Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 21:1-32

21  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, gbé ojú rẹ síhà Jerúsálẹ́mù kí o sì rọ̀jò+ ọ̀rọ̀ sí àwọn ibi mímọ́,+ kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+  Kí o sì sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ ọ́,+ ṣe ni èmi yóò mú idà mi jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀,+ èmi yóò sì ké olódodo àti ẹni burúkú kúrò nínú rẹ.+  Kí èmi lè ké olódodo àti ẹni burúkú kúrò nínú rẹ ní ti tòótọ́, nítorí náà, idà mi yóò jáde lọ láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ẹran ara láti gúúsù dé àríwá.+  Gbogbo àwọn ẹlẹ́ran ara yóò sì ní láti mọ̀ pé, èmi tìkára mi, Jèhófà, ti mú idà mi jáde kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀.+ Kì yóò padà mọ́.”’+  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, mí ìmí ẹ̀dùn ti ìwọ ti ìgbáròkó gbígbọ̀n.+ Àní pẹ̀lú ìkorò ni kí o fi mí ìmí ẹ̀dùn lójú wọn.+  Kí ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n bá sọ fún ọ pé, ‘Ní tìtorí ohun wo ni ìwọ ṣe ń mí ìmí ẹ̀dùn?’+ kí o wí pé, ‘Nítorí ìròyìn kan ni.’+ Nítorí yóò dé dájúdájú,+ gbogbo ọkàn-àyà yóò domi,+ gbogbo ọwọ́ yóò sì rọ jọwọrọ, gbogbo ẹ̀mí yóò dorí kodò, gbogbo eékún pàápàá yóò sì máa ro tótó fún omi.+ ‘Wò ó! Yóò dé dájúdájú,+ a ó sì mú kí ó ṣẹlẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Sọ pé, ‘Idà, idà!+ A ti pọ́n ọn,+ a sì ti dán an pẹ̀lú. 10  A ti pọ́n ọn fún ète ṣíṣètò ìfikúpa, a sì ti dán an fún ète dídan yinrinyinrin.’”’”+ “Tàbí ṣé kí a yọ ayọ̀ ńláǹlà?”+ “‘Ṣé ó ń kọ ọ̀pá aládé+ ọmọ mi+ sílẹ̀ ni, bí ó ti ń ṣe sí gbogbo igi?+ 11  “‘Ẹnì kan sì fi fúnni pé kí a dán an, kí a lè fi ọwọ́ lò ó. Èyí—idà—ni a ti pọ́n, a sì ti dán an, kí a lè fi í lé olùpani lọ́wọ́.+ 12  “‘Ké jáde, sì hu,+ ọmọ ènìyàn, nítorí òun alára ti dé láti dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn mi;+ ó dojú ìjà kọ gbogbo ìjòyè Ísírẹ́lì.+ Àwọn tí a fi sọ̀kò lu idà wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi.+ Nítorí náà, lu itan pẹ́pẹ́.+ 13  Nítorí a ti ṣe àyẹ̀wò kan,+ kí sì ni bí ó bá kọ ọ̀pá aládé sílẹ̀ pẹ̀lú?+ Èyí kì yóò máa wà títí lọ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 14  “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn—sọ tẹ́lẹ̀, fi àtẹ́lẹwọ́ lu àtẹ́lẹwọ́,+ kí o sì sọ pé ‘Idà!’ ní ìgbà mẹ́ta.+ Idà àwọn tí a pa ni. Idà ẹni ńlá tí a pa ni, èyí tí ó yí wọn ká.+ 15  Kí ọkàn-àyà bàa lè domi+ àti kí a lè sọ àwọn tí a bì ṣubú ní ẹnubodè+ wọn di púpọ̀, ṣe ni èmi yoo sì fi idà pani. Págà, a ṣe é fún dídán yinrinyinrin, a dán an fún ìfikúpani!+ 16  Fi ara rẹ hàn ní aríran kedere;+ lọ sí apá ọ̀tún! Mú ipò rẹ; lọ sí apá òsì! Sí ibikíbi tí o bá kọ ojú rẹ sí! 17  Èmi alára pẹ̀lú yóò fi àtẹ́lẹwọ́ mi kan lu àtẹ́lẹwọ́ mi kejì,+ dájúdájú, èmi yóò sì mú ìhónú+ mi wá sí ìsinmi.+ Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́.” 18  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 19  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, gbé ọ̀nà méjì kalẹ̀ fún ara rẹ fún idà ọba Bábílónì láti wọlé.+ Láti ilẹ̀ kan ni kí àwọn méjèèjì ti jáde lọ, àmì ìtọ́ka ni kí a ṣe;+ ìkòríta ọ̀nà ìlú ńlá ni kí a ṣe é sí. 20  Kí o gbé ọ̀nà kan kalẹ̀ fún idà náà láti wọlé lòdì sí Rábà+ ti àwọn ọmọkùnrin Ámónì, àti ọ̀kan lòdì sí Júdà, lòdì sí Jerúsálẹ́mù olódi.+ 21  Nítorí ọba Bábílónì dúró jẹ́ẹ́ ní ìkòríta, ní orí ọ̀nà méjì, láti yíjú sí iṣẹ́ wíwò.+ Ó mi àwọn ọfà. Ó fi ère tẹ́ráfímù+ béèrè; ó wo inú ẹ̀dọ̀. 22  Ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ìwoṣẹ́ wà fún Jerúsálẹ́mù, láti fi òlùgbóró+ lélẹ̀, láti la ẹnu ẹni fún pípani, láti gbé ìró sókè nínú àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì,+ láti gbé òlùgbóró ti àwọn ẹnubodè, láti yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì, láti kọ́ odi ìsàgatì.+ 23  Ó sì dà bí ìwoṣẹ́ tí kò jóòótọ́ lójú wọn+—àwọn tí wọ́n ti fi ìbúra búra fún wọn;+ ó sì ń mú ìṣìnà wá sí ìrántí,+ kí a bàa lè mú wọn.+ 24  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí mímú tí ẹ mú kí a rántí ìṣìnà yín nípa títú tí a tú ìrélànàkọjá yín síta, kí a lè rí ẹ̀ṣẹ̀ yín ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìbálò yín, nítorí tí a pè yín wá sí ìrántí,+ àní ọwọ́ ni a o fi gbá yín mú.’+ 25  “Ní ti ìwọ, ìjòyè burúkú+ ti Ísírẹ́lì,+ tí ó ti gbọgbẹ́ ikú, ẹni tí ọjọ́ rẹ̀ dé ní ìgbà ìṣìnà ìkẹyìn,+ 26  èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé+ kúrò. Èyí kì yóò rí bákan náà.+ Gbé ohun tí ó rẹlẹ̀ pàápàá ga,+ kí o sì rẹ ẹni gíga pàápàá wálẹ̀.+ 27  Rírun, rírun, rírun ni èmi yóò run ún.+ Ní ti èyí pẹ̀lú, dájúdájú, kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin+ yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.’+ 28  “Àti ní ti ìwọ, ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí nípa àwọn ọmọ Ámónì àti nípa ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ wọn.’ Kí o sì wí pé, ‘Idà, idà, tí a fà yọ fún ìfikúpani, tí a dán láti mú kí ó jẹni run, kí ó bàa lè máa dán yinrinyinrin,+ 29  nítorí rírí tí wọ́n rí ohun tí ó jẹ́ òtúbáńtẹ́ fún ọ, nítorí wíwò tí wọ́n ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ,+ kí a bàa lè gbé ọ lé ọrùn àwọn tí a pa, àwọn ènìyàn burúkú, àwọn tí ọjọ́ wọ́n dé ní ìgbà ìṣìnà ìkẹyìn.+ 30  Dá a padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Ní ibi tí a ti dá ọ, ní ilẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ,+ ni èmi yóò ti dá ọ lẹ́jọ́. 31  Ṣe ni èmi yóò da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lé ọ lórí.+ Iná ìbínú mi kíkan ni èmi yóò fi fẹ́ atẹ́gùn lù ọ́, èmi yóò sì fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìnírònú, àwọn oníṣẹ́ ọnà ìparun.+ 32  Nítorí ìwọ yóò di ohun tí a fi ń dá iná.+ Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà ní àárín ilẹ̀ náà. A kì yóò rántí rẹ, nítorí èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé