Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 18:1-32

18  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Kí ni ó túmọ̀ sí fún yín pé ẹ ń sọ ọ̀rọ̀ òwe yìí lórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, pé, ‘Àwọn baba ni ó jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan’?+  “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘ẹ̀yin kì yóò máa bá a lọ mọ́ láti máa sọ ọ̀rọ̀ òwe yìí ní Ísírẹ́lì.  Wò ó! Gbogbo ọkàn—tèmi ni wọ́n.+ Bí ọkàn+ baba ti jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkàn ọmọ—tèmi ni wọ́n.+ Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀+—òun gan-an ni yóò kú.+  “‘Àti ní ti ènìyàn kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó jẹ́ olódodo, tí ó sì ti mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo+ ṣẹ ní kíkún;  tí kò jẹun+ ní orí àwọn òkè ńlá,+ tí kò sì gbé ojú rẹ̀ sókè sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ ti ilé Ísírẹ́lì,+ tí kò sì sọ aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin,+ tí kò jẹ́ sún mọ́ obìnrin tí ó wà nínú ohun ìdọ̀tí rẹ̀;+  tí kò jẹ́ ṣe ènìyàn èyíkéyìí níkà;+ ohun ìdógò tí ó gbà fún gbèsè tí a jẹ ẹ́ ni ó ń dá padà;+ tí kò lọ́ ohunkóhun gbà ní jíjanilólè;+ àwọn tí ebi ń pa ni ó ń fi oúnjẹ+ tirẹ̀ fún, àwọn tí ó wà ní ìhòòhò ni ó sì ń da ẹ̀wù bò;+  kì í fi ohunkóhun fúnni ní èlé,+ kì í sì í gba ẹ̀dá owó kankan;+ ó ń fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò nínú àìṣèdájọ́ òdodo;+ ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ni ó ń mú ṣẹ ní kíkún láàárín ènìyàn àti ènìyàn;+  ó ń rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi,+ ó sì ń pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́ láti mú òtítọ́+ ṣẹ ní kíkún, ó jẹ́ olódodo.+ Dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 10  “‘Bí ẹnì kan bá sì bí ọmọ tí ó jẹ́ ọlọ́ṣà,+ olùta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,+ tí ó ti ṣe ohun tí ó dà bí ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí 11  (ṣùgbọ́n tí òun fúnra rẹ̀ kò ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun náà gan-an); bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ti jẹun pẹ̀lú lórí àwọn òkè ńlá,+ tí ó sì ti sọ aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin;+ 12  tí ó ṣe ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì níkà;+ tí ó lọ́ àwọn nǹkan gbà ní jíjanilólè,+ tí kò dá ohun ìdógò padà;+ tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ,+ tí ó ti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+ 13  Ó ti fúnni láti gba ẹ̀dá owó,+ ó sì gba èlé,+ ó dájú pé òun kì yóò máa wà láàyè nìṣó. Gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí ni ó ti ṣe.+ A ó fi ikú pa á dájúdájú. Ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ yóò wà lórí rẹ̀.+ 14  “‘Sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ, tí ó ń rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀ tí ó ti dá, ó rí i, òun kò sì ṣe ohun tí ó dà bí wọn.+ 15  Òun kò jẹun lórí àwọn òkè ńlá, kò gbé ojú sókè sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ ti ilé Ísírẹ́lì;+ kò sọ aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin;+ 16  kò sì ṣe ènìyàn èyíkéyìí níkà,+ kò fi ipá gba ohun ìdógò,+ kò sì kó ohunkóhun ní jíjanilólè;+ àwọn tí ebi ń pa ni ó fi oúnjẹ+ tirẹ̀ fún, ẹni tí ó wà ní ìhòòhò ni ó sì fi ẹ̀wù bò;+ 17  ó ti fa ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lára ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; kò sì gba ẹ̀dá owó+ àti èlé;+ ó mú àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi ṣẹ;+ ó rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi;+ òun alára kì yóò kú nítorí ìṣìnà baba rẹ̀.+ Dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó.+ 18  Ní ti baba rẹ̀, nítorí ó lu jìbìtì lọ́nà tí ó peléke,+ ó lọ́ ohun kan gbà ní jíja arákùnrin lólè,+ tí ó sì ti ṣe ohun yòówù tí kò dára ní àárín àwọn ènìyàn rẹ̀,+ wò ó! nígbà náà, kí ó kú nítorí ìṣìnà rẹ̀.+ 19  “‘Ẹ̀yin yóò sì sọ dájúdájú pé: “Èé ṣe tí ọmọ kò ru ohunkóhun nítorí ìṣìnà baba?”+ Wàyí o, ní ti ọmọ, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ni ó mú ṣẹ ní kíkún,+ gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi ni ó pa mọ́, ó sì ń tẹ̀ lé wọn.+ Dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó.+ 20  Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.+ Ọmọ kì yóò ru ohunkóhun nítorí ìṣìnà baba, baba kì yóò sì ru ohunkóhun nítorí ìṣìnà ọmọ.+ Òdodo olódodo yóò wà lórí rẹ̀,+ ìwà burúkú ẹni burúkú yóò sì wà lórí rẹ̀.+ 21  “‘Wàyí o, ní ti ẹni burúkú, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yí padà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá,+ tí ó sì pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́ ní ti tòótọ́, tí ó sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo+ ṣẹ ní kíkún, dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú.+ 22  Gbogbo ìrélànàkọjá rẹ̀ tí ó ti ṣe—a kì yóò rántí wọn lòdì sí i.+ Nítorí òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe, òun yóò máa wà láàyè nìṣó.’+ 23  “‘Èmi ha ní inú dídùn rárá sí ikú ẹni burúkú,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘bí kò ṣe pé kí ó yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè ní ti tòótọ́?’+ 24  “‘Wàyí o, nígbà tí olódodo bá yí padà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí ó sì ṣe àìṣèdájọ́ òdodo+ ní ti tòótọ́; ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí ẹni burúkú ti ṣe ni ó ń ṣe,+ tí ó sì wà láàyè, kò sí ìkankan nínú gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe tí a óò rántí.+ Nítorí ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti dá, nítorí wọn ni yóò ṣe kú.+ 25  “‘Ẹ̀yin yóò sì sọ dájúdájú pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò gún.”+ Jọ̀wọ́, gbọ́ ilé Ísírẹ́lì. Ṣé ọ̀nà tèmi ni kò gún?+ Ọ̀nà yín ha kọ́ ni kò gún?+ 26  “‘Nígbà tí olódodo bá yí padà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí ó sì ṣe àìṣèdájọ́ òdodo+ ní ti tòótọ́, tí ó sì kú nítorí wọn, nítorí àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe, òun yóò kú.+ 27  “‘Nígbà tí ẹni burúkú bá yí padà kúrò nínú ìwà burúkú rẹ̀ tí ó ti hù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo+ ṣẹ ní kíkún, òun ni ẹni tí yóò pa ọkàn rẹ̀ mọ́ láàyè.+ 28  Nígbà tí ó bá rí i,+ tí ó sì yí padà kúrò nínú gbogbo ìrélànàkọjá rẹ̀ tí ó ti ṣe,+ dájúdájú, òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú.+ 29  “‘Ilé Ísírẹ́lì yóò sì sọ dájúdájú pé: “Ọ̀nà Jèhófà kò gún.”+ Ní ti àwọn ọ̀nà mi, wọn kò ha gún, ilé Ísírẹ́lì?+ Kì í ha ṣe àwọn ọ̀nà tiyín ni kò gún?’+ 30  “‘Nítorí náà, bí àwọn ọ̀nà olúkúlùkù ti rí, bẹ́ẹ̀ ní èmi yóò ṣe ṣe ìdájọ́ yín,+ ilé Ísírẹ́lì,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+ ‘Ẹ yí padà, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ mú ìyípadà bá gbogbo ìrélànàkọjá yín,+ ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ tí ń fa ìṣìnà fún yín.+ 31  Ẹ mú gbogbo ìrélànàkọjá yín kúrò lọ́dọ̀ yín, nínú èyí tí ẹ ti ré ìlànà kọjá,+ kí ẹ sì ṣe ọkàn-àyà tuntun+ àti ẹ̀mí tuntun+ fún ara yín, nítorí èé ṣe tí ẹ ó fi kú,+ ilé Ísírẹ́lì?’ 32  “‘Nítorí èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni tí ń kú lọ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. ‘Nítorí náà, ẹ ṣe ìyípadà, kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé