Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Ìsíkíẹ́lì 10:1-22

10  Mo sì ń bá a lọ láti wò, sì kíyè sí i! lókè òfuurufú+ tí ó wà lórí àwọn kérúbù náà ni ohun kan wà tí ó dà bí òkúta sàfáyà,+ tí ó rí bí ìrísí ìtẹ́,+ ó fara hàn lókè wọn.  Ó sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ àní láti wí pé: “Wọlé sáàárín ètò àgbá kẹ̀kẹ́,+ sí abẹ́ àwọn kérúbù, kí o sì fi ẹyín iná+ láti àárín àwọn kérúbù náà kún ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ méjèèjì, kí o sì fọ́n wọn sórí ìlú ńlá náà.”+ Bẹ́ẹ̀ ni ó wọlé lójú mi.  Àwọn kérúbù náà sì dúró ní apá ọ̀tún ilé náà nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìṣúdùdù èéfín sì kún àgbàlá inú lọ́hùn-ún.+  Ògo Jèhófà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbéra sókè láti ọ̀dọ̀ àwọn kérúbù wá sí ibi àbáwọ ilé náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ilé náà kún fún ìṣúdùdù èéfín,+ àgbàlá náà sì kún fún ìtànyòò ògo Jèhófà.  Àní ìró ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà+ sì di èyí tí a gbọ́ títí dé àgbàlá òde, bí ìró Ọlọ́run Olódùmarè nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ó pàṣẹ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, pé: “Mú iná láti àárín ètò àgbá kẹ̀kẹ́, láti àárín àwọn kérúbù náà,” bẹ́ẹ̀ ni ó wọlé, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbá kẹ̀kẹ́ náà.  Kérúbù náà sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti àárín àwọn kérúbù sí iná+ tí ó wà láàárín àwọn kérúbù náà,+ ó sì mú un, ó sì fi í sínú ìtẹkòtò ọwọ́ ẹni tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ ẹni tí ó gbà á, tí ó sì jáde lọ.  A sì rí àwòrán ọwọ́ ará ayé tí àwọn kérúbù náà ní lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn.+  Mo sì ń wò ó, sì kíyè sí i! àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù náà, àgbá kẹ̀kẹ́ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kan àti àgbá kẹ̀kẹ́ kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kejì,+ ìrísí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà sì dà bí ìpọ́nyòò òkúta kírísóláítì. 10  Àti pé, ní ti ìrísí wọn, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìrí kan náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan bá wà ní àárín àgbá kẹ̀kẹ́ kan.+ 11  Nígbà tí wọ́n bá ń lọ, ìhà wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni wọ́n fi ń lọ. Wọn kì í yí padà nígbà tí wọ́n bá ń lọ, nítorí ibi tí orí bá dojú kọ, ni wọn yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ. Wọn kì í yí padà nígbà tí wọ́n bá ń lọ.+ 12  Gbogbo ẹran ara wọn àti ẹ̀yìn wọn àti ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ apá wọn àti àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì kún fún ojú yí ká.+ Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn. 13  Ní ti àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà, a ké jáde sí wọn ní etí mi pé, “àgbá kẹ̀kẹ́ alásokọ́ra!” 14  Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ojú mẹ́rin.+ Ojú àkọ́kọ́ jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì sì jẹ́ ojú ará ayé,+ ojú kẹta sì jẹ́ ojú kìnnìún, ojú kẹrin sì jẹ́ ojú idì.+ 15  Àwọn kérúbù náà a sì dìde+—ẹ̀dá alààyè kan náà tí mo ti rí ní Odò Kébárì+ ni— 16  nígbà tí àwọn kérúbù náà bá sì lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn;+ nígbà tí àwọn kérúbù náà bá sì gbé ìyẹ́ apá wọn sókè láti gbéra sókè kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà kì yóò yí padà, àní àwọn fúnra wọn, kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.+ 17  Nígbà tí àwọn wọ̀nyí bá dúró jẹ́ẹ́, àwọn náà a dúró jẹ́ẹ́; nígbà tí àwọn wọ̀nyí bá sì dìde,+ àwọn náà a sì dìde pẹ̀lú wọn, nítorí ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà ń bẹ nínú wọn.+ 18  Ògo+ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ láti orí ibi àbáwọ ilé náà, ó sì dúró jẹ́ẹ́ lórí àwọn kérúbù náà.+ 19  Wàyí o, àwọn kérúbù náà gbé ìyẹ́ apá wọn sókè, wọ́n sì dìde kúrò lórí ilẹ̀ ayé+ lójú mi. Nígbà tí wọ́n lọ síwájú, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà pẹ̀lú wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn pẹ́kípẹ́kí; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró ní ibi àtiwọ ẹnubodè ìlà-oòrùn ti ilé Jèhófà, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn, láti òkè. 20  Èyí ni ẹ̀dá alààyè+ tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní Odò Kébárì,+ tí mo fi mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21  Ní ti àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ojú mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ní ìyẹ́ apá mẹ́rin,+ ìrí ọwọ́ ará ayé sì wà lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn. 22  Àti ní ti ìrí ojú wọn, ojú wọn jẹ́ ìrísí tí mo rí lẹ́bàá Odò Kébárì, àwọn gan-an ni.+ Iwájú tààrà ni olúkúlùkù wọn ń lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé