Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 14:1-23

14  Àwọn ọkùnrin lára awọn àgbàlagbà Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá, wọ́n sì jókòó níwájú mi.+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, ní ti àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, wọ́n ti mú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn wá sí ọkàn-àyà wọn, ohun ìkọ̀sẹ̀ tí ń fa ìṣìnà wọn ni wọ́n sì ti gbé sí iwájú wọn.+ Wọn yóò ha ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ mi rárá bí?+  Nítorí náà, bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ọkùnrin èyíkéyìí nínú ilé Ísírẹ́lì tí ó bá mú òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ rẹ̀ wá sí ọkàn-àyà rẹ̀, tí ó sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ náà tí ń fa ìṣìnà rẹ̀ sí iwájú rẹ̀, tí ó sì wá ní ti tòótọ́ sọ́dọ̀ wòlíì náà, èmi, Jèhófà, èmi yóò mú ara mi wá dá a lóhùn nínú ọ̀ràn náà gẹ́gẹ́ bí ògìdìgbó tí àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ+ rẹ̀ jẹ́,  fún ète gbígbá ilé Ísírẹ́lì mú nípasẹ̀ ọkàn-àyà wọn,+ nítorí wọ́n ti fa ara wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi nípasẹ̀ òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ wọn—gbogbo wọn pátá.”’+  “Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ẹ padà wá, kí ẹ sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín,+ kí ẹ sì yíjú padà, àní kúrò nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yín;+  nítorí ọkùnrin èyíkéyìí láti ilé Ísírẹ́lì tàbí lára àwọn àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní Ísírẹ́lì, tí ó yọ ara rẹ̀ kúrò nínú títọ̀ mí lẹ́yìn,+ tí ó sì mú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ rẹ̀ wá sí ọkàn-àyà rẹ̀, tí ó sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ náà tí ń fa ìṣìnà rẹ̀ sí iwájú rẹ̀, tí ó sì wá ní tòótọ́ sọ́dọ̀ wòlíì náà láti ṣe ìwádìí fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ mi,+ èmi, Jèhófà, èmi yóò mú ara mi wá dá a lóhùn nípasẹ̀ èmi tìkára mi.  Èmi yóò dojú mi kọ ọkùnrin náà,+ èmi yóò sì fi í ṣe àmì+ àti ọ̀rọ̀ òwe,+ èmi yóò sì ké e kúrò ní àárín àwọn ènìyàn mi;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’+  “‘Àti ní ti wòlíì náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di ẹni tí a tàn, tí ó sì sọ ọ̀rọ̀ kan ní ti tòótọ́, èmi tìkára mi, Jèhófà, ti tan wòlíì náà;+ ṣe ni èmi yóò na ọwọ́ mi jáde lòdì sí i, èmi yóò sì pa a rẹ́ ráúráú kúrò ní àárín àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.+ 10  Wọn yóò sì ní láti ru ìṣìnà wọn.+ Ìṣìnà olùṣe ìwádìí yóò jẹ́ ohun kan náà bí ti ìṣìnà wòlíì náà,+ 11  kí àwọn ti ilé Ísírẹ́lì má bàa rìn gbéregbère mọ́ kúrò nínú títọ̀ mí lẹ́yìn,+ kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́ nípasẹ̀ gbogbo ìrélànàkọjá wọn. Wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”+ 12  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 13  “Ọmọ ènìyàn, ní ti ilẹ̀ kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó dá ẹ̀ṣẹ̀ sí mi ní ṣíṣe àìṣòótọ́,+ èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí i pẹ̀lú, èmi yóò sì bá a ṣẹ́ àwọn ọ̀pá tí a ń fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí,+ èmi yóò sì rán ìyàn sí i,+ èmi yóò sì ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.”+ 14  “‘Ká ní àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí wà ní àárín rẹ̀, Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù,+ àwọn alára nítorí òdodo+ wọn yóò dá ọkàn wọn nídè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”+ 15  “‘Tàbí bí mo bá mú kí àwọn aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà la ilẹ̀ náà já,+ tí àwọn ní tòótọ́ sì mú kí ó ṣòfò ọmọ,+ tí ó sì di ahoro ní ti tòótọ́ láìsí ẹni tí ń là á kọjá ní tìtorí àwọn ẹranko ẹhànnà náà,+ 16  bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí bá tilẹ̀ wà ní àárín rẹ̀, bí mo tí ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘wọn kì yóò dá àwọn ọmọkùnrin tàbí àwọn ọmọbìnrin nídè; àwọn, kìkì àwọn fúnra wọn, ni a óò dá nídè, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro.’”+ 17  “‘Tàbí bí ó bá jẹ́ idà ni mo mú wá sórí ilẹ̀ yẹn,+ tí èmi sì wí ní ti tòótọ́ pé: “Kí idà la ilẹ̀ náà já,” tí mo sì ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀+ kúrò nínú rẹ̀ ní ti tòótọ́, 18  àní bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí bá wà ní àárín rẹ̀,+ bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘wọn kì yóò dá àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin nídè, ṣùgbọ́n àwọn, kìkì àwọn fúnra wọn, ni a óò dá nídè.’”+ 19  “‘Tàbí bí ó bá jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn ni mo rán sí ilẹ̀ náà,+ tí èmi sì da ìhónú mi sórí rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀,+ láti ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀ kúrò nínú rẹ̀, 20  àní bí Nóà,+ Dáníẹ́lì+ àti Jóòbù+ bá wà ní àárín rẹ̀,+ bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘wọn kì yóò dá ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin nídè; àwọn fúnra wọn nítorí òdodo wọn yóò dá ọkàn ara wọn nídè.’”+ 21  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Bẹ́ẹ̀ ni yoo jẹ́ pẹ̀lú, nígbà tí ìgbésẹ̀ ìdájọ́ mi mẹ́rin+ tí ń ṣeni léṣe yóò wà—idà àti ìyàn àti aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà àti àjàkálẹ̀ àrùn+—tí èmi ní tòótọ́ yóò rán sórí Jerúsálẹ́mù láti ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀+ kúrò nínú rẹ̀. 22  Ṣùgbọ́n, wò ó! àwùjọ ẹgbẹ́ tí ó sálà, àwọn tí a mú jáde,+ ni yóò ṣẹ́ kù nínú rẹ̀ dájúdájú. Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, àwọn rèé! Wọ́n ń jáde bọ̀ lọ́dọ̀ yín, ẹ ó sì ní láti rí ọ̀nà wọn àti ìbálò wọn.+ Dájúdájú, a ó sì tù yín nínú nítorí ìyọnu àjálù náà tí èmi yóò ti mú wá sórí Jerúsálẹ́mù, àní gbogbo èyí tí èmi yóò ti mú wá sórí rẹ̀.’” 23  “‘Wọn yóò sì tù yín nínú dájúdájú nígbà tí ẹ bá rí ọ̀nà wọn àti ìbálò wọn; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé kì í ṣe láìnídìí ni èmi yóò ti ṣe gbogbo èyí tí èmi yóò ṣe lòdì sí i,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé