Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 16:1-63

16  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ̀ mí wá síwájú sí i, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ Jerúsálẹ́mù di mímọ̀+ fún un.  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí fún Jerúsálẹ́mù: “Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ìbí rẹ jẹ́ láti ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì.+ Ẹni tí í ṣe Ámórì ni baba rẹ,+ ìyá rẹ sì jẹ́ ọmọ Hétì.+  Ní ti ìbí rẹ, ní ọjọ́ tí a bí ọ,+ a kò gé okùn ìdodo rẹ, a kò sì wẹ̀ ọ́ nínú omi fún ìwẹ̀nùmọ́, a kò sì fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, a kò sì fi ọ̀já wé ọ rárá.  Ojú kankan kò káàánú fún ọ láti ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun wọ̀nyí fún ọ ní ìyọ́nú sí ọ,+ ṣùgbọ́n a sọ ọ́ sí orí pápá nítorí pé ìfitẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ọkàn rẹ wà ní ọjọ́ tí a bí ọ.  “‘“Mo sì ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo sì rí ọ tí o ń tàpá nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ọ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, ‘Máa wà láàyè nìṣó!’+ bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún ọ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, ‘Máa wà láàyè nìṣó!’  Ògìdìgbó púpọ̀ gan-an bí ìrújáde pápá ni mo sọ ọ́ dà kí o lè tóbi, kí o sì di ńlá,+ kí o sì wọlé pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ àtàtà.+ Àwọn ọmú méjèèjì pàápàá yọ dáadáa, irun rẹ sì hù ṣàkìtì-ṣàkìtì, nígbà tí o wà ní ìhòòhò àti ìhòòhò goloto.”’  “‘Mo sì ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo sì rí ọ, sì wò ó! ìgbà rẹ jẹ́ ìgbà ìfìfẹ́hàn.+ Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí na ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ mi bò ọ́,+ láti bo ìhòòhò goloto rẹ àti láti sọ gbólóhùn ìbúra fún ọ àti láti wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì di tèmi.+  Síwájú sí i, mo fi omi wẹ̀ ọ́,+ mo sì ṣan ẹ̀jẹ̀ rẹ nù kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára.+ 10  Mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ẹ̀wù tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára+ wọ̀ ọ́, mo sì fi awọ séálì+ wọ̀ ọ́ ní bàtà, mo sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà+ wé ọ, mo sì fi aṣọ olówó iyebíye bò ọ́. 11  Mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ àti láti fi júfù+ sí ọwọ́ rẹ àti ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn+ yí ọrùn rẹ ká. 12  Síwájú sí i, mo fi òrùka imú+ sí ihò imú rẹ àti yẹtí sí etí+ rẹ àti adé ẹlẹ́wà sí orí+ rẹ. 13  Ìwọ sì ń fi wúrà àti fàdákà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, aṣọ rẹ sì jẹ́ ọ̀gbọ̀ àtàtà àti aṣọ olówó iyebíye àti ẹ̀wù tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára.+ Ìyẹ̀fun kíkúnná àti oyin àti òróró+ ni ìwọ jẹ, ìwọ sì di ẹni tí ó lẹ́wà gidigidi ní ìrísí, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìwọ wá yẹ fún ipò ọba.’”+ 14  “‘Orúkọ kan sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ fún ọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nítorí ẹwà fífanimọ́ra rẹ, nítorí ó pé, nítorí ọlá ńlá mi tí mo fi sára rẹ,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 15  “‘Ṣùgbọ́n ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹwà fífanimọ́ra rẹ,+ o sì di kárùwà ní tìtorí orúkọ rẹ,+ o sì bẹ̀rẹ̀ sí da ìṣe kárùwà rẹ sórí olúkúlùkù ẹni tí ń kọjá lọ;+ tirẹ̀ ni ó jẹ́. 16  Ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí mú nínú àwọn ẹ̀wù rẹ, o sì ṣe ibi gíga+ tí ó ní àwọ̀ aláràbarà fún ara rẹ, ìwọ yóò sì fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà lórí wọn+—irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wọlé, kò sì gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. 17  Ìwọ yóò sì mú ohun èlò ẹlẹ́wà láti inú wúrà mi àti láti inú fàdákà mi tí mo ti fi fún ọ,+ ìwọ yóò sì ṣe àwọn ère ọkùnrin+ fún ara rẹ, ìwọ sì fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà pẹ̀lú wọn.+ 18  Ìwọ a sì mú ẹ̀wù rẹ tí a kó iṣẹ́ ọnà sí lára, ìwọ a sì bò wọ́n; òróró mi àti tùràrí+ mi ni ìwọ sì ń fi síwájú wọn ní ti tòótọ́. 19  Oúnjẹ tí mo fi fún ọ—ìyẹ̀fun kíkúnná àti òróró àti oyin tí mo ti mú kí o jẹ+—ni ìwọ pẹ̀lú fi sí iwájú wọn ní tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni,+ ó sì ń bá a lọ láti rí bẹ́ẹ̀’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” 20  “‘Ìwọ a sì mú àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ tí o bí fún mi,+ ìwọ a sì fi àwọn wọ̀nyí rúbọ sí wọn láti jẹ wọ́n run+—èyíinì kò ha tó gẹ́ẹ́ ní ti ìṣe kárùwà rẹ? 21  Ìwọ a sì pa àwọn ọmọ mi,+ nípa mímú wọn la iná kọjá ni ìwọ sì ń fi àwọn wọ̀nyí fún wọn.+ 22  Àti nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ àti ìṣe kárùwà rẹ ni ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ nígbà tí o wà ní ìhòòhò àti ìhòòhò goloto; tí o ń tàpá nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ tí o wà.+ 23  Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ (“ègbé, ègbé ni fún ọ,”+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ) 24  tí o bẹ̀rẹ̀ sí mọ òkìtì fún ara rẹ tí o sì ń ṣe ibi gíga fún ara rẹ ní gbogbo ojúde ìlú.+ 25  Ní gbogbo ìkòríta ọ̀nà ni ìwọ kọ́ ibi gíga rẹ sí,+ o sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ẹwà fífanimọ́ra rẹ di ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí,+ o sì na ẹsẹ̀ rẹ gbalaja sí olúkúlùkù ẹni tí ń kọjá lọ,+ o sì sọ ìṣe kárùwà rẹ di púpọ̀ sí i.+ 26  O sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà fún àwọn ọmọ Íjíbítì,+ àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ran ńlá,+ o sì ń bá a lọ láti mú iṣẹ́ kárùwà rẹ pọ̀ gidigidi láti mú mi bínú. 27  Sì wò ó! èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí ọ dájúdájú,+ èmi yóò sì dín ohun tí a yọ̀ǹda fún ọ kù,+ èmi yóò sì fi ọ́ fún ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn+ àwọn obìnrin tí ń kórìíra rẹ,+ àwọn ọmọbìnrin Filísínì,+ àwọn obìnrin tí a tẹ́ lógo ní tìtorí ọ̀nà rẹ ní ti ìwà àìníjàánu.+ 28  “‘Ìwọ sì ń bá a lọ láti fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà fún àwọn ọmọ Ásíríà nítorí ìwọ kò ní ìtẹ́lọ́rùn,+ ìwọ sì ń bá a lọ láti fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà pẹ̀lú wọn, ìwọ kò sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú. 29  Nítorí náà, ìwọ mú iṣẹ́ kárùwà rẹ pọ̀ gidigidi sí ilẹ̀ Kénáánì,+ sí àwọn ará Kálídíà;+ nínú èyí pàápàá, ìwọ kò ní ìtẹ́lọ́rùn. 30  Wo bí mo ti kún fún ìhónú+ sí ọ tó,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘nípa ṣíṣe tí o ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, iṣẹ́ obìnrin,+ kárùwà ajẹgàbaléni!+ 31  Nígbà tí o mọ òkìtì rẹ sí gbogbo ìkòríta ọ̀nà, tí o sì ṣe ibi gíga rẹ sí gbogbo ojúde ìlú, síbẹ̀, ìwọ kò dà bí kárùwà nínú ọ̀yà tí a ń fi ojú ẹ̀gàn wò. 32  Bí ó ti rí nínú ọ̀ràn aya tí ó ṣe panṣágà, ó mú àwọn àjèjì dípò ọkọ rẹ̀.+ 33  Ó ti jẹ́ àṣà wọn láti máa fi ẹ̀bùn fún gbogbo kárùwà,+ ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ ti fi àwọn ẹ̀bùn rẹ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ lọ́nà ìgbónára,+ ìwọ sì fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún wọn láti wọlé tọ̀ ọ́ wá láti gbogbo àyíká nínú ìṣe+ kárùwà rẹ. 34  Àti pé ní ti ọ̀ràn rẹ nínú ìṣe kárùwà rẹ, ohun tí ó jẹ́ òdì-kejì sí ti àwọn obìnrin yòókù ni ó ń ṣẹlẹ̀, a kò sì tíì ṣe iṣẹ́ kárùwà tí ó jọ ọ̀nà tí o ń gbà ṣe tìrẹ, àní ní ti ọ̀yà tí o ń fi fúnni nígbà tí a kò fún ọ ní ọ̀yà, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ òdì-kejì.’ 35  “Nítorí náà, ìwọ kárùwà,+ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 36  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Nítorí ìdí náà pé o tú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde,+ o sì tú abẹ́+ rẹ síta nínú ìṣe kárùwà rẹ sí àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ lọ́nà ìgbónára+ àti sí gbogbo òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ rẹ tí ó yẹ ní ṣíṣe họ́ọ̀ sí, àní pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ tí o fi fún wọn,+ 37  nítorí náà, kíyè sí i, èmi yóò kó gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ lọ́nà ìgbónára jọpọ̀, àwọn ẹni tí ìwọ jẹ́ adùn fún àti gbogbo àwọn tí ìwọ nífẹ̀ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ìwọ kórìíra, èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀ lòdì sí ọ láti gbogbo àyíká, èmi yóò sì tú abẹ́ rẹ síta fún wọn, wọn yóò sì rí gbogbo abẹ́ rẹ.+ 38  “‘Ṣe ni èmi yóò fi ìdájọ́ àwọn panṣágà obìnrin+ àti àwọn obìnrin tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀+ ṣe ìdájọ́ rẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ ìhónú àti owú+ fún ọ. 39  Ṣe ni èmi yóò fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, wọn yóò sì ya òkìtì+ rẹ lulẹ̀ dájúdájú, a ó sì bi àwọn ibi gíga rẹ wó+ dájúdájú, wọn yóò sì bọ́ ẹ̀wù rẹ+ kúrò lára rẹ, wọn yóò sì kó àwọn ohun èlò rẹ ẹlẹ́wà,+ wọn yóò sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ìhòòhò goloto. 40  Wọn yóò sì gbé ìjọ+ dìde dojú kọ ọ́, wọn yóò sì sọ ọ́ ní òkúta,+ wọn yóò sì fi idà wọn pa ọ́.+ 41  Wọn yóò sì fi iná+ sun àwọn ilé rẹ, wọn yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún lójú ọ̀pọ̀ obìnrin;+ ṣe ni èmi yóò mú kí o dẹ́kun jíjẹ́ kárùwà,+ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fúnni ní ọ̀yà mọ́. 42  Dájúdájú, èmi yóò sì mú ìhónú mi wá sí ìsinmi rẹ̀ nínú rẹ,+ owú mi yóò sì yí kúrò lọ́dọ̀ rẹ;+ ṣe ni èmi yóò gbé jẹ́ẹ́, a kì yóò sì mú mi bínú mọ́.’ 43  “‘Nítorí ìdí náà pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ,+ ìwọ yóò sì kó ṣìbáṣìbo bá mi nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí,+ àní sì kíyè sí i, èmi pẹ̀lú, ní tèmi, yóò gbé ọ̀nà tìrẹ lé orí rẹ gan-an,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘ó sì dájú pé ìwọ kì yóò máa bá a lọ nínú ìwà àìníjàánu èyíkéyìí pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ. 44  “‘Wò ó! Olúkúlùkù ẹni tí ń pa òwe+ sí ọ yóò pa òwe yìí, pé: “Bí ìyá ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin rẹ̀ rí!”+ 45  Ọmọbìnrin ìyá rẹ ni ọ́,+ ẹni tí ń fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ọkọ rẹ̀+ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ sì ni ọ́, àwọn tí wọ́n fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn. Ọmọ Hétì+ ni ìyá ẹ̀yin obìnrin yìí, ẹni tí í ṣe Ámórì+ sì ni baba yín.’” 46  “‘Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin sì ni Samáríà+ alára, àti àwọn àrọko rẹ̀,+ tí ń gbé ní òsì rẹ, àti àbúrò rẹ obìnrin, tí ǹ gbé ní ọ̀tún rẹ sì ni Sódómù+ àti àwọn àrọko rẹ̀.+ 47  Ìwọ kò sì rìn ní ọ̀nà wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn.+ Ní ìgbà díẹ̀ sí i, àní ìwọ, ní gbogbo ọ̀nà rẹ,+ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun ju èyí tí wọ́n gbé. 48  Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘Sódómù arábìnrin rẹ, òun àti àwọn àrọko rẹ̀, wọn kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí o ṣe, ìwọ àti àwọn àrọko rẹ.+ 49  Wò ó! Èyí ni ohun tí ó jẹ́ ìṣìnà Sódómù arábìnrin rẹ: Ìgbéraga,+ ànító oúnjẹ+ àti ipò ìrọra+ ti wíwà láìní ìyọlẹ́nu ni ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ àti àwọn àrọko rẹ̀,+ ọwọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́+ àti àwọn òtòṣì ni kò fún lókun.+ 50  Wọ́n sì ń bá a lọ láti jẹ́ onírera+ àti láti máa ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí níwájú mi,+ mo sì mú wọn kúrò níkẹyìn, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti rí pé ó yẹ.+ 51  “‘Ní ti Samáríà,+ òun kò tíì dẹ́ṣẹ̀ àní tó ìdajì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ ń mú àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ pọ̀ gidigidi ju bí àwọn ti ṣe lọ, tí o fi mú kí àwọn arábìnrin rẹ fara hàn ní olódodo nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ tí o ń ṣe.+ 52  Ìwọ pẹ̀lú, ru ìtẹ́lógo rẹ nígbà tí ó bá di pé o jiyàn ní ìtìlẹyìn fún àwọn arábìnrin rẹ. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú èyí tí o hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí ju bí wọ́n ti ṣe lọ, wọ́n jẹ́ olódodo jù ọ́ lọ.+ Ìwọ pẹ̀lú, kí ìtìjú bá ọ, kí o sì ru ìtẹ́lógo rẹ ní ti pé o mú kí àwọn arábìnrin rẹ fara hàn ní olódodo.’ 53  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì kó àwọn òǹdè wọn jọ,+ àwọn òǹdè Sódómù àti àwọn àrọko rẹ, àti àwọn òǹdè Samáríà àti àwọn àrọko rẹ̀; èmi yóò sì kó àwọn òǹdè rẹ jọ ní àárín wọn,+ 54  kí o lè ru ìtẹ́lógo rẹ;+ kí o sì gba ìtẹ́lógo nítorí gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe, ní ti pé o tù wọ́n nínú.+ 55  Àwọn arábìnrin rẹ, Sódómù àti àwọn àrọko rẹ̀, yóò padà sí ipò wọn àtijọ́, Samáríà àti àwọn àrọko rẹ yóò sì padà sí ipò wọn àtijọ́, ìwọ alára àti àwọn àrọko rẹ̀ yóò sì padà sí ipò yín àtijọ́.+ 56  Sódómù arábìnrin rẹ kò sì yẹ ní ohun gbígbọ́ nípa rẹ̀ ní ẹnu rẹ ní ọjọ́ ìgbéraga rẹ,+ 57  kí a tó fi ìwà búburú tìrẹ hàn síta,+ gan-an bí ìgbà ẹ̀gàn àwọn ọmọbìnrin Síríà+ àti gbogbo àwọn tí ó yí i ká, àwọn ọmọbìnrin Filísínì,+ àwọn tí ń pẹ̀gàn rẹ láti ìhà gbogbo.+ 58  Ìwà àìníjàánu+ rẹ àti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ, ìwọ fúnra rẹ yóò rù wọ́n,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 59  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Èmi pẹ̀lú yóò ṣe sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe,+ nítorí ìwọ tẹ́ńbẹ́lú ìbúra ní bíba májẹ̀mú mi jẹ́.+ 60  Èmi, èmi alára, yóò sì rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ,+ èmi yóò sì fìdí májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin múlẹ̀ fún ọ.+ 61  Dájúdájú, ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ,+ ìtẹ́lógo yóò sì bá ọ nígbà tí o bá gba àwọn arábìnrin rẹ, àwọn tí wọ́n dàgbà jù ọ́ lọ àti àwọn tí wọ́n jẹ́ àbúrò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì fi wọ́n fún ọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọbìnrin,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe nítorí májẹ̀mú rẹ.’+ 62  “‘Èmi, èmi alára, yóò fìdí májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ múlẹ̀;+ ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, 63  kí o lè rántí, kí ìtìjú sì bá ọ+ ní ti gidi, kí o má bàa ní ìdí kankan mọ́ láti la ẹnu+ rẹ nítorí ìtẹ́lógo rẹ, nígbà tí mo bá ṣe ètùtù+ fún ọ nítorí gbogbo ohun tí o ti ṣe,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé