Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 13:1-23

13  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọ tẹ́lẹ̀,+ kí o sì sọ́ fún àwọn tí ń sọ tẹ́lẹ̀ láti inú ọkàn-àyà wọn+ pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ègbé ni fún àwọn wòlíì arìndìn,+ tí wọ́n ń tọ ẹ̀mí+ ara wọn lẹ́yìn, tí wọn kò rí nǹkan kan!+  Ísírẹ́lì, àwọn wòlíì rẹ dà bí àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ibi ìparundahoro.+  Dájúdájú, ẹ kì yóò gòkè lọ sí àwọn àlàfo náà,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò mọ ògiri òkúta+ nítorí ilé Ísírẹ́lì, láti dúró nínú ìjà ogun ní ọjọ́ Jèhófà.”+  “Wọ́n ti rí ìran ohun tí kò jóòótọ́, wọ́n sì ti woṣẹ́ tí ó jẹ́ irọ́,+ àwọn tí ń wí pé, ‘Àsọjáde Jèhófà ni,’ nígbà tí Jèhófà alára kò rán wọn, wọ́n sì ti dúró láti mú kí ọ̀rọ̀ ṣẹ.+  Kì í ha ṣe ìran tí kò jóòótọ́ ni ẹ̀yin rí, ìwoṣẹ́ tí ó jẹ́ irọ́ ha sì kọ ni ẹ̀yin sọ, nígbà tí ẹ ń wí pé, ‘Àsọjáde Jèhófà ni,’ nígbà tí èmi alára ko sọ nǹkan kan?”’+  “‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “‘Nítorí ìdí náà pé ẹ sọ ohun tí kì í ṣe òtítọ́, ẹ sì rí ìran irọ́, nítorí náà, kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”  Ọwọ́ mi ti wà lára àwọn wòlíì tí ń rí ìran ohun tí kì í ṣe òtítọ́, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́.+ Wọn kì yóò máa bá a lọ láti wà nínú àwùjọ tímọ́tímọ́+ àwọn ènìyàn mi, a kì yóò sì kọ orúkọ wọn sínú àkọsílẹ̀ orúkọ ilé Ísírẹ́lì,+ wọn kì yóò sì wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ 10  nítorí ìdí náà, bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ìdí náà pé wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi ṣáko lọ, wọ́n ń wí pé, “Àlàáfíà wà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà,+ ẹnì kan sì wà tí ń mọ ògiri ìkélé, ṣùgbọ́n àwọn tí ń fi ọ̀dà ẹfun+ rẹ́ ẹ ń ṣe é lásan ni.’+ 11  “Sọ fún àwọn tí ń fi ọ̀dà ẹfun rẹ́ ẹ pé yóò wó. Dájúdájú, eji wọwọ tí ń kún àkúnya yóò rọ̀, ẹ̀yin, òkúta yìnyín, yóò sì já bọ́, ẹ̀fúùfù-òjijì ti ìjì ẹlẹ́fùúùfù yóò sì fa ìlàsíwẹ́wẹ́.+ 12  Sì wò ó! ògiri náà yóò wó. A kì yóò ha sọ fún yín pé, ‘Ipele rírẹ́ èyí tí ẹ fi rẹ́ ẹ dà?’+ 13  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò mú kí ẹ̀fúùfù-òjijì ti ìjì ẹlẹ́fùúùfù rọ́ jáde ní ìhónú mi, àti ní ìbínú mi, eji wọwọ tí ń kún àkúnya yóò rọ̀, àti ní ìhónú mi, òkúta yìnyín yóò já bọ́ fún ṣiṣe ìparun pátápátá.+ 14  Ògiri tí ẹ fi ọ̀dà ẹfun rẹ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, èmi yóò sì bá a kanlẹ̀, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì hàn síta.+ Ṣe ni yóò ṣubú, ẹ ó sì wá sí òpin ní àárín rẹ̀; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+ 15  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì mú ìhónú mi wá sí ìparí lára ògiri náà àti lára àwọn tí ń fi ọ̀dà ẹfun rẹ́ ẹ, èmi yóò sì wí fún yín pé: “Ògiri náà kò sí mọ́, àwọn tí ó sì ń rẹ́ ẹ kò sí mọ́,+ 16  àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fún Jerúsálẹ́mù àti àwọn tí ń rí ìran àlàáfíà fún un,+ nígbà tí kò sí àlàáfíà,”’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+ 17  “Àti ní tìrẹ, ìwọ ọmọ ènìyàn, dojú kọ+ àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn rẹ tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì obìnrin+ láti inú ọkàn-àyà wọn,+ kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn. 18  Kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ń rán àwọn ọ̀já pọ̀ sí gbogbo ìgúnpá, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú sí orí ní onírúurú ìwọ̀n láti ṣọdẹ àwọn ọkàn!+ Àwọn ọkàn tí ẹ̀yin obìnrin yìí ń dọdẹ ha jẹ́ ti àwọn ènìyàn mi, ẹ ha sì pa ọkàn tí ó jẹ́ tiyín mọ́ láàyè bí? 19  Ẹ̀yin yóò ha sì sọ mi di aláìmọ́ lójú àwọn ènìyàn mi nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà bálì àti nítorí òkèlè oúnjẹ,+ láti fi ikú pa àwọn ọkàn tí kò yẹ́ kí ó kú+ àti láti pa àwọn ọkàn mọ́ láàyè, àwọn tí kò yẹ́ kí ó wà láàyè nípa irọ́ tí ẹ pa fún àwọn ènìyàn mi, àwọn tí ń gbọ́ irọ́?”’+ 20  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Kíyè sí i, èmi dojú ìjà kọ ọ̀já ẹ̀yin obìnrin yìí, èyí tí ẹ fí ń dọdẹ mú àwọn ọkàn bí ẹni pé wọ́n jẹ́ ohun tí ń fò, dájúdájú, èmi yóò fà wọ́n ya kúrò ní apá yín, èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ọkàn tí ẹ ń dọdẹ mú lọ, àwọn ọkàn bí ẹni pé wọ́n jẹ́ ohun tí ń fò.+ 21  Èmi yóò sì fa ìbòjú yín ya kúrò, èmi yóò sì dá àwọn ènìyàn mi nídè kúrò lọ́wọ́ yín, wọn kì yóò sì sí ní ọwọ́ yín bí ohun tí a mú nígbà ìdọdẹ; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 22  Nítorí fífi èké mú ọkàn-àyà olódodo dorí kodò,+ nígbà tí èmi alára kò fa ìrora fún un, àti fún mímú ọwọ́ ẹni burúkú le,+ kí ó má bàa yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí a lè pa á mọ́ láàyè,+ 23  nítorí náà, ẹ̀yin obìnrin yìí kì yóò máa bá a lọ́ ní rírí ohun tí kì í ṣe òtítọ́ ní ìran,+ iṣẹ́ wíwò+ ni ẹ kì yóò sì wò+ mọ́;+ èmi yóò sì dá àwọn ènìyàn mi nídè kúrò lọ́wọ́ yín,+ ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé