Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 17:1-24

17  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, pa àlọ́,+ kí o sì sọ ọ̀rọ̀ òwe sí ilé Ísírẹ́lì.+  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Idì ńlá,+ tí ó ní ìyẹ́ apá ńlá,+ pẹ̀lú ìyẹ́ àfifò gígùn, tí ó kún fún ìyẹ́-òun-ìhùùhù, tí ó ní onírúurú àwọ̀, wá sí Lẹ́bánónì,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mú téńté orí+ igi kédárì.+  Ó já orí ọ̀jẹ̀lẹ́ rẹ̀ gan-gan, ó sì mú un wá sí ilẹ̀ Kénáánì;+ ó sì fi í sínú ìlú ńlá àwọn oníṣòwò.  Síwájú sí i, ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà,+ ó sì fi í sínú pápá fún irúgbìn. Gẹ́gẹ́ bí igi wílò lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi,+ bí igi wílò ni ó gbé e kalẹ̀.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rú jáde, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di àjàrà tí ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ tí kò ga,+ tí ó tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé sínú; ní ti gbòǹgbò rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n wá wà lábẹ́ rẹ̀. Ó sì di àjàrà níkẹyìn, ó sì yọ ọ̀mùnú, ó sì yọ àwọn ẹ̀ka jáde.+  “‘“Idì ńlá+ mìíràn sì wá wà, tí ó ní ìyẹ́ apá ńlá, tí ó sì ní ìyẹ́ àfifò ńlá,+ sì wò ó! àjàrà yìí na gbòǹgbò rẹ̀ tebitebi sọ́dọ̀ rẹ̀.+ Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé ni ó nà jáde sí i kí ó lè bomi rin in, ní jíjìnnà sí ebè títẹ́ inú ọ̀gbà tí a gbìn ín sí.+  Inú pápá tí ó dára, lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi, ni a gbé e lọ gbìn sí,+ kí ó lè mú ẹ̀tun jáde, kí ó sì lè so èso, kí ó di àjàrà ọlọ́lá ọba.”’  “Sọ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Yóò ha ní àṣeyọrí sí rere bí?+ Ẹnì kan kì yóò ha fa gbòǹgbò+ rẹ̀ gan-an ya, kí ó sì mú èso rẹ̀ gan-an di onípẹ̀ẹ́? Gbogbo èéhù rẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ já kì yóò ha di gbígbẹ?+ Yóò di gbígbẹ. Kì í ṣe nípa apá ńlá tàbí nípa ògìdìgbó ènìyàn ni a ó fi gbé e sókè láti gbòǹgbò rẹ̀. 10  Sì wò ó! bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbé e lọ gbìn, yóò ha ní àṣeyọrí sí rere bí? Kì yóò ha gbẹ pátápátá, àní bí ìgbà tí ọwọ́ ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn bá bà á?+ Nínú ebè títẹ́ inú ọgbà tí ìrújáde rẹ̀ wà ni yóò ti gbẹ dànù.”’”+ 11  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 12  “Jọ̀wọ́ sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé náà+ pé, ‘Ẹ̀yin ní tòótọ́ kò ha mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí?’ Sọ pé, ‘Wò ó! Ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì tẹ̀ síwájú láti mú ọba rẹ̀+ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀, ó sì mú wọn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Bábílónì.+ 13  Síwájú sí i, ó mú ọ̀kan nínú irú-ọmọ tí ó jẹ́ ti ọba,+ ó sì bá a dá májẹ̀mú, ó sì mú un wá sínú ìbúra;+ ó sì kó àwọn tí ó wà ní ipò iwájú ní ilẹ̀ náà lọ,+ 14  kí ìjọba náà lè di èyí tí ó rẹlẹ̀,+ láìlè gbé ara rẹ̀ sókè, kí ó lè dúró nípa pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.+ 15  Ṣùgbọ́n níkẹyìn, ó ṣọ̀tẹ̀+ sí i ní rírán àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ sí Íjíbítì, kí ó lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ògìdìgbó ènìyàn. Òun yóò ha ní àṣeyọrí sí rere bí? Òun yóò ha sá àsálà, ẹni tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹni tí ó sì ti ba májẹ̀mú jẹ́? Òun yóò ha sá àsálà ní ti tòótọ́ bí?’+ 16  “‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,”+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, “ní ọ̀dọ̀ ọba tí ó fi í jẹ ọba, ẹni tí òun tẹ́ńbẹ́lú ìbúra rẹ̀,+ tí òun sì ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni òun yóò kú sí ní àárín Bábílónì.+ 17  Nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun ńlá àti nípasẹ̀ ìjọ tí ó jẹ́ ògìdìgbó, Fáráò kì yóò mú kí ó gbéṣẹ́ nínú ogun,+ nípa yíyára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì àti nípa mímọ odi ìsàgatì, láti ké ọ̀pọ̀ ọkàn kúrò.+ 18  Ó sì ti tẹ́ńbẹ́lú ìbúra+ ní bíba májẹ̀mú jẹ́, sì wò ó! ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ fúnni,+ àní ó ti ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Òun kì yóò sá àsálà.”’+ 19  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Bí mo ti ń bẹ láàyè, dájúdájú, ìbúra mi tí ó ti tẹ́ńbẹ́lú+ àti májẹ̀mú mi tí ó ti bàjẹ́—àní èmi yóò mú un wá sí orí rẹ̀. 20  Ṣe ni èmi yóò na àwọ̀n mi bò ó lórí, ó dájú pé a ó sì mú un nínú àwọ̀n tí mo fi ń ṣọdẹ;+ ṣe ni èmi yóò mú un wá sí Bábílónì, èmi yóò sì mú ara mi wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀ nípa ìwà àìṣòótọ́ tí ó ti hù sí mi.+ 21  Àti ní ti gbogbo ìsáǹsá rẹ̀ nínú gbogbo àwùjọ ọmọ ogun rẹ̀, nípa idà ni wọn yóò ṣubú, àwọn tí ó ṣẹ́ kù ni a óò fọ́n káàkiri, àní sínú gbogbo ẹ̀fúùfù.+ Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́.”’+ 22  “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Èmi pàápàá yóò mú lára téńté orí igi kédárì+ gíga fíofío, èmi yóò sì gbé e kalẹ̀; láti téńté ẹ̀ka igi rẹ̀ ni èmi yóò ti já èyí tí ó jẹ́ ọ̀jẹ̀lẹ́,+ èmi alára yóò sì gbé e lọ gbìn sórí òkè ńlá gíga tí ó lọ sókè fíofío.+ 23  Orí òkè ńlá ibi gíga Ísírẹ́lì ni èmi yóò gbé e lọ gbìn sí,+ ó dájú pé òun yóó sì yọ ẹ̀tun, yóò sì so èso,+ yóò sì di kédárì ọlọ́lá ọba.+ Abẹ́ rẹ̀ sì ni gbogbo ẹyẹ tí ó ní onírúurú ìyẹ́ apá yóò máa gbé ní ti tòótọ́; inú òjìji àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé ni wọn yóò máa gbé.+ 24  Gbogbo igi inú pápá yóò sì ní láti mọ̀ pé, èmi tìkára mi, Jèhófà,+ ti mú igi gíga rẹlẹ̀,+ mo ti gbé igi rírẹlẹ̀ ga,+ mo ti mú igi tí ó ṣì ní ọ̀rinrin gbẹ dànù,+ mo sì ti mú igi gbígbẹ yọ ìtànná. Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti sọ ọ́, mo sì ti ṣe+ é.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé