Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 15:1-8

15  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, ọ̀nà wo ni igi àjàrà+ gbà yàtọ̀ sí gbogbo igi yòókù, ọ̀mùnú, tí ó wà nínú àwọn igi igbó?  A ha ń mú òpó láti ara rẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́? Tàbí àwọn ènìyàn ha ń mú èèkàn láti ara rẹ̀ láti gbé nǹkan èlò kọ́ sí?  Wò ó! Inú iná ni a ó fi sí láti fi ṣe ohun ìdáná.+ Ìkángun rẹ̀ méjèèjì ni iná jẹ run ní ti tòótọ́, àárín rẹ̀ gan-an sì jó gbẹ.+ Ó ha yẹ fún iṣẹ́ èyíkéyìí bí?  Wò ó! Nígbà tí ó bá wà láìyingin, a kì í lò ó fún iṣẹ́ èyíkéyìí. Áńbọ̀sìbọ́sí ìgbà tí iná jẹ ẹ́ run, tí ó sì jó gbẹ, ni a óò wá lò ó fún iṣẹ́ èyíkéyìí síwájú sí i!”+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí igi àjàrà láàárín àwọn igi igbó, tí mo ti fi fún iná bí ohun ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni mo ti fi àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù fúnni.+  Mo sì ti dojú mi kọ wọ́n.+ Láti inú iná ni wọ́n ti jáde lọ, ṣùgbọ́n iná gan-an ni yóò jẹ wọ́n run.+ Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá dojú kọ wọn.’”+  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ nítorí ìdí náà pé wọ́n ṣe àìṣòótọ́,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé