹ̀ dà bí ìkookò tí ń fa ẹran ọdẹ ya ní títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ ní pípa àwọn ọkàn run fún ète jíjẹ èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu.+ 28  Àwọn wòlíì rẹ̀ ti fi ọ̀dà ẹfun+ rẹ́ ẹ fún wọn, wọ́n ń rí ìran ohun tí ó jẹ́ òtúbáńtẹ́,+ wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún wọn,+ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,” nígbà tí Jèhófà alára kò sọ̀rọ̀. 29  Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ń bá ìpètepèrò lílu jìbìtì nìṣó,+ wọ́n sì ń já nǹkan gbà ní jíjanilólè,+ wọ́n sì ṣe àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì níkà,+ wọ́n sì lu àtìpó ní jìbìtì láìsí ìdájọ́ òdodo.’+ 30  “‘Mo sì ń wá ẹnì kan nínú wọn tí yóò máa tún ògiri òkúta+ ṣe, tí yóò sì máa dúró síbi àlàfo+ níwájú mi nítorí ilẹ̀ náà, kí èmi má bàa run ún;+ èmi kò rí ẹnì kankan. 31  Nítorí náà, èmi yóò da ìdálẹ́bi+ tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lé wọn lórí. Èmi yóò fi iná ìbínú mi kíkan pa wọ́n run pátápátá.+ Ṣe ni èmi yóò mú ọ̀nà wọn wá sórí wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé