Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìsíkíẹ́lì 11:1-25

11  Ẹ̀mí+ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé mi sókè,+ ó sì gbé mi wá sí ẹnubodè ìlà-oòrùn ilé Jèhófà tí ó dojú kọ ìhà ìlà-oòrùn,+ sì wò ó! ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n+ wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè, ní àárín wọn ni mo sì rí Jaasánáyà ọmọkùnrin Ásúrì àti Pẹlatáyà ọmọkùnrin Bẹnáyà, àwọn ọmọ aládé àwọn ènìyàn náà.+  Ó sì wí fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ìwọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń pète-pèrò ọṣẹ́, tí wọ́n sì ń gbani ní ìmọ̀ràn búburú lòdì sí ìlú ńlá yìí;+  tí wọ́n ń wí pé, ‘Kíkọ́ àwọn ilé kò ha ti sún mọ́lé?+ Òun ni ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀,+ àwa sì ni ẹran.’  “Nítorí náà, sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn.”+  Nígbà náà ni ẹ̀mí Jèhófà bà lé mi,+ ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Sọ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Ẹ̀yin sọ ohun tí ó tọ́, ilé Ísírẹ́lì; àti ní ti ohun tí ó dìde nínú ẹ̀mí yín, èmi alára ti mọ̀+ ọ́n.  Ẹ̀yin mú kí àwọn ènìyàn yín tí a pa nínú ìlú ńlá yìí di púpọ̀, ẹ sì ti fi àwọn ènìyàn tí a pa kún àwọn ojú pópó rẹ̀.”’”+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Ní ti àwọn ènìyàn yín tí a pa tí ẹ gbé sáàárín rẹ̀, àwọn ni ẹran,+ òun sì ni ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀;+ mímú ẹ̀yin fúnra yín jáde kúrò ní àárín rẹ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀.’”+  “‘Ẹ̀yin bẹ̀rù idà,+ èmi yóò sì mú idà wá sórí yín,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+  ‘Dájúdájú, èmi yóò sì mú yín jáde kúrò ní àárín rẹ̀, èmi yóò sì fi yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́,+ èmi yóò sì mú ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí yín.+ 10  Nípa idà ni ẹ ó ṣubú.+ Ní ojú ààlà Ísírẹ́lì+ ni èmi yóò ti dá yín lẹ́jọ́; ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 11  Òun kì yóò sì jẹ́ ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀ fún yín,+ ẹ̀yin kì yóò sì jẹ́ ẹran ní àárín rẹ̀. Ní ojú ààlà Ísírẹ́lì ni èmi yóò ti dá yín lẹ́jọ́, 12  ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nítorí pé ẹ̀yin kò rìn nínú àwọn ìlànà mi, àwọn ìdájọ́ mi ni ẹ kò sì tẹ̀ lé,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin hùwà ní ìbàmú pẹ̀lú ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà yí ká yín.’”+ 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé ní gbàrà tí mo sọ tẹ́lẹ̀, Pẹlatáyà ọmọkùnrin Bẹnáyà kú,+ mo sì dojú bolẹ̀, mo sì ké ní ohùn rara+ pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ!+ Ìparun pátápátá ni ìwọ yóò ha mú ṣẹ ní kíkún sórí àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì?”+ 14  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 15  “Ọmọ ènìyàn, ní ti àwọn arákùnrin rẹ,+ àwọn arákùnrin rẹ, àwọn ọkùnrin tí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ rẹ láti ṣe àtúnrà kàn, gbogbo ilé Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀, sì ni àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà réré sí Jèhófà. Tiwa ni ilẹ̀ náà; ilẹ̀ náà ni a ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí ohun ìní’;+ 16  nítorí náà, sọ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kó wọn jìnnà réré lọ sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ síbẹ̀, èmi yóò di ibùjọsìn fún wọn fún ìgbà díẹ̀ láàárín ilẹ̀ tí wọ́n dé sí.”’+ 17  “Nítorí náà, sọ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí: “Dájúdájú, èmi yóò kó yín jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, èmi yóò sì kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ láàárín àwọn tí a tú yín ká sí, èmi yóò sì fi ilẹ̀ Ísírẹ́lì fún yín.+ 18  Dájúdájú, wọn yóò sì wá sí ibẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo ohun ìríra rẹ̀ àti gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.+ 19  Èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà kan,+ èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn;+ ó dájú pé èmi yóò sì mú ọkàn-àyà òkúta kúrò nínú ẹran ara wọn,+ èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà ẹlẹ́ran ara,+ 20  kí wọ́n lè máa rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, kí wọ́n sì pa àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, kí wọ́n sì mú wọn ṣe ní ti tòótọ́;+ kí wọ́n di ènìyàn mi ní ti tòótọ́,+ kí èmi alára sì di Ọlọ́run wọn.”’+ 21  “‘“Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ọkàn-àyà wọn ń rìn nínú ohun ìríra wọn àti ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn,+ dájúdájú, èmi yóò mú ọ̀nà wọn wá sórí wọn,” ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.’”+ 22  Àwọn kérúbù+ náà sì wá gbé ìyẹ́ apá wọn sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ sì wà nítòsí wọn,+ ògo+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn, lókè.+ 23  Ògo Jèhófà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ kúrò ní ìlú ńlá náà, ó sì wá dúró lórí òkè ńlá+ tí ó wà ní ìlà-oòrùn ìlú ńlá náà.+ 24  Ẹ̀mí+ sì gbé mi sókè,+ níkẹyìn, ó mú mi wá sí Kálídíà lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn,+ nínú ìran nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run; ìran náà tí mo rí sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi. 25  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ìgbèkùn nípa gbogbo ohun tí Jèhófà tí jẹ́ kí ń rí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé