Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 19:1-14

19  “Àti ní ti ìwọ, gbé orin arò+ sókè nípa àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì,+  kí o sì wí pé, ‘Kí ni ìyá rẹ? Abo kìnnìún láàárín àwọn kìnnìún.+ Ó dùbúlẹ̀ láàárín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀. Ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.  “‘Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà.+ Ó sì di ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ bí a ṣe ń fa ẹran ọdẹ ya.+ Ó jẹ ará ayé pàápàá run.  Àwọn orílẹ̀-èdè sì ń gbọ́ nípa rẹ̀. A mú un nínú ihò wọn, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fi àwọn ìkọ́ gbé e wá sí ilẹ̀ Íjíbítì.+  “‘Nígbà tí ó rí i pé òun ti dúró, tí ìrètí òun sì ti ṣègbé, nígbà náà, ó mú òmíràn nínú àwọn ọmọ rẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ni ó mú un jáde.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn káàkiri ní àárín àwọn kìnnìún. Ó sì di ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kọ́ bí a ṣe ń fa ẹran ọdẹ ya.+ Ó pa ará ayé pàápàá jẹ.+  Ilé gogoro tí ó ń gbé sì wá di mímọ̀ fún un, ó sì pa àwọn ìlú ńlá wọn pàápàá run di ahoro,+ tí ilẹ̀ náà fi di ahoro, ó sì fi ìró ìkéramúramù rẹ̀ kún inú rẹ̀.+  Gbogbo orílẹ̀-èdè ní gbogbo àyíká láti àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí dojú ìjà kọ ọ́,+ wọ́n sì wá na àwọ̀n wọn bò ó lórí.+ A mú un nínú ihò wọn.+  Níkẹyìn, wọ́n fi àwọn ìkọ́ gbé e sínú àgò, wọ́n sì gbé e wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì.+ Wọ́n fi àwọ̀n ìṣọdẹ gbé e wá, kí a má bàa gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè ńlá Ísírẹ́lì.+ 10  “‘Ìyá rẹ+ dà bí àjàrà kan nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ,+ tí a gbìn sẹ́bàá omi. Ó di èyí tí ń so èso, tí ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀ yanturu omi.+ 11  Wọ́n sì wà fún àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí ó lágbára, tí ó wà fún ọ̀pá aládé àwọn olùṣàkóso.+ Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, gíga rẹ̀ sì yọ sókè ní àárín àwọn ẹ̀ka, a sì rí i, nítorí gíga rẹ̀, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé.+ 12  Ṣùgbọ́n a fà á tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò nínú ìbínú kíkan.+ A gbé e lulẹ̀, ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn sì ń bẹ tí ó gbẹ èso rẹ̀ dànù.+ Ọ̀pá rẹ̀ tí ó lágbára ni a ya kúrò, ó sì gbẹ.+ Iná pàápàá jẹ ẹ́ run.+ 13  Wàyí o, a gbìn ín sí aginjù,+ ní ilẹ̀ aláìlómi àti olóùngbẹ.+ 14  Iná sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá láti inú ọ̀pá rẹ̀.+ Ó jẹ àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ gan-an run, àní èso rẹ̀, kò sì wá sí ọ̀pá tí ó lágbára nínú rẹ̀ mọ́, kò sí ọ̀pá aládé fún ṣíṣàkóso mọ́.+ “‘Orin arò nìyẹn, yóò sì di orin arò.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé