Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 2:1-10

2  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn,+ dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ kí n lè bá ọ sọ̀rọ̀.”+  Ẹ̀mí sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ inú mi ní gbàrà tí ó bá mi sọ̀rọ̀,+ ó sì mú mi dìde dúró lórí ẹsẹ̀ mi níkẹyìn, kí n lè gbọ́ Ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.+  Ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò rán ọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Àwọn fúnra wọn àti àwọn baba ńlá wọn ti ré ìlànà mi kọjá títí di òní yìí gan-an.+  Àti àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ aláfojúdi,+ tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́kàn-àyà líle+—èmi yóò rán ọ sí wọn, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’  Àti ní tiwọn, yálà wọn yóò gbọ́+ tàbí wọn yóò fà sẹ́yìn+—nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé+—ó dájú pé wọn yóò mọ̀ pẹ̀lú pé wòlíì kan wà ní àárín wọn.+  “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má fòyà wọn;+ má sì fòyà ọ̀rọ̀ wọn, nítorí àwọn olóríkunkun+ wà àti àwọn ohun tí ń gún ọ,+ àárín àwọn àkekèé+ sì ni ìwọ ń gbé. Má fòyà+ àwọn ọ̀rọ̀ wọn, má sì jẹ́ kí ojú wọn kó ìpayà bá ọ,+ nítorí wọn jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé.+  Kí o sì sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọ́n fà sẹ́yìn, nítorí ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.+  “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ bí ọlọ̀tẹ̀ ilé.+ La ẹnu rẹ, kí o sì jẹ ohun tí èmi yóò fi fún ọ.”+  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wò, sì kíyè sí i! a na ọwọ́ kan sí mi,+ sì wò ó! àkájọ ìwé kan wà nínú rẹ̀.+ 10  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó tẹ́ ẹ síwájú mi, a sì kọ̀wé sí i tojú tẹ̀yìn;+ a sì kọ orin arò àti ìkédàárò àti ìpohùnréré ẹkún sínú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé