Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 20:1-49

20  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún keje, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, pé àwọn ọkùnrin nínú àwọn àgbàlagbà Ísírẹ́lì wọlé wá láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jókòó níwájú mi.+  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá pé:  “Ọmọ ènìyàn, bá àwọn àgbàlagbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ṣé nítorí àtiwádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe ń bọ̀?+ ‘Bí mo ti ń bẹ láàyè, ọ̀dọ̀ mi kọ́ ni ẹ ó ti ṣe ìwádìí,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’  “Ìwọ yóò ha dá wọn lẹ́jọ́ bí? Ìwọ yóò ha dá wọn lẹ́jọ́, ọmọ ènìyàn?+ Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí àwọn baba ńlá wọn.+  Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì,+ mo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ mi sókè+ pẹ̀lú sí irú-ọmọ ilé Jékọ́bù+ ní ìbúra, mo sì sọ ara mi di mímọ̀ fún wọn ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn ní ìbúra, pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+  Ní ọjọ́ yẹn, mo gbé ọwọ́ mi sókè+ sí wọn ní ìbúra láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ tí mo ti ṣe amí rẹ̀ fún wọn, èyí tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.+ Ìṣelóge ilẹ̀ gbogbo ni.+  Mo sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù yín gbé ohun ìríra ojú rẹ̀ sọnù,+ kí ẹ má sì fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ Íjíbítì sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+  “‘“Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí mi,+ wọn kò sì gbà láti fetí sí mi. Ohun ìríra ojú wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni wọn kò gbé sọnù, wọn kò sì fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ Íjíbítì sílẹ̀,+ tí ó fi jẹ́ pé mo ṣèlérí láti da ìhónú mi lé wọn lórí, láti mú ìbínú mi wá sí ìparí lára wọn ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì.+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi kí a má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè láàárín àwọn tí wọ́n wà,+ nítorí mo ti sọ ara mi di mímọ̀ fún wọn lójú wọn nígbà tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 10  Bẹ́ẹ̀ ni mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo sì mú wọn wá sí aginjù.+ 11  “‘“Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi;+ mo sì sọ àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi di mímọ̀ fún wọn, kí ènìyàn tí ń tẹ̀ lé wọn lè máa wà láàyè nípasẹ̀ wọn pẹ̀lú.+ 12  Àwọn sábáàtì mi ni mo sì fi fún wọn pẹ̀lú,+ láti di àmì láàárín èmí àti àwọn,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà tí ń sọ wọ́n di mímọ́. 13  “‘“Ṣùgbọ́n, ilé Ísírẹ́lì ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi ní aginjù.+ Wọn kò rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi,+ wọ́n sì kọ àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi,+ àwọn tí ó jẹ́ pé bí ènìyàn bá ń pa mọ́, yóò máa wà láàyè nípasẹ̀ wọn.+ Wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ gidigidi,+ tí mo fi ṣèlérí láti da ìbínú mi kíkan lé wọn lórí ní aginjù, kí n lè pa wọ́n run pátápátá.+ 14  Ṣùgbọ́n mo gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi, kí a má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, lójú àwọn ẹni tí mo ti mú wọn jáde.+ 15  Èmi alára sì tún gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn ní ìbúra ní aginjù,+ láti má ṣe mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo ti fi fún wọn, èyí tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ (ìṣelóge ilẹ̀ gbogbo ni,)+ 16  nítorí ìdí náà pé wọ́n kọ àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi; àti ní ti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, wọn kò rìn nínú wọn, àwọn sábáàtì mi ni wọ́n sì sọ di aláìmọ́, nítorí pé àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn ni ọkàn-àyà wọn ń tọ̀ lẹ́yìn.+ 17  “‘“Ojú mi bẹ̀rẹ̀ sí káàánú fún wọn kí èmi má pa wọ́n run,+ èmi kò sì pa wọ́n run pátápátá ní aginjù. 18  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ wọn ní aginjù+ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ rìn nínú ìlànà àwọn baba ńlá yín,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ pa àwọn ìdájọ́ wọn mọ́,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ 19  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Ẹ rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi,+ kí ẹ sì pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́,+ kí ẹ sì tẹ̀ lé wọn.+ 20  Kí ẹ sì sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́,+ kí wọ́n sì jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+ 21  “‘“Àwọn ọmọ sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Wọn kò rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, wọn kò sì pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́ nípa títẹ̀lé wọn, àwọn tí ó jẹ́ pé bí ènìyàn bá ń pa mọ́, yóò máa wà láàyè nípasẹ̀ wọn pẹ̀lú.+ Àwọn sábáàtì mi ni wọ́n sọ di aláìmọ́.+ Nítorí náà, mo ṣèlérí láti da ìhónú mi lé wọn lórí, láti mú ìbínú mi wá sí ìparí lára wọn ní aginjù.+ 22  Mo sì fa ọwọ́ mi sẹ́yìn,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi, pé kí a má bàa sọ ọ́ di aláìmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, lójú àwọn ẹni tí mo ti mú wọn jáde.+ 23  Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi alára gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn ní ìbúra ní aginjù,+ láti tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti láti fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ 24  nítorí ìdí náà pé wọn kò mú àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi ṣe,+ wọ́n sì kọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi,+ wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́,+ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ ti àwọn baba ńlá wọn ni ojú wọn sì ń tọ̀ lẹ́yìn.+ 25  Èmi alára pẹ̀lú yóò sì jẹ́ kí wọ́n ní àwọn ìlànà tí kò dára àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ tí wọn kò lè tipasẹ̀ wọn máa wà láàyè nìṣó.+ 26  Èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ àwọn ẹ̀bùn wọn nígbà tí wọ́n bá mú olúkúlùkù ọmọ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ la iná kọjá,+ kí n lè sọ wọ́n di ahoro, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’+ 27  “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn+ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ọ̀ràn yìí, àwọn baba ńlá yín sọ̀rọ̀ sí mi tèébútèébú, ní fífi tí wọ́n fi àìṣòótọ́ hùwà sí mi.+ 28  Mo sì tẹ̀ síwájú láti mú wọn wá sí ilẹ̀+ tí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn ní ìbúra láti fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè kékeré tí ó ga+ àti gbogbo igi ẹlẹ́ka púpọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ wọn níbẹ̀,+ wọ́n sì ń fi ọrẹ ẹbọ wọn amúnibínú fúnni níbẹ̀, wọ́n sì ń mú òórùn amáratuni wọn wá síbẹ̀,+ wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn jáde níbẹ̀.+ 29  Nítorí náà, mo wí fún wọn pé, ‘Kí ni ibi gíga tí ẹ ń bọ̀ yìí túmọ̀ sí, tí a fi ní láti pe orúkọ rẹ̀ ní Ibi Gíga títí di òní yìí?’”’+ 30  “Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ẹ̀yin ha ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin+ ní ọ̀nà àwọn baba ńlá yín, ẹ ha sì ń tọ ohun ìríra wọn lẹ́yìn nínú ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe?+ 31  Àti ní gbígbé ẹ̀bùn yín sókè nípa mímú àwọn ọmọ yín la iná kọjá,+ ẹ̀yin ha ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin nítorí gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín títí di òní bí?+ Ní àkókò kan náà, ẹ ó ha ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ èmi alára, ilé Ísírẹ́lì?”’+ “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘Ọ̀dọ̀ mi kọ́ ni ẹ ó ti ṣe ìwádìí.+ 32  Èyí tí ó sì ń bọ̀ wá sínú ẹ̀mí+ yín kì yóò ṣẹlẹ̀ rárá,+ ní ti pé ẹ ń wí pé: “Kí a dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí ìdílé àwọn ilẹ̀,+ ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún igi àti òkúta.”’”+ 33  “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘ọwọ́ líle àti apá nínà jáde+ àti ìhónú tí a tú jáde ni èmi yóò fi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí yín.+ 34  Ṣe ni èmi yóò sì mú yín jáde kúrò nínú àwọn ènìyàn, ọwọ́ líle àti apá nínà jáde àti ìhónú tí a tú jáde+ ni èmi yóò sì fi kó yín jọpọ̀ láti àwọn ilẹ̀ tí a tú yín ká sí. 35  Dájúdájú, èmi yóò mú yín wá sí aginjù ti àwọn ènìyàn,+ èmi yóò sì mú ara mi wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú yín níbẹ̀ ní ojúkojú.+ 36  “‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti mú ara mi wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín ní aginjù ilẹ̀ Íjíbítì,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú ara mi wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú yín,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 37  ‘Dájúdájú, èmi yóò mú yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá,+ èmi yóò sì mú yín wọnú ìdè májẹ̀mú.+ 38  Ṣe ni èmi yóò sì gbá àwọn adìtẹ̀ sí mi àti àwọn olùrélànàkọjá+ mọ́ kúrò nínú yín, nítorí láti ilẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣe àtìpó ni èmi yóò ti mú wọn jáde, ṣùgbọ́n wọn kì yóò wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+ 39  “Ẹ̀yin, ilé Ísírẹ́lì, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kí olúkúlùkù yín lọ sin àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ rẹ̀.+ Àti lẹ́yìn náà, tí ẹ kò bá fetí sí mi, ẹ kì yóò fi àwọn ẹ̀bùn yín àti àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ yín sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ mọ́.’ 40  “‘Nítorí ní òkè ńlá mímọ́ mi, ní òkè ńlá ibi gíga Ísírẹ́lì,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘ibẹ̀ ni àwọn, gbogbo àwọn ilé Ísírẹ́lì látòkè délẹ̀, yóò ti sìn mí, ní ilẹ̀ náà.+ Ibẹ̀ ni èmi yóò ti ní ìdùnnú sí wọn, ibẹ̀ sì ni èmi yóò ti béèrè àwọn ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín nínú gbogbo ohun mímọ́ yín.+ 41  Nítorí òórùn amáratuni, èmi yóò ní ìdùnnú sí yín,+ nígbà tí mo bá mú yín jáde kúrò ní àárín àwọn ènìyàn, tí èmi sì kó yín jọpọ̀ ní tòótọ́ láti àwọn ilẹ̀ tí a tú yín ká sí,+ ṣe ni a ó sì sọ mí di mímọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.’+ 42  “‘Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí mo bá mú yín wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ sí ilẹ̀ tí mo gbé ọwọ́ mi sókè ní ìbúra láti fifún àwọn baba ńlá yín. 43  Dájúdájú, ẹ óò rántí ọ̀nà yín+ àti gbogbo ìbálò yín tí ẹ fi sọ ara yín di ẹlẹ́gbin+ níbẹ̀, ní ti tòótọ́ ẹ ó sì kórìíra ojú yín tẹ̀gbintẹ̀gbin nítorí gbogbo ohun búburú yín tí ẹ ti ṣe.+ 44  Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà+ nígbà tí mo bá gbé ìgbésẹ̀ nípa yín nítorí orúkọ mi,+ kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà búburú yín tàbí gẹ́gẹ́ bí ìbálò yín dídíbàjẹ́,+ ìwọ ilé Ísírẹ́lì,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 45  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 46  “Ọmọ ènìyàn, gbé ojú+ rẹ sí ìhà gúúsù, kí o sì rọ̀jò+ ọ̀rọ̀ sí gúúsù, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ fún igbó tí ó wà ní pápá gúúsù. 47  Kí o sì sọ fún igbó gúúsù pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Kíyè sí i, èmi yóò ti iná bọ̀ ọ́,+ yóò sì jẹ gbogbo igi tí ó ṣì ní ọ̀rinrin àti igi gbígbẹ inú rẹ run.+ Ọwọ́ iná tí ń jó ni a kì yóò fẹ́ pa,+ nípasẹ̀ rẹ̀ ni a óò jó gbogbo ojú gbẹ láti gúúsù dé àríwá.+ 48  Gbogbo àwọn ẹlẹ́ran ara yóò sì rí i pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ni ó sọ iná sí i, tí a kì yóò fi fẹ́ ẹ pa.”’”+ 49  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ọ̀rọ̀ òwe ha kọ́ ni ó ń sọ?’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé